44
IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 AGBEYEWO: IYIPADA OTUN EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re KOKO ORO: IYIPADA TI OLORUN IBI-KIKA: Esekieli 36:25-27 ALAYE ISAAJU Iyipada ti Olorun je mo: (a) Wiwe mo kuro ninu ese (ese 25) (b) Siso okan di otun (ese 26) (c) Gbigba agbara nipa Emi Mimo lati rin ninu ona Olorun (ese 27) Olorun ti kilo fun awon omo Israeli lehin odun ti o ju irinwo odun lo ni oko eru ni Egipti pe “Bi iwo ko ba fetisi ohun Oluwa Olorun re, lati ma kiyesi ati se gbogbo ase Re ati ilana Re.... a o si si o kiri gbogbo ijoba aye” (Deut. 28:15, 25). A fon won kaakiri opolopo orile-ede nitori aigboran won (2 Awon Oba 17:23). Sibesibe Esekieli so asotele pe Olorun yo ko won jo lati orile ede gbogbo pada si ile ini won. Awon eni ibaje ati olorun lile eniyan Israeli yii yoo di eni iyipada ti Olorun, ki ise nitori yiye won bikose nitori ife Olorun Romu 5:8. A tun so nipa iyipada Olorun yii ni Jeremiah 31:33-34. O was si imuse ni Majemu Titun ti Jesu Kristi (Heberu 8:8-12; Heberu 10:16-17), eyi ti a fi idi re mule nipa itaje sile lori oke Kalfari (Matteu 26:28). Nipase ise irapada ti omo Re yi, O we ese wa nu, O dariji wa, Emi Mmo Re si n so wa di otun. Nitori pe ninu ese ni a gbe bi wa (Saamu 51:5), okan wa a maa fa si ife ara wa ju ti Olorun lo. A ni lati be Olorun ki O we wa mo lati inu wa (Saamu 51:7), Ki O si kun okan ati emi wa pelu ero ati ife titun. AWON IBEERE 1. Bawo ni Olorun Metalokan se n mu iyipada ba wa? (Titu 3:4-6). Se alaye. 2. Kin ni ipa ti enikoookan n ko lati le ni iriri iyipada ti Olorun? Romu 12:1-2. Se alaye. ORO IPARI Kristeni je eda titun. Emi Mimo fun won ni igbesi aye titun, won di eni iyipada (2 Kor. 5:17). Fun iranlowo si ka 2 Awon Oba 17 & 25.

IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

  • Upload
    others

  • View
    0

  • Download
    0

Embed Size (px)

Citation preview

Page 1: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: IYIPADA TI OLORUN

IBI-KIKA: Esekieli 36:25-27

ALAYE ISAAJU

Iyipada ti Olorun je mo:

(a) Wiwe mo kuro ninu ese (ese 25)

(b) Siso okan di otun (ese 26)

(c) Gbigba agbara nipa Emi Mimo lati rin ninu ona Olorun (ese 27)

Olorun ti kilo fun awon omo Israeli lehin odun ti o ju irinwo odun lo ni oko eru ni Egipti pe “Bi

iwo ko ba fetisi ohun Oluwa Olorun re, lati ma kiyesi ati se gbogbo ase Re ati ilana Re.... a o si

si o kiri gbogbo ijoba aye” (Deut. 28:15, 25).

A fon won kaakiri opolopo orile-ede nitori aigboran won (2 Awon Oba 17:23). Sibesibe Esekieli

so asotele pe Olorun yo ko won jo lati orile ede gbogbo pada si ile ini won. Awon eni ibaje ati

olorun lile eniyan Israeli yii yoo di eni iyipada ti Olorun, ki ise nitori yiye won bikose nitori ife

Olorun Romu 5:8.

A tun so nipa iyipada Olorun yii ni Jeremiah 31:33-34. O was si imuse ni Majemu Titun ti Jesu

Kristi (Heberu 8:8-12; Heberu 10:16-17), eyi ti a fi idi re mule nipa itaje sile lori oke Kalfari

(Matteu 26:28). Nipase ise irapada ti omo Re yi, O we ese wa nu, O dariji wa, Emi Mmo Re si n

so wa di otun.

Nitori pe ninu ese ni a gbe bi wa (Saamu 51:5), okan wa a maa fa si ife ara wa ju ti Olorun lo. A

ni lati be Olorun ki O we wa mo lati inu wa (Saamu 51:7), Ki O si kun okan ati emi wa pelu ero

ati ife titun.

AWON IBEERE

1. Bawo ni Olorun Metalokan se n mu iyipada ba wa? (Titu 3:4-6). Se alaye.

2. Kin ni ipa ti enikoookan n ko lati le ni iriri iyipada ti Olorun? Romu 12:1-2. Se alaye.

ORO IPARI

Kristeni je eda titun. Emi Mimo fun won ni igbesi aye titun, won di eni iyipada (2 Kor. 5:17).

Fun iranlowo si ka 2 Awon Oba 17 & 25.

Page 2: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJI - OJO KETADINLOGBON OSU KINNI ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: MIMO KRISTI GEGE BI ODO AGUNTAN IRUBO WA

IBI-KIKA: Ifihan 5:1-14

ALAYE ISAAJU

Ohun ti a fi ye wa nipa iyipada ti emi ni fifi okan ti eran ropo okan okuta, eyi ti yoo fi agbara fun

awa eniyan lati maa se ife Olorun ki a le bo lowo iparun ti awon iranse Olorun, bi wolii Esekieli

ti so asotele re. Ohun ti o se pataki ni pe taa ni o ni agbara yii lowo ati bawo ni o se le te awa

eniyan lowo.

Ninu ibi kika wa, Johannu Aposteli se apejuwe yekeyeke iwe kan ti a ko, ti a si fi edidi meje di.

Iwe naa, “ni owo eni ti o joko lori ite” je akosile ohun gbogbo ti Olorun ni lokan fun araye.

Bi o tile je wi pe awon angeli ati awon agbaagba peju sibe “ko si enikan ni orun, tabi lori ile aye,

tabi nisale ile, ti o le si iwe naa tabi ti o le wo inu re” Ifihan 5:3. O se pataki fun wa lati mo pe

ALAIYE ni gbogbo awon eda ti o wa nibe. Lehin naa ni enikan farahan ti a pe ni kiniun ati odo-

aguntan. Odo-aguntan ti o ti jowo ara Re lati se ife Olorun nipa fifi emi Oun tikaraare rubo lori

igi agbelebu fun ese gbogbo araye. Oun nikan ni o ye lati si iwe naa, O si se be e gege.

Ni akoko Majemu Laelae, won maa n lo aguntan, bi o tile je wi pe ko kun oju iwon lati se etutu

fun ese awon eniyan (Heb. 10:11). Sugbon Jesu, Odo-Aguntan Olorun (Johannu 1:25) ni ebo

ikeyin, arukun ati aruda fun ese gbogbo araye (Heberu 10:12-14).

Isipaya Johannu yii fi idi otito nipa Jesu mule, gege bi Odo-Aguntan ti a fi rubo. Ohun ti o ku fun

wa ni lati gba otito yi gbo. Nipa bayii nikan ni a fi le jogun ileri Olorun lati fun wa ni okan titun

ati emi ti o to Ese 36:26.

AWON IBEERE

1. Kin ni yiye Odo-Aguntan lati si iwe naa fi ye wa? Ifihan 5:3, 12.

2. N je Isa. 53:7 fi omo Olorun han gege bi alailagbara? Jiroro.

3. Ninu ohun gbogbo ti Jesu so ati eyi ti O se, ewo ni o jo o loju ju gege bi Kristeni? Se alaye

ORO IPARI

Darapo mo ohun egbegberun lona egberun angeli lati ko orin ti o wa ninu Ifihan 5:12.“Yiye ni

odo-Aguntan na.....ati ogo ati ibukun”

Page 3: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETA - OJO KETA OSU KEJI ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: GBIGBA ISE IGBALA GBO

IBI-KIKA: Heberu 2:1-10

ALAYE ISAAJU

Ise igbala je mo ibi, igbe aye, ise iranse, iku ati ajinde Jesu Kristi. O ko le je Kristeni bi ko se pe

o ba ni ibere titun ti o da lori ise igbala ti Kristi muwa. Didi atunbi je ibere irin ajo Kristeni titi

yoo fi mu iyipada aye rere ba eniyan (Jn. 3:3-5).

Igbala ni fife lati ni ibasepo toooto pelu Olorun nipase Jesu Kristi. Enikookan gbodo se tan lati

gba tabi ko ihinrere, ko si eni ti o le je ajumo jogun ijoba orun nipa iran tabi ibatan. Ohun rere ni

lati ni awon obi ti o je onigbagbo, sugbon eyi ko tumo si pe a o ni igbala tabi igbe aye rere. O

gbodo gba Jesu gbo ki o si maa to O leyin.

Jesu nikan ni o ni oro iye naa. Lode oni opolopo eniyan ni o n wa igbala kaakiri ti won si ti so

Jesu orisun igbala tooto kansoso naa nu. Awon kan a maa se bi eni pe won n to Jesu leyin, won a

maa lo si ile ijosin nitori ipo, nitori ebi ati ore tabi nitori ise oro aje; sugbon idahun meji ni o wa

fun ipe Jesu Kristi - sise tan lati gba A gbo tabi ko O sile. Beeni ko si dara lati wa ni ipo kogbona

kotutu (Ifihan 3:15-16).

N je o ti je ipe Kristi? N je o se tan lati je igbadun igbala ofe ti Jesu ti se ileri re? Gege bi ipade

Jesu ati Sakeu ni Luku 19:1-9, ma jafara nitori ola lee pe ju fun o (2 Kor. 6:12).

AWON IBEERE

1. Ki ni awon ise igbala?

2. Igbala ki ise ohun ti o lee jogun lodo awon obi re. Jiroro lori eyi . (Fil. 2:12-13, Esekieli

14:20).

3. Ki ni ibasepo ti o wa laarin igbala ati iyipada. Jiroro lori eyi.

ORO IPARI

Orin akogbe: Maabo, ore mi maabo,

Maabo, ore mi jowo maabo,

Oni lojo igbala re,

Ola lee pe ju fun o

Maabo kiakia ko wa gba igbala ofe

Page 4: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERIN -OJO KEWA OSU KEJI ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: TITAYO JESU KRISTI

IBI-KIKA: Filipi 2:9-11, Kolose 1:15-19b

ALAYE ISAAJU

Titayo tumo si didaraju, yiyanju, ati lilola ju ninu ati lori ohun gbogbo ni iri ati ipo.

Titayo Jesu Kristi fi idi awon nnkan wonyi mule pe:

1. Jesu Kristi ni Oluwa awon oluwa ati Oba awon oba.

2. Jesu ga ju ohun gbogbo ni ti ipo oba, ola ati agbara, O si n se alakoso ohun gbogbo Isaiah

9:6-7, Heberu 1:8.

3. Jesu, Oruko ti O bori gbogbo oruko, agbara, ite, awon ijoye ati agbara okunkun. Fil. 2:9-11

4. Ohun gbogbo ni o wa nipa Re; Ikun ninu Olorun n gbe ninu Re. Nipase Re awa si di kikun.

Kol. 2:10.

5. Ori fun awon alufa, wolii, angeli. O si je Omo lori ohun gbogbo ni ile Oun tikalare. Heb. 3:6.

Jesu Kristi mo eni ti Oun I se, O si fe ki awon omo eyin Oun ni oye yii, nitori naa O beere eni ti

won fi Oun pe. Nipa itoni Emi Mimo, Peteru dahun wipe Iwo ni Kristi naa omo Olorun (Luku

9:18-20), Jesu si so wi pe lori eri yii ni Oun yoo ko Ijo Oun le. Pelu gbogbo itenumo oro imisi ti

Peteru so nipa Jesu ati awon ifidimule ninu ijewo igbagbo, oniruuru adura ati bee lo ti awa naa

maa n se, a ko fi gbogbo ara se afihan re ninu ise wa. Eyi tumo si wi pe enu ni a fi n jewo Re, ki

ise lati okan wa Matt. 15:8. Emi mimo ni O fi agbara fun Peteru lati jeri Jesu gege bi Kristi,

sugbon nigba ti eran ara lo o, o se Kristi. Bakan naa awa ko je ki ekun oye itayo julo Jesu Kristi

jinle ninu ookan aya wa nipase iyipada ti Emi.

A ni ogun rere ninu itayo ti Jesu Kristi ti esin, agbara, ite tabi awon Ijoye le koju tabi yipada. A

gbodo ni oye ki a si maa sise ninu imo yii ki a ba le je kristieni ti o kun oju iwon ti o n gbe igbe

aye iyipada.

IBEERE

1. Kin ni itumo titayo?

2. Bawo ni Jesu Kristi se tayo ninu ohun gbogbo? Johannu 1:1-3.

3. Kin ni awon abayo nigba ti a ba lo oruko Jesu pelu ekunrere igbagbo ninu titayo Re ninu

awon ipo wonyi?

a. agbara emi okunkun Saamu 114:7, Isaiah 64:2, Jakobu 2:19

b. igba aisan - Ise 3:1-8

c. igba itankanle Ihinrere - Ise 2:36-42

d. nigba adura - Johanu 14:13

ORO IPARI

Oluwa, Olorun, Alagbara julo, Je ki oye ati ifidimule titayo ti o wa ninu Oruko Jesu Kristi kun

ookan aya wa, ki a le gbe igbe aye iyipada ti Kristieni. Amin

Page 5: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KARUN-UN - OJO KETADINLOGUN OSU KEJI ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: IDALARE ATI ONA NIPA EJE JESU

IBI-KIKA: Romu 5:1-9

ALAYE ISAAJU

Idalare tumo si “siso diolododo tabi alailebi”. O fi iduro sinsin ati ipo ti o dara niwaju Olorun

han.

Ninu majemu laelae, awon alufa ati gbogbo ohun elo isin ninu tempili ni a maa n fi eje eran ti ko

ni abawon won (Heberu 9:21-22). Nipa eyi, awon ohun elo isin ati awon alufa paapaa yoo di

itewogba fun ise isin. Bakan naa, nipa igbagbo, eje Jesu (eyi ti ise Odo aguntan Olorun) ti so

alaimo di eni mimo, bee ni o si si ona fun wa lati wa si odo Olorun ati fun Olorun lati to wa wa

(Efesu 2:13& 18).

Eje Jesu je eri fun onigbagbo pe awon igbekale ofin ni Jesu ti mu se fun wa. Nitori eyi, Satani ti

padanu ni gbogbo ona lati fi wa sun niwaju Baba (Ifihan 12:10-11). Abayori siso di mimo

nipase eje Jesu je alaafia pelu Olorun, gbogbo idena lati to Olorun wa si ti kuro. Nitori naa,

igbagbo ninu eje Jesu ti mu itiju, iberu ati aiye niwaju Olorun kuro (Heberu 9:1-2;10).

Adura je ona pataki ti a fi le maa ri eto wa gba lodo Olorun. Nitori naa, ninu gbogbo adura wa, a

gbodo maa wo itoye ati ola Jesu Kristi nikan, ki ise ti ara wa. Eyi ko di wa lowo lati se ise rere. A

gbodo see (Efesu 2:10). Sugbon a ko gbodo naani ododo ara wa sugbon ododo Jesu ki Olorun le

gbo adura wa. Nitori idi eyi ni a se n gba adura ni oruko Jesu, ti o tumo si wi pe igbagbo wa n

wo itoye Jesu nikansoso.

AWON IBEERE

1. Kin ni idi ti o fi je wi pe nipase eje Jesu nikan ni a fi ni oore-ofe lati to Olorun wa?

(Johannu 14:6)

2. Tito Olorun wa nipa Jesu; se alaye itan agbowoode ati Farisi (Luku 18:9-14).

3a. Ododo Abrahamu nipa igbagbo mu un ye lati gbadura fun orile ede kan. Se alaye (Gen.

18:23-33)

b. Bawo ni awa naa se le gbadura ti o n se ise agbara fun awon omonikeji wa ati awon orile-ede

aye?

ORO IPARI

Fun idariji ese ati mimu ibanuje kuro, a nilo eje Jesu fun iyipada.

Page 6: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEFA - OJO KERINLELOGUN OSU KEJI ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: IGBE AYE TITUN NINU KRISTI

IBI-KIKA: 2 Kor. 5:14-20

ALAYE ISAAJU

Ibeere fun igbe aye titun ninu Kristi, toka sii pe igbe aye kan ti wa ri. Fun awa onigbagbo, igbe

aye wa atijo je iwa Adamu ti a n gbe ninu ara, eyi ti o lodi si Emi mimo Romu 8:5-8. Ni igba

laelae Olorun se eeto lati mu wa pada si odo ara Re nipa riran awon wolii Re Romu 3:10-13,

sugbon eniyan ko lati ronupiwada.Jesu nipa ife Re si araye jowo ara Re fun etutu ese wa, lai ka si

iwora lati bo ogo Re sile Fil. 2:6. Bi Olorun ba fi ife nla Re han fun wa, o ye ki a ku si ese aye

wa. A ko gbodo gbe igbe aye tite ara eni lorun nikan, sugbon ki a te Olorun lorun ninu Kristi

Jesu Olugbala wa 2 Kor. 5:15.

Nigba ti a ba gbagbo, ti a si gba Jesu ni Olorun ati Olugbala wa a ti gba Emi Mimo, a si ti di eda

titun. “Ki e ma si da ara yin po mo aye yi: sugbon ki e parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki eyin

ki o le ri idi ife Olorun, ti o dara, ti o si se itewogba, ti o si pe” Romu 12:2.

Nitori naa, awa ti di iko fun Kristi (v20) ti o ni lati so eso ki a si tan ihinrere ilaja fun awon

elomiiran. A gbodo je olooto ti yoo fi ife ati ise rere Olorun han, ti yoo fi wa han gege bi

onigbagbo ti o ni igbe aye otun Heb. 10:24.

AWON IBEERE

1. Jiroro idanimo (a) igbe aye ti ara (b) igbe aye otun Kol. 3:1-11.

2. Kin ni o ye ki o je ise wa gege bi iko fun Kristi ni ode oni Efesu 4:21-22, 2 Korinti 5:19-20.

ORO IPARI

A gbodo je ki emi ti o ji Jesu dide kuro ninu oku so ara kiku wa di aaye fun igbe aye ibamu pelu

Kristi.

Page 7: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJE - OJO KEJI OSU KETA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: IFARAHAN IGBE AYE TITUN NINU KRISTI - IDAGBASOKE TI EMI

IBI-KIKA: Romu 12:1-2, Heberu 5:12-6:3

ALAYE ISAAJU

Igbe aye titun ti bere ni kete ti eniyan ba ti gba Jesu Kristi ni Oluwa ati Olugbala Re. Nitori naa

bi enikeni ba wa ninu Kristi o di eda titun, ohun atijo ti koja lo, kiyesi i won si di titun 2 Korinti

5:17.

Iyipada atorunwa ninu eniyan yoo fun un ni okan titun ati emi titun ti yoo fi aaye sile fun iyipada

ninu aye eni naa Esekieli 36:26. Igbe aye titun ninu Kristi yoo mu opolopo idagbasoke wa eyi ti

yoo farahan ninu bi eniyan yoo se maa fi oye gbe ohun ti o n sele. Yoo dagba kuro ninu mimu

wara ti yoo si maa je ounje lile nitori awon ti o ti dagba ni ounje lile wa fun Heberu 5:14.

Oye ti o ye kooro ni a o maa ri ninu eni ti o ni idagbasoke nipa ti emi I Korinti 14:20, eyi ti o

tun je afihan igbe aye titun ninu Kristi, Romu 6:1-4. Siwaju si i yoo yera kuro ninu awon ohun ti

o je ti ara, ti ko si ni darapo mo ohun ti aye yii 12:2, yoo si maa ronu nipa ohun ti orun ninu

irinajo re lojoojumo.

Kristeni ti o ti dagbasoke nipa ti emi yoo maa fa awon elomiran si odo Jesu. Yoo maa so fun

awon elomiran bi oun ti to Jesu wo ati bi O se dun to Orin Dafidi 34:8. Bi eni naa se n fi ife,

iteriba ati itoju han fun awon elomiran yoo je ami idanimo Jesu ninu aye re. Ihuwasi yii yoo mu

ki awon ti o n lo si orun apadi dinku ti awon ti o n lo si ijoba Olorun yoo si maa po si, gege bi

Kristi se pa lase fun wa ni Matteu 28:19-20.

AWON IBEERE

1. Ki ni awon ohun ti yoo mu ki eni ti o ti dagba nipa ti emi tayo laarin awujo?

2. N je didagbasoke nipa ti emi le gba wa lowo (i) ese (ii) ibanuje? Jiroro.

3. N je nini igbe aye titun ninu Kristi nikan to lati mu awon elomiiran wa sodo Kristi? Jiroro.

ORO IPARI

A ko gbodo je Kristeni ti yoo maa mu wara nikan. A gbodo gbiyanju lati dagba soke.

Page 8: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJO - OJO KESAN OSU KETA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: ERI IGBE AYE TITUN NINU KRISTI - SISO ESO

IBI-KIKA: Kol. 1:3-10

ALAYE ISAAJU

Titi ti Jesu fi di Olugbala wa, ota Olorun ni a je. Igbe aye titun ninu Kristi je iriri emi ti o so wa

di eni iyipada titi aye II Kor. 5:17. O je igbe aye iyipada si aworan ati jijo Kristi.

Igbe aye titun ninu Kristi a maa so eso, a maa farahan nipa isodotun emi, okan ati aapon lati jeri

okan si ijoba orun.

Eri siso eso wa nipa ti ara ati ti emi:

Ti emi n farahan nipa ife, ayo, alaafia, ipamora, iwapele, isoore, igbagbo, iwa tutu ati ikora-eni-

nijanu Gal. 5;22-23a.

Eri ti ara n farahan nipa: ipejopo onigbagbo, eko Bibeli, bibe awon alaisan ati awon alaini wo,

isoore, iranlowo si omonikeji, irele ati idariji.

Igbe aye titun ninu Kristi je aye ti o jowo ara eni fun Un ati ti o wa ni ibamu pelu ife Olorun eyi

ti o je siso eso Gen. 1:28.

AWON IBEERE

1. Kin ni awon iriri ami ti o n fi igbe aye titun ninu Kristi han?

2. Igbe aye titun ninu Kristi ko le je alaileso. Jiroro Saamu 1, Johannu 15.

ORO IPARI

Eso siso atorunwa je ipinnu Olorun fun araye. Eso siso je ami idagbasoke. A ni lati ma dagba si

ninu Kristi.

Page 9: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KESAN - OJO KERINDINLOGUN OSU KETA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Nini Oye Nipa Iyipada Ati Ilana Re

KOKO ORO: ERI IGBE AYE TITUN NINU KRISTI- IMUPADABOSIPO

IBI-KIKA: Joeli 2:23-27

ALAYE ISAAJU

Ninu awon ayewo ti o koja, a ka nipa awon anfaani igbe aye titun ninu Kristi eyi ti o je abayori

iyipada lati orun wa- idagbasoke nipa ti Emi ati siso eso ti Emi. Eko ti oni da lori imupadabosipo,

eyi ti o je ileri Olorun fun awon onigbagbo.

Ileri Olorun si eniyan je pipe nitori ko fa ohunkohun seyin. Bibeli so pe; bi awa ba yipada sodo

Oluwa Olorun wa, ti a si feti si ohun Re gege bi gbogbo ase Re, ti a si sin In pelu gbogbo okan

wa, nigba naa ni Oluwa Olorun wa yoo yi igbekun wa pada yo O sanu fun wa, yo O mu wa bo

sipo, yo O si ko wa jo lati orile ede gbogbo ti Oluwa Olorun ti tu wa ka si (Deut. 30: 2-3). O si

tun se ileri pe Oun yoo mu “odun wonni pada fun yin wa, eyi ti esu on iru kokoro jewejewe, ati

iru kokoro keji, ati iru kokoro jewejewe miiran ti fi je, ...”(Joeli 2:25). A ri apeere miiran ninu

igbe aye Jobu eni ti Olorun da ikolo re pada nitori pe o duro sinsin, o si je oloooto omo odo.

Nitooto, Olorun si fun un ni ilopo meji ohun ti o sonu, igbeyin aye Jobu kun fun ibukun ju ibere

aye re lo (Jobu 42: 10).

Ki a ba le gbadun awon anfaani ti o wa ninu ileri Olorun lori imupadabosipo ni ekunrere, a

gbodo gba Olorun gbo ki a si jewo Olorun gege bi Oluwa (Romu 10:10). Siwaju si, Romu 10:11

so pe “Oju ki yoo ti enikeni ti o ba gba A gbo” Eyi tumo si pe eni ti o ba gbekele Oluwa

patapata yoo gbe igbe aye iyipada ki yoo si kabamo ni gbogbo ojo aye re.

AWON IBEERE

1. Kin ni awon afiyesi fun imupadabosipo pipe? Se alaye

2. Kin ni awon anfaani imupadabosipo pipe? Romu 10:9-11; Johannu 5: 5-9

3. Se afiwe iyipada ati imupadabosipo. Kolosse 2:10

ORO IPARI

Igbesi aye ti o wa lati odo Olorun leyin igba ti a ti yi pada je kikun ati pe kiki awon ti Olorun ba

ti yi pada ni o le gbadun re.

Page 10: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEWAA - OJO KETALELOGUN OSU KETA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: MAJEMU LAELAE

IBI-KIKA: Eksodu 19:1-8; 24:1-11

ALAYE ISAAJU

Majemu je adehun tabi ileri laarin awon egbe meji tabi ju bee lo, eyi ti o ni igbekale ati ironu

ninu. Ibi kika wa da lori Majemu ti a ti owo Mose fi lole, sugbon awon Majemu laelae miiran wa

gege bi ti Abrahamu, Noa ati bee bee lo. Majemu pelu Abrahamu da lori igbagbo ati ifokansin ti

o ni ninu Olorun ti a si ka si ododo fun un. Olorun fi oro Majemu ti ko ni asomo lole pelu

Abrahamu ni idahun si bi Abrahamu se fe fi omo re Isaaki rubo (Gen. 22:17-18).

Ibi kika wa ti oni da lori Majemu ti Mose ti o ni asomo. Olorun gbe awon omo Israeli le iye apa

owo Re, O si fi owo agbara mu won jade kuro ninu oko eru Egipti. O fun won ni awon ofin lati

pamo, o si ba won da Majemu pe “... bi eyin ba fe gba ohun mi gbo nitooto, ti e o si pa majemu

mi mo, nigba naa ni eyin o je isura fun mi ju gbogbo eniyan lo, nitori gbogbo aye ni ti Emi. Eyin

o si maa je ijoba alufa fun Mi...” Eksodu 19:5-6.

Majemu ti Mose da lori imuse awon ofin ati ilana Olorun ti a fi lele ninu iwe Deut. 28. Ni afiwe

Majemu ti a se pelu Abrahamu ti o da lori iwa igbagbo, Majemu ti Mose ni a se nitori iwa

aigboran, aigbagbo ti a ri ninu aye awon omo Israeli leyin igba ti Olorun mu won jade kuro ni

Egipti.

Ibuwon eje eran je ipa pataki ninu Majemu ti Mose, Mose tenumoo wi pe “eje Majemu ti Oluwa

Olorun yin ba yin da”Eks. 24:8. Eje naa ye ki o mu ese awon omo Israeli kuro, nitori laisi

itajesile ko si idariji ese. Heb. 9:22. Sugbon Majemu tita eje eran sile yii ko pe fun imukuro ese.

AWON IBEERE

1. So ninu awon Majemu ti Olorun da pelu awon eniyan Re Gen. 22:!7-18, Gen. 9:8-17;

Eksodu 15:26, 19:5-6, 2 Sam. 7:12-16.

2. So Majemu ti Olorun da pelu Abrahamu, ki o si fi we Majemu ti O da pelu Mose, Gen.

15:18-21; Gen. 22:17-18; Eksodu 19:5-8.

3. N je awon omo Israeli mu awon ilana Majemu Olorun se? Jiroro.

ORO IPARI

Olorun maa n pa ileri Re mo. O si fe ki a gbe aye igboran ki a si gbadun Majemu ti O ba wa da..

Page 11: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KOKANLA - OGBON OJO OSU KETA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: EETO AWON ALUFA

IBI-KIKA: Eksodu 28:1-3

ALAYE ISAAJU

Ninu Majemu Laelae, ona merin otooto ni a fi n pe eniyan tabi fi ami ororo yan eniyan, bi i

ifami-ororo yan ti oba (I Sam. 10:1) ifami-ororo yan ti wolii, (Oba Kini 19:16b), ifami-ororo yan

ti alufa Lefitiku 8:12 ati ifami-ororo yan fun akanse ise bi ti Samsoni Onidajo 13:7, ati Baseleli

Eksodu 31:1-5.

O je ohun idunnu pe ninu gbogbo awon ipe yi, ti alufa ni a fi mo eya kan. Enikeni ninu eya

Israeli le di wolii, oba, ati ohun elo fun akanse ise fun Olorun. Sugbon Aaroni ati awon omo re

okunrin, nikan ni a le pe si ise alufa. Ipe ti a ya soto ni fun idile yii. Ni pataki, Olorun paa lase

fun Mose lati ran aso mimo ati eleso daradara fun won. Ogun rere ni eniti a bi sinu eya Lefi ni,

nitori a le fi ami ororo yan won si ipo alufa tabi olori alufa, won a si ni awon anfaani wonyi:

Gege bi Numeri 18 ati Lefitiku 21 se so

- won ko ni kopa ninu awon ise ti o lagbara

- won a maa gba idamewa ati ohun akoso lati odo awon elomiiran

- won yoo ma se akoso pinpin awon ebun ati ore

- awon nikan ni a fun lase lati le sise ninu ati ni ayika ibi mimo

- won a je iko, ti o n fi adura jagun fun awon elomiran

- won a maa gbe, aye iya ara eni si mimo

Gbogbo onigbagbo ni lati mo eni ti won je ninu Oluwa. A i ni oye oro Olorun je ki opolopo

onigbagbo padanu jije ibukun alufa Olorun. Gege bi alufa, o ye ki a te eekun wa ba lati gbadura

fun awon ti ko i ti gbagbo, ki a le se atilehin fun Olori Alufa naa Jesu Kristi ninu ise alagbawi

Re.

AWON IBEERE

1. Awon eto ise alufa melo ni a ri ninu Bibeli? Ekso. 28:1-3, Heb. 6:20

2. Ninu I Pet. 2:9 ati Ifihan 1:6, kini idi ti Bibeli fi n pe gbogbo Kristeni ni alufa nigba ti ki i

se gbogbo wa ni a wa lati eya Lefi tabi ti a fi ami ororo yan gegebi alufa ni ile ijosin.

3. Se apejuwe ipo Alufa Jesu Kristi ninu awon ibi kika yi Heb. 7:17, Matt. 27:50-51, Heb.

10:14, Heb. 7:24-25, Ifihan 1:5-6.

ORO IPARI

Nitori a ko ni olori Alufa ti ko le sai ba ni kedun, nitori naa e je ki a wa si ibi ite oore-ofe pelu

igboya, ki a le ri aanu gba, ki a si ri oore-ofe lati maa rannilowo ni akoko ti o wo Heb. 4:15-16.

Page 12: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJILA - OGUNJO OSU KERIN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: EETO AWON WOLII

IBI-KIKA: Eksodu 3:1-14; Deuteronomi 18:15-22

ALAYE ISAAJU

Tani a le pe ni wolii? Woli je eni ti o darapo mo esin kan (gege bi Kristeni, Esin awon Juu, Esin

Baali ati bee bee lo) ti o n je ise ti a gbagbo pe o ti odo Olorun wa. O tun je eni ti o n so awon oro

ifihan ti o ti odo Olorun wa.

Ninu Bibeli, Mose ni eni akoko ti Olorun diidi pe lati je ojise fun Oun (Eksodu 3:1-10). O si wa

je awokose fun gbogbo awon wolii ti won tele e (Deut. 18:15, 18).

Apapo igbe aye, bii ihuwasi ni awujo ati ibowo esin, ni o je okunkundun fun awon wolii ninu

Bibeli. Opolopo ninu won ni won ko ipa pataki ninu oro oselu ni akoko won. Nitori awon wolii

tooto a maa je ise ti Olorun ran won, eyi fun won ni igboya lati dojuko awon oba, awon alakoso

ilu ati awon eniyan ni akoko won (2 Sam. 7:12; I Awon Oba 1:11-14; 2 Kronika 29:25). Won

gbagbo pe oro ti awon n so ki i se ero Olorun lasan sugbon pe oro ti o le mu iyipada otun wa fun

awon ohun ti o n sele.

Ki i se siso asotele nikan ni a ran awon wolii, sugbon ki won tun le so ero Olorun lori awon ohun

ti o n sele lowolowo. Opolopo awon wolii inu Bibeli ni won bere ise ojise won nipa siso asotele

lori awon ohun ti yoo sele lójo iwaju (Amosi 1:1-2). Iran won nipa ibinu Olorun ti o n bo je ipe si

ironupiwada nigba ti iran nipa alaafia ti n bo je ipe si itesiwaju otito sise. Eyi ni o mu ki awon

wolii wonyi yato si awon aworawo awon keferi ti won maa n so asotele iro. Awon ise ti a fi ran

awon wolii yi je iranlowo lati yi Israeli pada ni orisirisi ona. Opolopo awon awujo ati enikookan

ni a ti ti ipa bee yi pada si rere.

Johannu onitebomi ni o kehin awon wolii ti majemu laelae (Matt. 11:13). Oun ni eni ti o fi Jesu

han gege bi Olugbala araye (Johannu 1:29). Jesu paapaa gba lati pe ara Re ni wolii (Matt.

13:57; Luku 13:44). Awon omo eyin Jesu naa gba ebun emi isotele, nigba ti Emi Mimo ba le

won ni ojo Pentikosti (Ise Awon Aposteli 2:2). Ogunlogo awon eniyan ni won ti gba ebun emi

isotele ti won si ti loo fun iyipada rere ni awujo.

AWON IBEERE

1. Bawo ni a se le mo boya wolii je ti Olorun tabi be ko? Deut. 13:1-4; 18:21-22.

2. Nje a si ni awon wolii tooto lode oni?

3. Kin ni idi ti Olorun fi ran awon wolii si Israeli ati si awa naa? I Awon Oba 17:1.

ORO IPARI

E mase kegan isotele. E maa wadi ohun gbogbo daju; e di eyi ti o dara mu sinsin. I Tessalonika

5:20-21.

Page 13: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETALA - OJO KETADINLOGBON OSU KERIN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: APOTI ERI

IBI-KIKA: Eksodu 25:10-22

ALAYE ISAAJU

Olorun pase ki a se Apoti Eri ti yoo je ami wi pe oju Oun wa ni aarin awon omo Israeli. Nigba

majemu laelae, ohun ti oju le ri ni a ma n lo lati je ki won mo wi pe Olorun wa laarin won. Eyi ri

be, nitori Jesu ko i ti wa ni awo eniyan ati wi pe igba itusile Emi Mimo ko i ti de. Olorun a maa fi

ibi ti oye eniyan mo lati fun won ni iyipada.

Olorun pase yekeyeke fun won bi won yoo se kan apoti eri ati awon ohun ti yoo wa ninu re.

(i) Ara apoti eri yoo je igi sittimu (v10) - Eyi je ami wi pe apoti naa ko ni tete baje

(ii) Won o fi kiki wura bo o (v11) -Eyi tumo si ohun mimo ti ko ni abawon

(iii) Oruka wura merin (v12) -O fun wa ni oye igun mereerin aye, afefe merin ti o

wa lati ona mereerin aye. Eyi fihan pe ohun gbogbo

wa labe akoso Olorun.

(iv) Awon eri ti Olorun fifun won (v16) -Eyi tumo si eni ti Olorun je: Alaanu, Olododo, Eni

didara, iyonu Re kii kuna ati Onidajo ododo, Ife ati

Mimo.

(v) Awon Kerubu (v18-20) -O duro fun ipese, aabo, ipamo Olorun.

Awon ase ati ifilole yii ran awon eniyan lowo lati ni oye iberu ati isin tooto si Olorun. Won wa ni

ibamu pelu Eri Olorun ti o wa ni ookan aya wa, lehin ti Olorun ti mu okan okuta kuro ninu wa ti

O si fun wa ni okan eran ti a fi ni awon nnkan wonyi:-

(i) Okan mimo ati ero rere

(ii) Ife si gbogbo eniyan ni igun mereerin aye

(iii) Ki a le duro gege bi ajeri ati asoju Re ninu aye yii

(iv) Mimo O, titele E ati gbigbonran si I

(v) Gbigbe igbe aye Kristeni ti o ti yipada lati se ife Re.

AWON IBEERE

1. Kin ni apoti eri je ati kin ni o duro fun. Ekso. 25:22, 33:14

2. Nibo ni apoti eri Olorun wa nisinsinyi - Johannu 4:16-18, I Korinti 3:16.

3. Se apejuwe awon ohun ti a maa ri ninu

a) apoti eri ti majemu laelae

b) apoti eri ti majemu titun (ookan aya)

Kin ni won duro fun?

ORO IPARI

Okan wa je apoti eri ti Emi Mimo n gbe, ti o si n dari wa lati gbe igbe aye iyipada ninu Kristi.

Page 14: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERINLA - OJO KERIN OSU KARUN-UN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: ISIN IPAGO

IBI-KIKA: Eksodu 40:1-38

ALAYE ISAAJU

Ago je ibi iyasoto ti awon omo Israeli ti n pade, lati sin Olorun. Olorun pa ase fun Mose lati pa

ago naa gege bi apeere ti o fi han an lori oke Sinai (Eksodu 25:9, Heb. 8:5). Ona meta pataki ni a

da ago naa si, ibi mimo julo, agbede meji ago ati agbala ti o yi ago ka. Gbogbo eniyan ni o le wo

agbala. Awon Alufa nikan ni o le wo agbede meji, nigba ti ibi mimo julo je ibi ti a paala fun, ti o

je ibi ti olori Alufa nikan le wo. Awon ohun eso ago naa ni apoti Eri, pepe turari, pepe adalu,

tabili fun akara ati opa wura fun fitila.

Ago yi je ibi ti awon eniyan ti maa n wa oju Oluwa nipa yiya ara won soto, fifo ara won mo, ati

sise ara won lokan labe akoso Olorun. Ise ti O yan fun awon omo Lefi ni lati maa se itoju ati ki

won maa gbe ago lati ibi kan de omiran (Num. 1:50-52; 3:1-4, 49). Ikuuku ati ina afonahanni a

maa duro lori ibi ti a gbe ago sile si nigba ti awon eniyan ba pa ago, a si maa to won sona nigba ti

won ba n rin.

Ninu isin ago, aye wa lati ni idapo pelu Olorun, se etutu fun ese ati sisan ore. Bibeli ko wa wi pe

lai si itaje sile ko si etutu fun ese. Nigba ti isin ipago je mo fifi eran osin rubo (Heb. 9:22), iku

Jesu Kristi lori igi agbelebu je arukun ati aruda ebo naa. Eyi mu iyipada otun wa si isin ninu

majemu titun.

AWON IBEERE

1. Kin ni pataki ati idi fun ipago?

2. Kin ni ibi meta otooto ti Olorun n gbe nisinsinyi ati nibo ni a ti le ba Olorun pade? (Joh.

2:18-22, 1 Kor. 3:16-17, Efesu 3:16-17a, Matt. 28:19-20)

3. Bawo ni elese se le to Olorun lo lati di eni iyipada? (Heb. 10:19-25)

4. N je ibasepo kan wa laarin Jesu ati ipago? (Johannu 10:9, 1:29, 8:12, 6:35).

ORO IPARI

Olorun ti fi aaye ati ba Oun ni asepo fun wa (Jakobu 4:8). O ti fun wa ni awokose lati sin In ni

otito pe ki igbe aye wa le je mimo ati itewogba ti o tona niwaju Re Romu 12:1.

Page 15: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEEDOGUN - OJO KOKANLA OSU KARUN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: IKOLA

IBI-KIKA: Gen. 17:9-14

ALAYE ISAAJU

Ikola ni yiyo awo oju ara okunrin nitori esin tabi fun imototo. Ikola ninu Majemu Laelae ni ami

majemu ti o wa laarin Olorun pelu Abrahamu Gen. 17:10. Nigba ti Olorun so fun Abrahamu wi

pe ko ko ila, ojo ori re ti koja ti omo bibi. Iyanu ibi Isaaki je kokoro si oye bi ikola se je ami

majemu. Nigba ti Abrahamu ati idile re kola, Olorun paa lase pe gbogbo omokunrin ti o ba ti pe

omo ojo mejo, a gbodo kola fun won (Gen. 17:12).

Ninu ofin Mose, won tumo ilana naa fun awon omo Israeli pe ki won ko aya won n’ila (Deut.

10:16). Eyi je ilana ti iyipada. Ipe yi ni won nilo lati se idanimo ami majemu ati pe o pon dandan

fun won lati se afihan ifaramo ti emi ati igboran si ife Oluwa. Jeremiah pa ase kan naa fun awon

elegbe re nitori iwa buburu won, eyi ti o lodi gedegbe si ohun ti Olorun fe Jer. 4:4. Fun un, ikola

je iyasimimo fun Olorun ati ifaramo iwa pipe ninu majemu, eyi ti iwa mimo je pataki Lef. 11:44.

Eyi naa je ipe si igbesi aye ti a yipada.

Ikola je ami nla fun awon Juu, ti Olorun pinnu lati fi se aami ini Re fun ohun elo ibukun fun

awon orile-ede miiran. A ko o si eya ara pataki yii fun itoka pe ki won ya ara won soto laarin

orile-ede miiran. Eya ara yi, nipa eyi ti a fi le rufin, ni aami lori re wi pe Olorun ni O nii. Bi o tile

je wi pe ikola je ami ita, o fi itewogba jije ti Olorun han.

AWON IBEERE

1. Bawo ni ikola se beere ninu Bibeli?

2. Kin ni idi re ti ikola se je nkan pataki ninu Majemu Laelae?

3. Se ikola wa fun elomiran? Jiroro (Jer. 9:25-26).

4. Kin ni igbe aye ikola se ye o si? (Romu 12:1-2)

ORO IPARI

E ko ara yin ni ila fun Oluwa, ki e si mu awo ikola okan yin kuro (Jer. 4:4)

Page 16: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERINDINLOGUN - OJO KEJIDINLOGUN OSU KARUN-UN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: EBO ATI ORE

IBI-KIKA: Lefitiku 1:1-17

ALAYE ISAAJU

Iwe Lefitiku je iwe itosona fun awon Alufa ati omo awon omo Lefi nipa ise isin won. O tun je

itosona igbe aye mimo fun awon Heberu, ninu eyi ti Ebo ati Ore je pataki.

Ninu iwe Lefitiku, awon omo Israeli pago si abe oke Sinai lati ko eko nipa pataki titele Olorun bi

won se n mura irinajo won lo si ile ileri. Olorun n ko won bi won o se gbe igbe aye eniyan mimo.

Ko je iyalenu pe a soro “Iwa Mimo” ninu iwe Lefitiku ni opolopo igba (152) ju iwe miiran ninu

Bibeli lo.

Ebo ati Ore wa fun ise isin, idariji ese ati igbe aye mimo. Nipa ebo ati ore a ko eko bi ese se

wuwo to ati ona ati se etutu fun ese. Niwon bi ko ti le seese fun wa lati se etutu fun ese ara wa,

ati pe itaje sile gbodo wa fun imukuro ese, majemu laelae lana lati fi eran osin se irubo. Eyi wa

fun igba die titi iku Jesu fi san igbese ese fun gbogbo eniyan titi ayeraye.

“Fi Jesu Kristi, Omo Re nikan

soso funni lati jiya iku lori agbelebu

fun idande wa, (nipa ebo kan ti

o fi ara Re ru lekansoso) Eni ti

o ru ebo itenilorun, Ebo arukun,

ati aruda, ebo ti o to fun ese gbogbo aye”

(Idapo Mimo - iwe Adura Yoruba)

Niwon igba ti Olorun ti fi Omo Re kan soso Jesu Kristi rubo, awa naa je E nigbese ebo igbe aye

wa (agbara, akoko, ebun, owo, ati bee bee lo) Romu 12:1-2.

AWON IBEERE

1. Kin ni ebo ati ore ko awon eniyan?

2. Kin ni idi ti ilana fini fini fi wa fun ore kookan? Lefitiku 1:3-13

3. Israeli nikan ko ni orile-ede ti o n fi eran osin rubo; titi di asiko yi opolopo esin ati asa

atowodowo maa n bere fun ebo. Kin ni iyato laarin ebo ti awon omo Israeli ati awon eniyan

miiran.

4. Ebo Jesu Kristi to fun etutu ese. Se alaye.

ORO IPARI

Eniti a se pupo fun ni a o bere pupo lowo re.

Page 17: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETADINLOGUN - OJO KARUNDINLOGBON OSU KARUN-UN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: IPO ATILEBA ATI ISUBU ENIYAN

IBI-KIKA: Gen. 2:7-17, 3:1-23

ALAYE ISAAJU

Dida ni a da eniyan. Olorun fi erupe ile mo eniyan, O mi eemi iye si iho imu re, eniyan si di

alaaye okan. Gen. 2:7.

Ninu itan iseda aye, a ka nipa igi imo rere ati buburu. Olorun pase pe Adamu ati Efa ko gbodo je

ninu eso igi naa. Sugbon ejo (Satani) Ifihan 12:9 tan Efa je, oun naa si ro oko re Adamu lati je e.

Ise owo Satani ni lati maa tan eniyan je. O maa n lo orisirisi ete gege bi ohun ti o sele ni akoko

naa. Nipa ti Efa, Satani mu u ki o siyemeji nipa ojurere Olorun. Olorun kanna ti O da Adamu ati

Efa, ti O fi won sinu ogba daradara ti o ni alaafia, ti O pese fun aini won, ti O si maa n be won

wo loorekoore ni Satani gbe kale gege bi Eni ti O mo ti ara Re nikan Gen. 3:5. O se ni laanu wi

pe Satani tan Adamu ati Efa je, o mu won dese, eyi si fa isubu gbogbo eniyan.

Aigboran ni o fa isubu eniyan. O seese ki idi ti Olorun fi pase fun Adamu ati Efa ma ye won,

sugbon won ko nilo Satani lati fi ye won. Ohun ti o ye fun won ni lati gba Olorun eleda won

gbo, sugbon won kuna, nipa bee gbogbo eniyan jogun iwa aigboran. Romu 5:12.

Mimo ni Olorun, Oun ko si le e bojuwo ese. O gegun fun ejo (Satani), O pase ijiya fun Efa, O

gegun fun ile nitori Adamu, O si le Adamu ati Efa jade kuro ninu ogba Edeni (Gen. 3:14-19, 22-

24). Sugbon ni ese 15, O fi ileri kan pamo ninu egun naa, eyi ti i se ileri Oludande, eni ti yoo yo

wa kuro ninu ipo isubu, ti yoo si ran wa lowo lati gbe igbe aye iyipada otun.

AWON IBEERE

1. Se alaye die ninu awon ona ti Satani n gba lati tan eniyan je.

2. Fife lati te ara wa ati awon elomiiran lorun, a maa yori si ese nigba miiran. Jiroro (I Sam.

8:19, 15:15-19)

3. Kin ni abajade isubu eniyan?

ORO IPARI

Asiko kan a maa wa ti ese wa yoo de oju iwon ti idajo yoo si to si wa. Iyipada okan tooto nikan

ni abayo.

Page 18: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJIDINLOGUN - OJO KINNI OSU KEFA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: PIPA AWON ENIYAN AKOKO RUN ATI IBERE TITUN

IBI-KIKA: Gen. 6:1-8, 7:13-24, 8:15-22

ALAYE ISAAJU

Aigboran Adamu ati Efa ati isubu won niwaju Olorun ni o ko ba gbogbo eda. Igbe aye ninu ogba

Edeni dabi Paradise ti aye. Iba se pe Adamu ati Efa ti gboran si Olorun ni, o see se ki won wa

ninu ogba naa titi ayeraye. Lehin isubu won, aye ko wa si ni Paradise rere ti Olorun fe ki o wa,

nitori olukuluku ni o n se ohun ti o wu won ti won si gbagbe Olorun. Amo sa, Noa sin Olorun o

si ri ojurere Re. O ba ni leru lati rii pe ko pe rara ti gbogbo eda fi gbagbe Olorun. Nitori ododo ati

igboran re, Olorun pa Noa ati idile re mo ninu ikun omi ti o pa gbogbo eda alaaye ati eweko run.

Inu Olorun baje nitori ti o da eniyan sinu aye (Gen. 6:6-8). Ohun edun ni o je fun Olorun pe

awon eniyan yan ese ati iku dipo ajosepo ti o peye pelu Oun. Ese wa maa n bi Olorun ninu gege

bi o ti ri ni igba aye Noa. Bi o tile je pe inu aye ese ni a wa, a le tele apeere Noa ki a si ri

“ojurere lodo Olorun”.

Olorun rii pe iwa buburu awon eniyan n po sii lojojumo, nitori naa O pase fun Noa pe , “opin

gbogbo eniyan de iwaju mi; nitori ti aye kun fun iwa-agbara lati owo won; si kiyesi, emi o si pa

won run pelu aye”.(Gen. 6:13). Olorun pase fun Noa pe ki o kan oko, Noa si se gege bi Olorun ti

paa lase fun. Leyin ti ohun gbogbo ti se tan, pelu awon eranko ati eye. O pase fun Noa pe ki o wo

inu oko naa nitori leyin ojo meje, ojo ogoji ojo yoo ro ti yoo si pa gbogbo ohun ti n be lori ile

run. Ohun gbogbo ni o wa si imuse gege bi Olorun ti paa lase. Ikun omi yii ni o mu iparun de ba

gbogbo aiye akoko naa. Nigba ti ikun omi naa gbe lori ile, Olorun pase fun Noa pe ki o jade ninu

oko pelu gbogbo ohun ti o wa ninu oko naa, ki won ba le maa bi sii, ki won si maa re sii lori ile.

Eleyi ni ibere aye titun. Olorun si ba Noa da majemu pe Oun ki yoo fi omi pa aye re mo (Gen.

9:11-17).

AWON IBEERE

1. So awon idi ti Olorun fi pa aye akoko run?

2. N je ile aye ti isisiyi dara ju igba aye Noa lo? Jiroro lori eyi.

ORO IPARI

“Nipa igbagbo ni Noa, nigba ti Olorun kilo ohun ti koi tii ri fun, o beru Olorun, o si kan oko fun

igbala ile re, nipa eyi ti o da aye lebi o si di ajogun ododo ti ise nipa igbagbo”(Heb. 11:7).

Page 19: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KOKANDINLOGUN - OJO KEJO OSU KEFA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: ESE ADALE, ADALE AWON OMO ISRAELI ATI KIKONI NI

IGBEKUN LO SI BABILONI

IBI-KIKA: Deut. 28:36-41, 2 Awon Oba 24:11-16

ALAYE ISAAJU

Nigba ti o ku die ki won de ile-ileri, leyin irin kiri awon omo Israeli fun ogoji odun ninu aginju,

iwe Deuteronomi tun ran won leti majemu Olorun pelu awon eniyan Re - Israeli. Bi o ti le je wi

pe Olorun mu won de ile ileri ti o kun fun wara ati oyin, o se ni laanu pe awon eniyan yi ko ko

ipa tiwon ninu majemu naa.

Ni ibi kika wa Deut. 28:36-41, Mose so fun awon omo Israeli awon ijiya ti o wa ninu aigboran

won ni gbogbo igba. Ese adale adale awon omo Israeli mu ki Olorun binu si won o si je ki awon

ara Babiloni ko won ni igbekun (Rom. 6:1).

Asa awon ara Babiloni nipa kiko ni ni igbekun yato si ti awon Assiria ti won maa n fi awon ajeji

ropo awon omo Israeli ni ile won. Awon ara Babiloni ni tiwon, a maa ko awon ti o lagbara ati

oloye, won a si fi awon alaani ati awon ti ko lagbara sile. Won a maa gba awon igbekun laaye

lati gbe papo, lati sise ki won si di eni pataki laarin awujo. Asa yi je ki awon Ju wa ni irepo ati se

ododo pelu Olorun ni gbogbo asiko ti won fi wa ni igbekun, eyi ni o je ki o seese fun won lati

pada si ile ni asiko Serubabeli ati Esra gege bi a ti ko sile ninu iwe Esra.

Ni aye yi ati aye ti n bo, igboran ni ere bee ni aigboran ni ijiya ti o ba ni leru. Bi o ti wu ki o ri,

ipadabo awon Israeli fun won ni aaye fun iyipada ati ibukun bi won ba “...je gbo ohun Olorun ki

won si pa ofin Re mo”Deut. 28:1-2.

AWON IBEERE

1. Bawo ni o se soro fun awon omo Israeli lati pa ofin Olorun mo leyin gbogbo ikilo Re? Jiroro

lori eyi.

2. Kin ni o se soro fun awon orile ede loni lati gboran si awon ase Olorun? Jiroro lori eyi.

3. Kin ni o se okunfa asa awon ijoba Babiloni nipa awon ilu ti won ko ni igbekun? Jiroro lori

eyi.

ORO IPARI

“Bi awon eniyan mi ti a n pe oruko mi mo, ba re ara won sile, ti won ba si gbadura, ti won ba si

wa oju mi, ti won ba si yipada kuro ninu ona buburu won, nigba naa ni emi o gbo lati orun wa,

emi o si dari ese won ji, emi o si wo ile won san” (II Kro. 7:14).

Page 20: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE OGUN - OJO KEEDOGUN OSU KEFA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Laelae

KOKO ORO: ILERI OLORUN LATI YI ISRAELI PADA

IBI-KIKA: Esekieli 11:17-20, Mika 4:6-5:5

ALAYE ISAAJU

Bibeli fi idi re mule pe awon omo Israeli je awon eniyan ti Olorun yan ti o si mu jade lati ile

Egipti pelu owo agbara Re. Ohun ti Olorun n fe ni pe ki won pa awon ofin Oun mo Eksodu

20:1-17. Sugbon awon omo Israeli maa n se aigboran si Olorun nipa “orun lile” won, ati titele

ise tabi ihuwasi awon orile-ede ti o yi won ka. Eleyi mu idajo Olorun wa sori won nitori isote

Israeli ati ese Juda ninu eyi ti iborisa, etan, ininilara, idajo aisododo ati ipaniyan mu idajo Olorun

wa si ori won. Nitori idi eyi a ko opolopo won pelu awon oba ati awon olori esin lo si igbekun.

Bi o tile je pe a ri opolopo eri iwa buburu wonyi, Olorun si tun se ileri pe Oun yoo yi won pada

nitori ife Re. Idaniloju iyipada naa ni awon wonyi:

i. Lati je ibi mimo fun won ni igbekun Esekieli 11:16, bi o tile je wi pe awon ti o wa ni ile ro

pe Olorun ti ko awon ti o wa ni igbekun sile nitori tempili ti o wa ni Jerusalemu.

ii. Lati ko won jo lati ile ti a ti tu won ka si, Yoo si mu won pada si ile won Esekieli 11:17.

iii. Lati je ki won ni okan kan, Oun yoo si fi emi titun si inu won ti yoo yori si iyipada ti emi ati

ti ara.

iv. Lati rin niwaju Re gege bi ofin Re pelu idaniloju pe won o je eniyan Re, Oun yoo si je

Olorun won Esekieli 11:20.

Iyipada yii tun te siwaju ni Mika 5:2 pelu ileri Olorun pe won yoo ni olori titun ti yoo ropo awon

oba ati awon asiwaju won. Olori yii yoo je alaafia won ti yoo ran won lowo lati gba won nigba ti

awon ota ba n gbogun ti won. Eni ti a n soro Re yii kii se elomiiran, bikose Jesu Kristi. Ileri yii

kan naa ni o wa fun gbogbo onigbagbo ti a ti gbala nipa eje Jesu Efesu 2:5-8. Lai ka ese wa si,

Olorun, ninu ife nla Re fun wa ni ireti iyipada nipa igbagbo ninu omo Re.

AWON IBEERE

1. Kin ni idi ti Olorun fi fi aaye gba kiko awon omo Israeli ti won je ayanfe Re ni igbekun?

Esekieli 11:12, Mika 3:4

2. N je a ri ijora laarin ihuwasi awon omo Israeli ati awon onigbagbo ode oni? Efesu 4:17-25.

Jiroro lori eyi.

3. Ileri Oluwa ni Esekieli 11:16“lati je ibi mimo kekere”. Bawo ni eyi se ye o si gege bi

onigbagbo?

4. Olorun ninu ife ati aanu Re ti ko lopin fun wa ni ireti iyipada. Jiroro lori eyi.

ORO IPARI

Nipa ife Kristi ni a ko fi pa wa run, nitori a je omo Re. Oro Olorun duro, gba a gbo ki o si yera

fun ibi IAA 17:27-28.

Page 21: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KOKANLELOGUN - OJO KEJILELOGUN OSU KEFA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: IPINNU OLORUN FUN IGBALA

IBI-KIKA: Jeremiah 29:11-14, Ifihan 5:1-9

ALAYE ISAAJU

Ipinnu Olorun fun eniyan ni lati wa titi eyi ti i se majemu ogba Edeni Genesisi 3:22. Majemu yii

ni opin de si nipa aigboran Adamu ati Efa nigba ti won je eso igi imo rere ati buburu eyi ti o fa

iku won nipa ti ara ati ti emi.

Olorun ninu aanu Re ko fe ki eniyan parun patapata. Ohun ti o tun fe ni pe ki a wa laaye, ki a ni

aasiki, O si tun se ileri pe Oun yoo da wa lohun nigba ti a ba pe E ti a wa oju Re pelu gbogbo

okan wa ki a baa le ni iyipada atorunwa Jeremiah 29:11-14. Nipa bayii O ran ayanfe Omo Re

lati ku fun ese wa lati gba wa lowo itiju ki a le ba A joba ni Paradise ki a si le ni iye ainipekun

eyi tii se ipinnu Re lati atetekose Matteu 1:21, Johannu 3:16, Ko fe ki enikeni ki o segbe

bikosepe ki won wa si ironupiwada 2 Peteru 3:9.

Ninu iwe Ifihan 5:1-9, a rii pe ko si eni ti o ye lati gbo ipe lati gba araye la. Enikansoso ti o ye ni

odo aguntan ti i se Jesu Kristi ti I se olurapada wa lati orun wa. Oun nikan ni o le si edidi naa.

Eyi ni o fa orin titun ti o wa ni Ifihan 5:9.

Iwo ni o ye lati gba iwe naa ati lati si edidi re nitori ti a ti pa o, iwo si ti fi eje Re se irapada

eniyan si Olorun lati inu eya gbogbo ati ede gbogbo, ati inu eniyan gbogbo ati orile-ede gbogbo

wa.

Lati odo Jesu Kristi nikan ni igbala ti wa, enikeni ti ko ba gba A ko le ri igbala tabi irapada.

AWON IBEERE

1. N je enikeni le mo odiwon ife Olorun fun eniyan lori igbala? Efesu 2:8-10, Johannu 3:16.

Jiroro.

2. Ki ni idi re ti eniyan tun fi n pafo ninu ese pelu gbogbo ife Olorun lati gba wa la? Jiroro.

ORO IPARI

Ipinnu Olorun fun igbala ti di mimuse nipase Jesu Kristi omo Re.

Page 22: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJILELOGUN - OJO KOKANDINLOGBON OSU KEFA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: ONA IBARAENISORO OTUN NIPASE JESU

IBI-KIKA: Heberu 1:1-8

ALAYE ISAAJU

Ibaraenisoro tumo si gbigbe oro kaale tabi mimu oro ki o ni ipa, fun apeere, oro siso, kikosile

tabi lilo ona miiran lati ba eniyan soro.

Ti a ba wo itan igbesi aye awon omo Israeli, a o ri bi Olorun se n ba awon eniyan Re soro

lojukooju, fun apeere:

i. Kaini - Gen. 4:6

ii. Noa - Gen. 6:13

iii. Abram - Gen. 8-15, 12:1-3

iv. Mose - Eksodu 3:4-7

v. Joshua - Joshua 1:8

Olorun tun soro, lati enu awon onidajo ati awon woli Re, fun apeere:

i. Debora - Onidajo 4:4-6

ii. Gideon - Onidajo 6:11-14

iii. Samueli - I Sam. 3:10-11

iv. Isaiah - Isaiah 6:8-11

v. Jeremiah - Jeremiah 1:4-8

awon wonyi si fi oro na to awon eniyan Olorun leti.

Ni asiko yi, Olorun nipa Emi Mimo n ba wa soro l’orisirisi ona, fun apeere:

a. nipa ala ati iran

b. nipa iwaasu

c. nipa kika Bibeli

d. nipa riru ebo orin kiko

Nipa bi Emi Mimo se n ba wa soro nisinsinyi, a n di eni iyipada ninu ero inu wa, awa si n mo idi

ife Olorun, ti o dara, ti o se itewogba, ti o si pe Romu 12:2.

AWON IBEERE

1. Se apeere awon ona ibaraenisoro pelu Olorun ninu:

a. Majemu laelae

b.Majemu titun

c. Asiko ti a wa yi

2. Bawo ni Isaiah 30:19-21 se ye o si?

ORO IPARI

Olorun ti pese anfaani orisirisi fun wa lati gbo ohun Re, a si ni lati lo awon anfaani ibaraenisoro

wonyi fun iyipada okan wa.

Page 23: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETALELOGUN - OJO KEFA OSU KEJE ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: MAJEMU TITUN: FIFI IFE, OORE-OFE ATI AANU HAN

IBI-KIKA: Luku 1:68-79

ALAYE ISAAJU

Ibi kika wa je orin iyin ti Sakariah ko ti o je abayori iyipada re nipa oore ofe ati aanu Olorun. Eyi

fi ireti ati ifoya enikookan ti o n jijakadi pelu iyemeji ati ailoye han, bi o ti wa lode oni. Sibesibe,

a ro wa lati gbekele Olorun patapata nitori O feran wa, ko si si ohunkohun ti o gbodo ya wa kuro

ninu ife Olorun Romu 8: 35.

Ife Olorun, aanu ati oore ofe Re tobi, o si lagbara ju gbogbo idojuko ti a le ni bi Kristeni. Bi

Olorun ba wa fun wa, taa ni yoo koju ija si wa: Nigba ti Olorun ba fi ife Re han si awon ayanfe

Re, A si ilekun ti enikeni ko le ti, A si la ona nibi ti ona ko si. Eyi je majemu Re fun wa. Ife

Olorun alailegbe ati ailopin, ti agbara owo Re tan titi de imuse ohun gbogbo nipa riran Omo Re

lati gba wa la kuro lowo awon ota wa ki a ba le sin In laisi iberu.

Nigba ti a ba si ti yipada, ti a si n gbadun awon Ibukun ti o po lati odo Olorun , o ye ki a na owo

idariji, ife, oore ati aanu si awon aladugbo wa bi ilana ti Kristi se fun wa. Kolose 3:12-16

Mimo a ti fife Jesu fun wa ni anfaani ati ase lati bori ifarahan ibi.

AWON IBEERE

1. Se alaye ife Olorun, aanu ati oore ofe ti o wa ninu igbesi aye onigbagbo Kolose 3:10-17

2. Kin ni majemu titun? Jiroro lori Johannu 13:34-35

3. Kin ni yoo je iriri wa nigba ti a ba rin ninu majemu yii?

ORO IPARI

Olorun mu ileri Re se bi o se fi aanu han fun wa nipa idande kuro ninu egun ati ajaga ese.

Page 24: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERINLELOGUN - OJO KETALA OSU KEJE ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: IKOLA NINU MAJEMU TITUN: BAPTISIMU

IBI-KIKA: Matt. 3:13-17, Matt. 28:16-20

ALAYE ISAAJU

Israeli ti wa ni aaye pataki ni okan Olorun. O yan orile-ede yii lati toka ona si ara Re ati lati fi ife

Re han si awon orile-ede ti o ti ara Abrahamu jade Deut. 14:2, Gen. 1:3, 17:1-12. Ikola je ami

afojuri majemu laarin Olorun ati orile-ede Israeli, eyi ti o ni ibukun fun gbogbo eniyan ninu

Majemu Titun nipase iku ati ajinde Jesu Kristi.

Ni akoko idakeroro (larin iwe Malaki ati Matteu) a ni lati se eto iwenumo fun awon eniyan ti ko

kola nitori ibasepo won pelu awon orile ede miiran ni akoko ikolo si igbekun. Eyi ni Baptismu

ironupiwada ti Johannu so nipa re. Jesu paapaa yonda ara Re lati pa ofin yii mo.

Majemu Titun ni ibasepo laarin Olorun ati eniyan nipase Jesu Kristi. Eyi wa fun gbogbo eniyan

ti o ba jewo igbagbo won ninu Jesu Kristi gege bi Oluwa ati Olugbala.

Baptismu ni siso eniyan di ara ijo Kristi nipa lilo omi gege bi ami tabi apeere, a le see nipa

wiwon omi sori, tabi nipa itebo omi Matt. 28:19. Baptismu ni o so onigbagbo di alajopin iku ati

ajinde Kristi Romu 6:3. Pataki baptismu ni lati se afihan ijeri ifarajin wa si Kristi IAA 8:36-39.

Gege bi ikola se je ami ninu Majemu Laelae, Baptismu je ilana emi ti a le gba lati di ara Kristi

ninu Majemu Titun. Ikola ninu Majemu Titun je ti okan ti yoo mu iyipada wa fun onigbagbo

Romu 2:29.

IBEERE

1. Kin ni idi ti eniyan se ni lati se Baptismu? Matt. 28:19-20, IAA 18:24-26, I Kor. 12:13.

2. Kin ni iyato laarin ikola ati Baptismu? Kol. 2:11-12.

3. Kin ni idi ti a fi n baptisi awon omo owo? IAA 16:15, IAA 16:30-33, Kol. 2:12.

4. Kin ni idi ti a fi gbe ohun elo baptismu si apa otun iwole ile ijosin?

ORO IPARI

Majemu Titun wa nipa iku ati ajinde Jesu Kristi. Nitori naa, e lo, e ma ko orile-ede gbogbo, ki e

si baptisi won ni oruko Baba ati ni ti omo, ati ni ti Emi Mimo Matt. 28:19.

Page 25: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KARUNDINLOGBON - OGUNJO OSU KEJE ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: IKOLA NINU MAJEMU TITUN: IGBOWOLELORI BISOPU

IBI-KIKA: Ise Awon Aposteli 18:24-28; 19:1-6

ALAYE ISAAJU

Ikola ninu Majemu Laelae je ami ti ode ti o fi han wipe eniyan ti gba lati je ti Olorun. O si je eya-

ara ipilese esin awon Ju.

Ikola ti Majemu Laelae yii fa ariyanjiyan laarin awon onigbagbo igbaani (IAA 15:1-2; Romu

2:25-29). Ikola ti okan (gege bii Majemu Titun ti gbaa) ni ironupiwada ati gbigba ebun Emi

Mimo. Awon ami ifarahan awon wonyi ni Baptismu ati Igbowolelori awon Aposteli.

Ikola yi je eto nipa eyiti a fi nfi ifaraji ti o peye fun Kristi han ati lati gba Emi Mimo nipa adura

ati Igbowolelori Bisopu. Eto yi je atowodowo ninu ijo awon eniyan Olorun, apeere eyi ti o je

Igbowolelori awon Aposteli nipa eyiti a fi ngba agbara ati ibukun Olorun. O je akoko ti awon ti o

fe gba Igbowolelori yoo fi idi ileri ti a se nitori won ni igba Baptismu won mule, ti won yoo si ya

ara won soto fun Olorun. Laarin awon ijo akoko, Igbowolelori Bisopu je fifi ese eniyan mule

ninu ijo.

O ye ki a mo pe Igbowolelori Bisopu ki i se eto lasan bikose iyipada okan. Iyipada ihuwasi wa

ni ife Olorun, a si gbodo gbe igbe aye ti o fi iyipada aye wa yii han. Ise wa ni lati lo fi igbe aye

wa titun yii yi awujo wa pada si rere.

AWON IBEERE

1. Kin ni awon ohun ti a n bere lowo awon ti o fe gba Igbowolelori Bisopu?

E jiroro.

2. Ipa wo ni Igbowolelori Bisopu ko lori

(a) Eni ti o gba Igbowolelori?

(b) Ijo Olorun ati awujo?

3. N je awujo wa n je anfaani awon Kristeni ti won ti gba Igbowolelori Bisopu?

E jiroro

ORO IPARI

Ikola ti Igbowolelori Bisopu je igbese pataki ninu irin ajo wa gegebi Kristeni. A gbodo mu un ni

okunkundun pelu ero ati gba iyipada otun nipase re.

Page 26: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERINDINLOGBON - OJO KETADINLOGBON OSU KEJE ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: IKOLA NINU MAJEMU TITUN: OUNJE ALE OLUWA

IBI-KIKA: Matteu 26:26-30, 1 Kor. 11:23-32

ALAYE ISAAJU

Ounje ale Oluwa je Sakramenti ti a fi lele nipa ase Jesu Kristi lati ma a se iranti igbe aye, iku,

ajinde ati igoke re orun Re titi di igba ti Oun yo o fi pada wa. O se dandan pe ki a gba a ni ona

tito, yiye pelu okan igbagbo, ki a ma baa wa si idalebi (1 Kor. 11:29). A fi lele ni ojo ase Irekoja

o si ni ami pelu ase Irekoja ti Majemu Laelae (Eks. 12:14, 43-51). Ohun meji pataki ni o wa ninu

ounje ale Oluwa, eyi ti ise akara ati oti waini. Akara ti a bu, ara Kristi ni i se ati ago ibukun ti a

mu eje Kristi ni i se. Lehin igbowolelori Bisopu, nigbakuugba ti a ba fe gba ara Oluwa, a ni lati

se ipalemo ti emi; eto eni ti o ba si gba akara ni lati gba waini pelu. A ko gbodo se awon ohun elo

na ku tabi ki a bo won.

Ounje ale Oluwa je (i) edidi ara ati eje Jesu ti Majemu Titun, (ii) ami wi pe “gbogbo wa ni lati

mu sinu isokan Emi”1 Kor. 12:13, (iii) eri ife ti o sowon ti eni ti O fi ara Re fun wa, ti O si fe wa

sibe titi laelae. Ami oore ofe ati ife inu rere Olorun si wa, ti n sise ti a ko fi oju ri, agbara, eyi ti o

n fi igbagbo wa mule ninu Re.

AWON IBEERE

1. Ka, ki o si jiroro lori eko ijo ekejidinlogbon.

2. Loju tire, n je ese alufa le je ki ounje ale Oluwa di alailola? (Eko ijo merindinlogbon)

3. Toka si awon anfaani ti o wa nigba ti a ba gba, ounje ale Oluwa.

4. Kin ni idi ti a se n se isin ounje ale Oluwa lojoojumo? (Ise 2:42-46. 1 Kor. 11:26).

ORO IPARI

Ki awa ti a pin ninu ara Kristi gbe aye ajinde Re, awa ti a si mu ago Re mu iye ba awon

elomiiran, ati awa ti imole Emi Mimo Re tan si, tan imole si aye yi Amin.

Page 27: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETADINLOGBON - OJO KETA OSU KEJO ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: JESU KRISTI GEGE BI ALUFA

IBI-KIKA: Heberu 4:14-5:9

ALAYE ISAAJU

Alufa ni olori awon olufokansin ti a fun ni ase lati maa se ilana isin. Oun ni onilaja laarin eniyan

ati Olorun. Oye alufa ni ilana ti Aaroni ni eniti Olorun pe lati je onilaja nipa mimu ore ati irubo

wa fun etutu.

Jesu Kristi ni Olori Alufa nla ti o ti wa ki a to da aye. O wa lati eya Judah eyi ti Mose ko so

ohunkohun nipa oye alufa nitori idile Lefi nikan ni Olorun pa lase lati ma je oye alufa.

Oye alufa Jesu Kristi ga ju ti awon alufa aye, a si fi we ti Melkisedeki oba Salemu “nitori a ko ni

olori alufa ti ko le sai ba ni kedun ninu ailera wa, eniti a ti danwo li ona gbogbo gege bi awa,

sugbon lailese”Heb. 4:15. Yato si awon Alufa Majemu Laelae ti won ni lati maa fi eran osin

rubo nigba gbogbo fun imukuro ese ara won ati ese Israeli, Olori Alufa nla ni, jowo ara Re

leekansoso fun ebo arukun ati aruda.

Oye alufa Jesu Kristi wa titi aye, ko le yi pada, eyi ti a se nipa ibura titi aye Heb. 7:21-24. Niwon

bi awon alufa yooku ninu Bibeli ti dagba ti won si ku, alufa nla wa, oniyonu wa titi aye. O si

joko lowo otun Olorun, o si n bebe fun wa Heb. 4:14-16, 5:6, Romans 8:34.

Nipa ti oye Alufa Re ti ko lopin, ki ise wi pe Kristi le yi aye wa pada nikan sugbon O tun le gba

gbogbo awon ti o to Olorun wa nipa Re la.

AWON IBEERE

1. Se afiwe oye Alufa ni ilara ti Lefi ninu majemu laelae, pelu oye Alufa ti Jesu Kristi (Eksodu

28:1, Heb. 5:1-3).

2. Jiroro lori awon ohun ti Kristi se fun araye gege bi olori Alufa. Heb. 4:16, Heb. 6:19-16

ORO IPARI

“Bi a si ti so o di pipe, o wa di orisun igbala ainipekun fun gbogbo awon ti o n gbo tire”Heb.

5:9.

Page 28: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJIDINLOGBON - OJO KEWA OSU KEJO ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: AWON ONIGBAGBO GEGE BII ALUFA

IBI-KIKA: Eks. 19 : 4 - 6; Lef. 8 : 1 - 36; 1 Pet. 2 : 6 - 14

ALAYE ISAAJU

Ninu Eksodu 19:4-6, Israeli je orile ede ti Olorun yan ti O gbala lati ya s’oto fun ara Re. Laarin

Israeli, awon omo Lefi ni O yan gege bi alufa. Ise-alufa yii je bi aworan ise iranse ti Jesu Kristi

ti n bo ti ko si wulo mo ni kete ti ebo Re lori igi agbelebu ti pari.

Peteru soro nipa ise alufa onigbagbo pe anfaani ni ise naa je. Gbogbo onigbagbo ni Olorun yan

gege bii: “iran ti Olorun yan.... awon eniyan oto, olu-alufa... ki a le fi olanla eni ti o pe yin jade

kuro ninu okunkun sinu imole iyanu Re”(I Pet. 2:9). Ara onigbagbo ni tempili Emi Mimo (I Kor.

6:19-20), nitori naa Olorun ti pe wa lati sin Oun tokantokan pelu irubo ara wa li ebo aaye (Romu

12:1-2).

Olorun n toka pe awon ise-alufa ti Majemu Laelae ko wulo mo nitori won ko pe. Nisinsinyi

awon onigbagbo le wa taara si iwaju Olorun nipase Alufa nla wa, Jesu Kristi (Heb. 4:14-16).

AWON IBEERE

1. Bawo ni ise-alufa ti onigbagbo se ye o si?

2. Kin ni awon nnkan ti a n reti ninu ise-alufa onigbagbo?

3. Kin ni anfaani ti o wa ninu jije ara awon olu-alufa?

ORO IPARI

Gege bi onigbagbo o ye ki a fi idanimo wa han gege bi “Alufa mimo” nigbakugba ti a ba n

gbadura tabi ti a n josin. A ko gbodo fi adura ati ijosin sile fun awon “akosemose” nikan; o je

ojuse ati anfaani gbogbo onigbagbo.

Page 29: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KOKANDINLOGBON - OJO KETADINLOGUN OSU KEJO ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Iyipada Otun - Majemu Titun

KOKO ORO: ENIYAN TI EMI

IBI-KIKA: Galatia 5:16-6:8

ALAYE ISAAJU

Ipa meji ni o n sise ninu eniyan; Emi Mimo ati emi ti eran ara. Iwa buburu, bi aibikita fun Olorun

ati elomiiran, ni a ri ninu iwe Galatia 5:19-22; 2 Kor. 12:20; Efesu 5:5 nigbati iwa rere, eyi ti

ise eso Emi wa ni Galatia 5:22-23.

Ero okan eniyan je buburu, ti n fa iparun, imo ti ara eni nikan, iponju, ojukokoro, idibaje, ese, ti o

si le se iku pa ni. Igbe aye rere a maa so eso emi, a maa fi ara jin, a maa fun ni ni ominira, a maa

to ni sona, a si maa fun ni ni igbe aye irorun.

Ako le sai kaa si pe eniyan ni ife buburu, ona kansoso ti a le gba ni ominira ni nipa agbara Emi

Mimo (Romu 8:9).

Nigba ti a ba di Eniyan ti Emi, a o le ran ara wa lowo, ki ise nipa ti ara nikan bikose nipa ti Emi -

Iwe Owe 27:17. Ijo Olorun a maa se deedee nigba ti awon omo ijo ba n sise ni isokan ti emi fun

anfaani ara won (Lefitiku 28:8). Esu ko fe ki eniyan gbe igbe aye ododo ti o ni iyipada, sugbon

eni ti o ba n gbe labe imisi Emi Mimo yoo je asegun nigba gbogbo.

AWON IBEERE

1. Gege bi Kristeni a maa n te si ati dese, kin ni ohun ti a le se lati ni agbara lori ese? Galatia

2:20; 6:14). Se alaye.

2. Ewu wo ni o wa ninu ki a maa se afarawe elomiiran? Saamu 73:1-2; Galatia 6:4, 5? Se

alaye.

ORO IPARI

N je ebi ko si nisinsinyi fun awon ti o wa ninu Kristi Jesu (Romu 8:1).

Page 30: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE OGBON - OJO KERILELOGUN OSU KEJO ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Awon Eniyan Inu Bibeli - Iyipada

KOKO ORO: PAULU (SAULU) APOSTELI

IBI-KIKA: Ise Awon Aposteli 22:1-16; Fil. 3:1-11

ALAYE ISAAJU

O je ohun ti o jo ni loju wi pe Paulu funraare ni o se apejuwe eniti oun je fun awon eniyan, ni

akoko tire. Loorekoore ni o nso itan ara re lati igba ti o n fi itara se inunibini si awon omo lehin

Kristi titi di igba ti o n fi itara polongo Kristi.

Ninu ibi kika wa akoko, a ri i bi a se n wo Paulu jade ninu tempili Jerusalemu lo si inu tubu.

Esun ti a fi kan an ni wi pe o n ko gbogbo eniyan ni ibi gbogbo lati lodi si ise ati ofin awon Juu

(Ise 21:28). Paulu ko ba won jiyan, nitori o ti mo isoro ti oun yoo dojuko tele (Ise 21:13-14).

Dipo eyi, o lo anfaani awon omo ogun ti o gba a sile lati ba awon agbajo na soro. O fi ara re han

fun won gege bii Juu ti o ti ko eko labe Gamalieli eniti a mo si Rabbi ti a fun ni owo gidigidi.

Paulu ti gba eko ti o ye kooro lori ise ati ofin awon Juu. Oun je Farisi ti o mo oro Olorun, ti o si

gbagbo tokantokan nigbana wi pe igbagbo Kristeni lodi patapata si ise ati ofin awon Juu. Nitori

naa ni oun se korira awon omo leyin Kristi, o si ti se inunibini si won lai laanu (Ise 8:1). Paulu

tesiwaju lati se ijeri bi oun se pada wa gba Kristi gbo. Jesu ti da a duro ni oju ona Damasku ki o

to le ni anfaani ati se ise ibi ti o n ba lo.

Iriri ona Damasku yi ni o fi opin si “eni atijo Paulu” ti o si so o di “eda titun” ninu Kristi (II

Kor. 5:17). Olorun ti yi i pada kuro ni oninunibini awon kristeni si ajihinrere Kristi. O n waasu

Kristi kaakiri, paapaa laarin awon kefeeri, o n jere okan fun Kristi, o si n da awon ijo sile. O maa

n ko iwe ranse si awon ijo ti o ti da sile lati gba won niyanju ati lati mu won lokan le. Iru iwe bee

ni Episteli Paulu si awon ara Filippi eyi ti o tenumo Ayo. Bi o tile je wi pe inu tubu ni Paulu ti n

ko pupo ninu awon episteli re, o fi ara re han bi eni ti o ni ayo ninu Olorun. O ni ayo tooto nipa

gbigbe gbogbo ero ati agbara re le ati mo Kristi, o tile so ijinle oro ni Fil. 3:8-10 nipa mimo

Kristi saaju ohun gbogbo laye. O ye ki gbogbo Kristeni ni ijeri oro ijinle yi bakan naa ninu irin

ajo igbagbo won.

AWON IBEERE

1. Awon iwa wo ni Paulu fi yangan nipa ogun ibi re?

2. Se alaye awon ti a pe ni “aja” ni igba aye Paulu ati awon ti ode oni (Fil. 3:2).

3. Nigba ti a ba n polongo Kristi, ijeri agbara Re ninu aye wa le wulo gidigidi lati ra okan pada.

Jiroro Ifihan 12:11.

ORO IPARI

Iyipada ti emi ti Paulu ni, je apeere nla fun ayeraye. Ko si eni ti o buru ju fun iyipada ti Emi

Mimo.

Page 31: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KOKANLELOGBON - OJO KOKANLELOGBON OSU KEJO ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Awon Eniyan Inu Bibeli - Iyipada

KOKO ORO: PETERU (APOSTELI )

IBI-KIKA: Johannu 13:6-9, 36-38; 21:3-17, Iaa 2:14, 38-42

ALAYE ISAAJU

Oro akoko ti Jesu so fun Simoni Peteru ni “wa, ki o maa to mi leyin” (Marku 1:17). Oro ikeyin

Re si i ni “maa to mi leyin”(Johannu 21:19). Laarin ase mejeeji ti Jesu pa fun Peteru, ko kuna

lati maa to Jesu leyin bi o tile je pe loorekoore ni o maa n kose. O dara lati je omo-eyin ti o maa

n kuna ni igba miiran ju omo-eyin ti o ko lati tele eni ti o n to leyin.

Nigba ti Jesu wo inu aye Peteru, apeja ni, n se ni o di eni otun, o si di eni ti o n se ohun otun. Bi o

tile je wi pe Jesu wo inu aye Peteru, eyi ko soo di eni pipe. Jesu ri Simoni gege bi alagbara

eniyan nitori naa O so ni Peteru - “apata”. Peteru je eni ti o maa n gbe igbese lai ronu jinle nigba

miiran, ko si fi gbogbo igba huwa gege bi “apata”. N je o se tan lati maa to Jesu leyin bi o tile

kuna? Jesu gba Peteru bi o tile je pe o ni awon aleebu, o si pada se awon ohun ribiribi fun Olorun

(IAA 2:14, 38-42, 3:1-10). Bi o tile je wi pe o je asiwaju ti ko fese mule ni asiko ise iranse Jesu,

eni ti o je ki ihale re di ohun isubu fun un, tobee ti o fi se Jesu (Johannu 18:10, 15-18, 25-27).

Jesu dari jii, O si mu pada bo sipo. Ki ise pe Jesu n wa awon eni awokose sugbon o yan awon

omo-eyin ti o lee so di otun nipa eko ati ajosepo pelu won fun ise iranse Re. Ni ojo Pentekosti,

Peteru ti o ti di eni otun, onirele, sugbon ti o gba igboya lati owo Emi Mimo di eni ti o n waasu

Ihinrere Kristi. Nipase re, bii egberun meta eniyan di onigbagbo nigba ti o waasu ihinrere Jesu

Kristi fun won.

O le ya wa lenu pe kin ni Jesu ri ninu wa ti o fi ni ki a maa to Oun leyin. Ni opo igba ni a maa n

ro pe a ko je eni pipe tabi pe a ti se awon asise to bee ge ti Olorun ko le dariji wa, ki O si lo wa

fun ise ijoba Re. Ko si iru ese ti o ti se, Olorun se ileri idariji, je ki O dariji o, ki o si sise fun un.

N je o se tan?

AWON IBEERE

1. Jiroro lori awon aleebu Peteru ati bi a se yii pada.

2. N je o ni apeere awon eniyan ti Olorun ti lo fun ise ribiribi bi o tile je pe won je alaiye.

ORO IPARI

“Ati awon ohun aye ti ko niyin, ati awon ti a n kegan, ni Olorun si ti yan, ani, awon ohun ti ko si

lati so awon ti o wa di asan. Ki o mase si eleran-ara ti yoo sogo niwaju Re”(I Kor. 1:28-29).

Page 32: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJILELOGBON - OJO KEJE OSU KESAN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Awon Eniyan Inu Bibeli - Iyipada

KOKO ORO: AYABA ESTERI

IBI-KIKA: Esteri 2:5-18; 3:8-4:17

ALAYE ISAAJU

Awon Juu wa ni ipo idaamu lehin igba ti a ko won kuro ni Jerusalemu lo si igbekun.

Esteri eniti abiso re nje Hadasa je omo orukan Juu ti o n gbe ni igbekun pelu Modekai arakunrin

re ni Susani. Ni asiko kan oba binu si ayaba Fasti nitori iwa afojudi re. Won si beere sii wa eni ti

yoo ropo re. Esteri je wundia ti o lewa, okan ninu awon omidan ti a ko jo si aafin lati toju, ki won

to le fi won han niwaju oba. Ninu agbala oba, o ba oju rere pade nitori o gba eko daradara, o si

mo iwon ara re. Nigba ti a fi won han oba, nitori ewa re, oba yan Esteri o si fi ade dee e lori.

Nipa igboran si arakunrin re, ko je fi eya re han. Bi Esteri si ti n gbile ni aafin, ikorira Hamani

fun awon Juu n pele sii, o si fi ipa je ki oba se ofin ti abayo re yoo jasi iparun awon Juu.

Nigba ti Modekai gbo, o fi iwe ofin naa ranse si Esteri lati ran an leti pe wiwa nibe je eeto

Olorun, o si ye ki o gbe igbese lati da aabo bo awon Juu. Ti o ba si ko lati se eyi, iranlowo yoo

jade ni ona miiran. Bi o tile je pe, o koko lora, o pinnu o si gba lati yoju si oba bi o tile je wi pe a

ko pee. O so pe “bi mo ba segbe, mo segbe”Est. 4:16b. Ohun ti o beere lowo arakunrin re ati

awon Juu, ni pe ki won para po pelu oun lati gba aawe fun ojo meta. Nipa igbagbo ati igboya, o

gba awon Ju la. Olorun si mu iyipada ba Esteri, Omo orukan ati onirele di aya oba, o si di ohun

elo ti a yan lati gba awon eniyan re la lowo iparun.

Ki iyipada bi ti Esteri to le waye, a gba awon onigbagbo ni iyanju lati sin Olorun tokantokan lai

siyemeji, nitori a mo wi pe O wa pelu wa O si mo ohun gbogbo nipa wa.

AWON IBEERE

1. Ni ibamu pelu ileri Olorun si awon Juu wi pe, Oun yoo maa je Olorun won, awon a si maa je

eniyan Re Ese. 11:22b. Se alaye bi eleyi se farahan ninu itan Esteri.

2. “Bi mo ba segbe, mo segbe”, bawo ni eyi se wa ni ibamu ninu ere ije awa Kristeni lode oni.

Jiroro. Esteri 4:16b.

ORO IPARI

Ninu gbogbo ona re, fi Olorun siwaju Yoo si gbe o ro.

Page 33: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETALELOGBON - OJO KERINLA OSU KESAN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Awon Eniyan Inu Bibeli - Iyipada

KOKO ORO: OMO ONINAKUNA

IBI-KIKA: Luku 15:11-24

ALAYE ISAAJU

Itumo inakuna ni iwa aibikita ni lilo ohun ini wa. Owe omo oninakuna je itan ti ko sajeji si wa

nipa baba kan ati awon omokunrin re mejeeji.

Eyi aburo beere ipin ogun tire lowo baba re. Baba yii se ohun ti omo re fe sugbon omokunrin yii

lo si ilu okeere nibi ti o ti na gbogbo ohun ini re ni inakuna pelu igbe aye aibikita ati

ifinnkansofo. Nigba ti gbogbo nnkan ti dojuru fun un o lo gba ise ni ogba elede, iwa ti o lodi si

ofin atowodowo awon Juu. Ipo ti o ba ara re buru jai ti o fi je pe idunnu ni iba je fun un lati pin

ounje je pelu awon elede. Nigba ti o ya, opolo re ji o si pinnu lati pada lo si ile lati lo ba baba re

Luku 15:18-20. O dide pelu igboya o si to baba re lo lati toro idariji ese re. Baba re ri i ni okeere

aanu re see o si lo lati pade re pelu ife. O pase ajoyo ase nla fun omo ti o ti sonu pelu egboro

maalu abopa, o fun un ni aayo aso, oruka fun owo re ati fun ese re. Okookan awon nnkan wonyi

je ami ipo ati itewogba.

Owe yii je ipe si ironupiwada ati pipada si odo Olorun. A ti sonu sugbon Kristi wa wa ri, Olorun

baba wa ko fe ki enikeni sonu ati pe inu Re maa n dun gan-an nigba ti a ba ronupiwada.

Ayo pupo ni o wa lorun nigba ti elese kan ba ronupiwada Luku 15:24. Ironupiwada wa a maa

silekun iyipada fun wa nipase Emi Mimo.

AWON IBEERE

1. N je a le dariji awon omo wa gege bi baba yii ti se? Jiroro.

2. Kin ni awon abajade idariji tabi aidariji? Matteu 6:14 & 15.

3. Jiroro lori idariji nigba ti a ba wo o ni ona Onesimu ati oga re. Filemoni 10 & 11.

ORO IPARI

Ironupiwada atokanwa n fa ayo ni orun ati ni aye.

Page 34: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERINLELOGBON - OJO KOKANLELOGUN OSU KESAN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Afiwe Majemu Laelae Ati Titun

KOKO ORO: EJE ABELI ATI EJE JESU

IBI-KIKA: Gen. 4:9-12, Heb. 12:18-24

ALAYE ISAAJU

Eko wa ti oni n so nipa itajesile eniyan. Eje Abeli ni a ta sile lati owo Kaini. Awon mejeeji je

omo Adamu ati Efa. Won se irubo si Olorun, sugbon Olorun tewogba ebo Abeli. Eleyi ko dun

mo Kaini ninu, o si pa arakunrin re Abeli. Eje Abeli ni a ta sile nitori ibinu ati owu, a ko taa sile

fun ohun rere kan. Ipaniyan je ohun ti o buru jai. Itajesile yii bi Olorun ninu Gen. 4:10. Eje Abeli

si ke tantan fun esan lati inu ile wa.

Ni idakeji ewe, Jesu jowo ara re fun wa lati ta eje Re sile lori igi agbelebu ni Kalfari. A ta eje Re

sile gege bi ebo ti o je itewogba fun ese wa. O ni agbara lati mu wa gbe igbe aye aseyori, irapada,

idapo, iwosan, aabo ati ase lori Satani Isa. 53:4, I Kor. 5:21; Efesu 1;7, Heb. 10:19. Eje Jesu a

maa mu iyipada wa si aye awon elese. O je ki won le wa siwaju Olorun pelu igboya Heb. 10:19.

Itasile eje Jesu je ohun mimo ti o je itewogba lodo Olorun fun idariji ese. Eje Jesu nikan ni o le

gba wa la, ti o si le yi wa pada. Ti a ba ko iwaasu nipa eje Jesu a ko lee ri igbala IAA 4:12.

AWON IBEERE

1. Eje Jesu n so ohun kan ti o dara ju eje Abeli lo. Jiroro

2. Bawo ni agbara iwenumo eje Jesu se ye o si?

ORO IPARI

Eje Jesu n so ife, o si n se iwenumo fun ese. O n so ohun didara ju eje Abeli lo Heb. 12:24b.

Page 35: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KARUNLELOGBON - OJO KEJIDINLOGBON OSU KESAN ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Afiwe Majemu Laelae Ati Titun

KOKO ORO: AJO IREKOJA ATI OUNJE ALE OLUWA

IBI-KIKA: Eksodu 12:1-14, Matt. 26:17-29

ALAYE ISAAJU

Ni igba ijadelo awon omo Israeli kuro ninu oko eru ni ile Egipti, Olorun pase ki won se ase ajo

Irekoja gege bi ami itusile. Won ni lati se eyi ni ojo kewaa osu kinni iwe ikaye osu awon Juu.

Idile kookan ni lati mu odo aguntan kan tabi ki awon idile pin odo aguntan kan laarin ara won,

gege bi won se po to ninu ebi. Odo aguntan naa ni lati je ako alailabawon ti ko ju odun kan lo.

Won o si pa odo aguntan naa ni ojo kerinla, osu naa, ki won si fi eje re won aterigba, ati awon

opo ilekun ile, ki angeli apanirun le re won koja. Eyi ko ni je ki won kopa ninu ijiya awon omo

Egipti. Eyi ni awon ayanfe Olorun (awon omo Israeli) yoo maa se lodoodun fun iranti Eksodu

12:14, I Korinti 11:26.

Bakan naa, Jesu, ni pipa ase Olorun mo ati fifi ara Re jin fun ofin, mu ase ajo Irekoja yii se ni

ona ti o ga julo. Oun tikaraare ni odoaguntan ti a pa, eyi fi irubo ti o tayo han. A ni lati maa se

iranti ifi ara Re rubo yi lodoodun.

Awon ase mejeeji yii (ajo Irekoja ati ounje ale Oluwa) yii-

(i) ni Olorun pa lase ki a maa se ni iranti

(ii) da lori fifi eje rubo, nitori lai si itaje sile, ko le si imukuro ese, itaje sile ni etutu naa.

(iii) je ijade kuro ninu oko eru ti ara ati ti emi

(iv) mu wa wa si iyipada otun

Awon ase mejeeji yi je ki o di mimo fun wa bi Olorun se ba awon ayanfe re ni Majemu Laelae

ati ni Majemu Titun lo gege bi imo ati ipo emi ti won wa. Irubo ti Jesu fi ara Re se ti a n se iranti

Re ninu Ounje ale Oluwa fi ona pipe si iyipada han.

AWON IBEERE

1. Ase ajo irekoja je ojiji irubo pipe ti Oluwa wa Jesu Kristi fi ara re se? Jiroro Heb. 10:4-24

2. “Lai si itaje sile ko le si ifiji ese” Bawo ni eyi se ye o si? Jiroro. Heb. 9:22-27.

3. Jesu wa lati fun wa ni agbara lati pa ofin mo. Jiroro. Matt. 5:17-20, Heb. 10:17.

ORO IPARI

Nitori irubo ti a fi eje eran osin ninu majemu laelae se ko pe, Jesu ninu majemu titun, fi ara Re

lele fun itusile ati irubo pipe nitori naa ko nilo irubo miiran mo.

Page 36: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERINDINLOGOJI - OJO KARUN-UN OSU KEWAA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Afiwe Majemu Laelae Ati Titun

KOKO ORO: ETUTU FUN ESE

IBI-KIKA: Lef. 5:1-13; 17:11; Rom. 3:21-26, Heb. 2:14-18

ALAYE ISAAJU

Etutu ja si bi a se le mu alaafia pada si aarin awon ti won n ba ara won ja (fun apeere Olorun ati

eniyan).

Ninu majemu laelae awon Alufa omo Lefi ni won maa n se etutu nipa pipa eran ti ko ni abawon,

won a si fi eje re won ara pepe. Nipa sise eyi, won ti se atunse fun ibasepo ti o ti baje laarin

Olorun ati eni naa ti o ti dese (Lefitiku 5:1-10). Eje eran ti a pa yi ni yoo je etutu fun ese elese

naa (Lefitiku 17:11).

A ya ojo pataki kan soto gege bi ojo isetutu fun ese gbogbo awon omo Israeli. Ni ojo yii ti o je

eekan soso lodun, Olori Alufa yoo wo ibi mimo julo pelu eje ewure lati lo se etutu fun ese

gbogbo awon eniyan naa (Lefitiku 16:29-30).

Ninu majemu titun, Jesu Kristi yooda ara Re gegebi odo agutan fun irubo lati fi se etutu fun ese

gbogbo awon ti o gba A gbo. Oun kan naa ni Olori Alufa ati odo Aguntan fun etutu ese wa. Jesu,

odo aguntan tooto ti Olorun ku lori Agbelebu, O si ta eje Re sile lati je etutu fun ese wa. Ni ojo

naa gan ni majemu titun bere ninu aye onigbagbo. Fifi eran osin rubo ni a fopin si nitori pe a ti ta

eje ti ko labawon sile fun ese wa. Eyi je irubo ti a se leekansoso fun ese wa. Nitori naa, a ko nilo

a seese tun se etutu mo. Kristi Olori Alufa wa ti O ga julo ni O le gba wa la titi aye nitori ti O wa

laaye, O n se alagbawi fun wa, O si n fun wa ni idaniloju igbala wa (Heberu 7:16, 27; 9:13-14,

24-26).

AWON IBEERE

1. So, ki o si se alaye awon iyato gidi ti o wa laarin etutu fun ese ninu Majemu laelae ati

Majemu titun.

2a. Kin ni idi ti o fi se pataki lati yi ona ti a fi n se etutu fun ese pada? Heb. 7:11-12, 16, 24-27.

b. Iru ipa wo ni iyipada yi ko ninu etutu fun ese ti awa ti gba.

3. Kin ni awon anfaani ti o wa ninu gbigba etutu ti Majemu Titun? II Kor. 5:17-19; Romu

5:10-21.

ORO IPARI

“Fifi eran osin rubo yi a maa se iranti ese ni odoodun nitori ko seese fun eje ako malu ati ti

ewure lati mu ese kuro”(Heberu 10:3-4).

Page 37: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETADINLOGOJI - OJO KEJILA OSU KEWAA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Afiwe Majemu Laelae Ati Titun

KOKO ORO: ISE ATI OORE-OFE

IBI-KIKA: Romu 4:1-5, Efesu 2:1-9

ALAYE ISAAJU

Awon esin kan gbagbo pe a gba won la nipa ise nigba ti eko Kristeni ko wa pe a gba wa la nipa

oore-ofe.

Ise n toka si akitiyan awon eniyan lati se aseyori fun idi kan tabi omiiran. Lati so wi pe a gba

eniyan la nipa ise tumo si pe ti o ba gbe igbe aye mimo ti o dara, iwo yoo lo si orun ti o ba ku.

Eyi ni pe igbiyanju lati se ise to dara ki ise eto lati lo si orun rere.

Oore-ofe ni ojurere ti ko to, ti a n fifun eni ti o gbaa. A se e lati mu iwa eniyan bo sipo ninu

majemu abasepo pelu Olorun, nipa iku Kristi.

Lati so wi pe eniyan ni igbala nipa oore-ofe tumo si pe a ni igbala nipa ife ati aanu Olorun nikan

ati etutu ebo Kristi lori igi agbelebu. Nitori naa, eyi yoo jogun iye ainipekun fun wa.

Gege bi Efesu 2:8-9 ti so, igbala kii se ere fun ise rere ki a ma baa gberaga. Ona kan soso lati ni

igbala ni igbekele ise irubo ti Kristi pari lori igi agbelebu. Ni kete ti a ba gba o la, o di eni

iyipada. O di eda titun, ohun atijo ti koja lo (2 Kor. 5:17). Itumo re ni wi pe ise rere ko le gba wa

la lona kankan sugbon ti a ba ni igbala, tinutinu ni a maa fi pa awon ofin Olorun mo lati le se

awon ise rere.

Ibasepo laarin oore-ofe ati ise ko le rara. Oore-ofe nipa igbagbo ni a fi gba wa la, ki ise nitori ise.

A ko le gba eto lati lo si orun rere nipase “sise rere”(Isa. 64:6), sugbon ise rere ye ki o je awon

ami onigbagbo tooto.

AWON IBEERE

1a. Kin ni itumo lati ni igbala nipa oore-ofe?

2. Ise rere ni ere igbala. Jiroro

3. Igbagbo laisi ise, oku ni. Jiroro

ORO IPARI

Oore-ofe sa

Ni gbeleke mi

Jesu ku fun araye

O ku fun mi pelu

Page 38: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJIDINLOGOJI - OJO KOKANDINLOGUN OSU KEWAA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Afiwe Majemu Laelae Ati Titun

KOKO ORO: ESIN ATI KETEKETE

IBI-KIKA: Eksodu 14:9, 23-31, Deut. 17:15-16, Awon Oba Kini 10:26-28, Luku

19:28-38

ALAYE ISAAJU

Awon ibi kika wa soro nipa awon eranko meji - Esin ati Ketekete. Awon mejeeji je awon ohun

irinse ti o kun oju iwon. Ketekete je eranko ti o maa n gbe eru, ti o tun gba ojuse lati ru eru awon

yooku, kii re, kii sii beru. Esin yara, o si je eranko ti o lagbara ati ami oba ti a n lo ni orisirisi

ona.

Ketekete je ami fun alaafia ati oro aje nigba ti Esin duro fun ami ogun ati agbara awon ologun.

Deuteronomi 17:16 so fun wa pe ni yiyan oba fun Israeli, Wolii ran awon eniyan leti ki won

mase yan oba ti yoo ko esin jo fun ara re. Eyi tumo si pe ki won mase yan oba ti yoo maa ko

orile ede si ogun sugbon ti o je oba ti o fe alaafia.

Igba ikeyin ti Jesu gun ketekete wo Jerusalemu duro fun irele ati alaafia, ki o ba le fi alaafia fun

aye dipo oba Ologun. Jesu wi pe, Alaafia mi ni mo fi fun yin kii se bi aye ti n fi funni...

(Johannu 14:27). Bi awa gege bi onigbagbo ba jewo Jesu ni Olugbala wa nigba gbogbo, alaafia

Olorun ti o ta imo gbogbo yo eyi ti Jesu mu wa yoo je tiwa (Filipi 4:7).

Ni ode oni, nigba gbogbo ni ijakadi maa n ,wa laarin iwa ipa ati alaafia. Gege bi o se wa pelu

awon omo Israeli, Oluwa so daju fun won ninu Eksodu 14:13-14 -“E ma beru, e duro jee, ki e si

ri igbala Oluwa, ti yoo fihan fun yin... nitori awon ara Egypti ti eyin ri ni oni, e ko ni ri won mo

laelae”. Eyi ni ileri ti majemu titun fun gbogbo awon Kristeni.

AWON IBEERE

1. Kin ni gigun ti Jesu gun ketekete wo Jerusalemu tokasi fun awon Kristeni lode oni?

2. Awon iwa wo ni onigbagbo le ko lara (i) Ketekete (ii) Esin

ORO IPARI

Awa ni Olugbala kan ti o nru gbogbo ojuse ati eru awon Kristeni tokantokan, nitori naa, ko

gbogbo aniyan yin le E, Oun ko je ja yin kule (Orin Dafidi 55:22; Matteu 11:28-29).

Page 39: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KOKANDINLOGOJI - OJO KERINDINLOGBON OSU KEWAA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Afiwe Majemu Laelae Ati Titun

KOKO ORO: OBA SAULU ATI PAULU APOSTELI

IBI-KIKA: I Samueli 9:27-10:1; 28:3-25; 2 Tim. 4:1-8

ALAYE ISAAJU

Oba Saulu ati Paulu Aposteli ni awon okunrin meji ti won ni ibasepo alailegbe pelu Olorun ti o

yi aye won pada patapata. Ni ile Sufi ni Saulu ti o je omokunrin Kisi ti ba Samueli wolii pade

nigba ti o n wa awon ketekete baba re ti won sonu. A yan Saulu gege bi oba Israeli kinni nigba ti

o ba Samueli pade. Paulu Aposteli ti o je Farisi ti oruko re tun n je Saulu ba Jesu pade ni ona

Damasku nigba ti o n lo lati se inunibini si awon omo eyin Jesu IAA 9:1.

Lehin igba ti Samueli wolii ti fi ami ororo yan Saulu ni Emi Olorun ti ba lee. Iyalenu ni o je fun

awon ti o rii nigba ti o n so asotele I Samueli 10:11. Nipa ti Saulu ara Tasisi, O se alabapade

Jesu Eni ti O fi Ara Re han fun un.

Saulu subu lese Jesu O si beere wi pe ki ni O fe ki oun ki o se (IAA 9:4-6). Iyipada de baa O si di

Paulu Aposteli ti o je ogbontagi, o di eni ti o sise takuntakun lati polongo ihinrere Kristi.

Oba Saulu ati Paulu Aposteli wa lati eya Benjamini. Oba Saulu tile se apejuwe idile re gege bi

eyi ti o kere ju ninu eya re ti ko si ka ara re si eni ti o ye lati di oba ile Israeli. Bakan naa ni Paulu

Aposteli so nipa ara re pe oun je eni ti o kere ju ninu awon Aposteli ti ko si ye ni eni ti a ba maa

pe ni Aposteli nitori pe oun se inunibini si ijo Olorun I Korinti 15:9.

Isina de ba oba Saulu ninu irin ajo re ni aye. O saigboran si Olorun ni opolopo igba o si tun fi

aaye gba ojukokoro, owu ati ilara lati di oro sinu okan re. Emi Olorun si dagbere fun un. Nigba ti

awon Filistini dide ogun sii, dipo ki o wa oju Olorun, o beere iranlowo lati odo aje Endori, o si

pari aye re gege bi aborisa. Ijoba Saulu ati igbesi aye re si pari pelu ibanuje.

Sugbon Paulu Aposteli duro sinsin ninu ipe re. O sa ere ije re pelu igboran patapata ti o fi so

leyin opin ise iranse re pe “Emi ti ja ija rere, emi ti pari ire-ije mi. emi pa igbagbo mo. Lati

isinsinyi lo a fi ade ododo lele fun mi” 2 Timoteu 4:7-8.

AWON IBEERE

1a. So die lara awon ijora ti o wa lara oba Saulu ati Paulu Aposteli (I Samueli 9:21, I Samueli

28:7-15; IAA 9:3-9; I Kor. 15:9; Fil. 3:5.

b. Kin ni awon iyato ti o wa laarin oba Saulu ati Paulu Aposteli?

2. Eko wo ni a le ko nipa igbe aye won?

ORO IPARI

Aigboran oba Saulu fa a kuro lodo Olorun ti igboran Paulu si faa si odo Re. O yipada o si di

olokiki ati alagbara Aposteli titi de opin.

Page 40: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE OGOJI - OJO KEJI OSU KOKANLA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Atubotan Iyipada Otun

KOKO ORO: ENI KOOKAN ATI IDILE

IBI-KIKA: Jer. 31:25-35, Iaa 22:6-16

ALAYE ISAAJU

Ninu irin ajo ile aye, nnkan maa n yipada lati ipo kan si omiiran. Eni kookan ni ifojusona wa fun

lati yipada si jijo Jesu Kristi ni afarawe ati wi pe won ko gbodo ni ibasepo pelu odiwon nnkan ti

aye (Romu 12:2).

Saulu gege bi enikan ni o yipada ni ibapade re pelu Jesu Kristi ni oju ona Damasku (IAA 22:6-

16).

Nihinyi Jeremiah fi han wa wi pe Olorun yoo da majemu titun pelu awon eniyan Re. Majemu yii

ni irubo Jesu Kristi fun irapada awon elese. Majemu titun yii ni o fun wa ni oore-ofe nipa Emi

Mimo (Jer. 31:34) eyi ti yoo ko wa ni eko ohun ti okan Olorun je (Johannu 14:26).

Oniruru iroyin nipa iyipada idile ni o wa ninu iwe mimo. Idile olori tubu naa ni o yi pada, nigba

ti o se eleri ifihan agbara Olorun ninu igbesi aye Paulu ati Sila ninu tubu (IAA 16:25-34). Bee

gege ni idile Koneliu yipada di akotun sinu Jesu Kristi (IAA 10:23-48).

Omo leyin Kristi gege bi eni ti o n lepa oke-orun, gbodo ni oye nipa Olorun ati lati rin ninu

igbala ati oore-ofe ti a n gbadun nipa Jesu Kristi. Gege bi idile Kristeni, a ni lati gbe igbe aye

ododo, ki a duro sinsin, alailegan ati otito gege bi odiwon ti Olorun

AWON IBEERE

1. Kin ni asotele gege bi a se ka ninu iwe Jeremiah 31:31-34?

2. Bawo ni asotele naa se mu iyipada wa sinu aye enikookan ati idile?

3. Kin ni awon ibukun ti o wa ninu gbigbe aye iyipada niwaju Olorun? (Efesu 5:27; Kolosse

1:21-22).

4. Kin ni awon anfaani otito oye Olorun ati oro Re ninu ijo Olorun ati orile ede Naijiria ni ode

oni?

ORO IPARI

Olododo ni Olorun wa; O si je alailegan. Nitori naa, awa idile Kristeni ko le sai ma lepa ati gbe

igbe aye olododo.

Page 41: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KOKANLELOGOJI - OJO KESAN OSU KOKANLA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Atubotan Iyipada Otun

KOKO ORO: ORILE EDE

IBI-KIKA: Owe 14:34, Danieli 6:19-28

ALAYE ISAAJU

Ni opolopo awon orile-ede ni ode oni, iwa-ododo ti di ohun ti a gbe si egbe kan. Iwa ododo ni o

n gbe orile ede leke. Iwa ododo je wiwa ni irepo pelu Olorun ati ni idalare. Opolopo awon asaaju

ati ara ilu ni ko si ni irepo pelu Olorun.

Lara awon iwa aleebu won yii ni gbigba abetele, ohun irira, ipanilaya, riru ofin, iborisa, ibalopo

aito, iwa ibaje, gbigbagbe ayika wa ati bee bee lo.

Ijo Olorun paapa ko sai ni ipin ninu awon iwa ibaje wonyii gege bi awon iwa aimo (abetele), fifi

iya je awon omode, ibalopo ti koye, ati ilopo okunrin pelu okunrin (I Korinti 5:1-2); nigba ti o

ye ki o je agbateru iyipada otun (Isaiah 2:2-3).

Ijo Olorun ni lati gbe aworan Olorun wo, ki o si je asiwaju ninu iyipada orile ede. Nigba ti orile-

ede kan ba yipada awon eniyan yoo ni afihan ibasepo otito pelu Olorun ati rinrin ni ona Re.

Nigba naa ni Olorun yoo mu ajakale-arun, ipanilaya, iyan ati bee bee lo kuro ni aarin won. Dipo

eyi, Olorun yoo pese aabo, ilera, ati aasiki fun won (2 Kronika 7:14).

AWON IBEERE

1. So kinnikinni ipo ti awon orile-ede wa ni ode oni gege bi iwe-mimo ti soo (Owe 14:34).

2. Bawo ni ijo Olorun se le je agbateru iyipada si awon orile ede?

ORO IPARI

Ara, e je ki imole yin ki o mole to bee ge niwaju eniyan, ki won ki o le maa ri ise rere yin, ki won

ki o le maa yin Baba yin ti nbe ni orun logo (Matteu 5:16); nigba ti iwa ododo tiwa je ti Jesu

Kristi Oluwa wa; nitori naa e je ki a duro sinsin ninu Re.

Page 42: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KEJILELOGOJI - OJO KERINDINLOGUN OSU KOKANLA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Atubotan Iyipada Otun

KOKO ORO: IDAPADA OLU ILU SI JERUSALEMU

IBI-KIKA: Jeremiah 31:27-40, Sekariah 8:1-8

ALAYE ISAAJU

Israeli je orile-ede ti Olorun da ti o si se agbekale re, O si ni ife si awon eto esin ati iselu won

gege bi orile-ede. Olorun da majemu pelu won pe Oun yoo je Olorun won ati pe won yoo je

eniyan Re. Majemu ayeraye ni eyi pelu awon eniyan Olorun. Imuse ti majemu yii duro lori sise

otito si awon ofin Re.

Gege bi eto iselu Israeli, Jerusalemu je Olu Ilu ti Dafidi se agbekale re nibi ti Tempili ati apoti eri

wa. O si tun je ibujoko ijoba. Israeli je alaisooto si Olorun nipa esin ati iselu won, bi o ti le je wi

pe Olorun kilo fun won lati enu awon woli Re. Ni opolopo igba ni Olorun fi aaye sile fun awon

orile-ede miiran lati fi iya je won nitori ese won. A ko won lo si igbekun ni ibi ti won ti lo

aadorin odun Jer. 31:28. Eyi lo fa ipadanu Jerusalemu gege bi Olu Ilu Israeli. Ko tun si eeto

iselu tabi ti esin awon Ju nitori pe lara ohun elo won ni a ti ko lo si igbekun, a si wo tempili pale.

Olorun je olotito ti ko je fi awon eniyan Re sile.

Ileri Olorun lati mu Jerusalemu pada bi Olu Ilu je ami iyipada Re. Olorun yoo mu awon eniyan

Re pada si ipo ti won ti wa tele ri. Eyi fihan wi pe Oluwa yoo fi Jerusalemu se ibugbe iwalaaye

Re yoO si wa ni Jerusalemu titi lae. A o mu awon eniyan Re pada lati gbogbo orile-ede ti Olorun

ti tu won ka si, Jerusalemu ni a o si maa pe ni ilu otito 2 Kor. 6:16 ati oke mimo Jer. 31:22,Joeli

2:1, Isaiah 6:3. Majemu ibasepo yii ni a o so di otun ati gbogbo agbegbe yoo kun fun iwalaaye

Olorun. Ileri idariji ati imupadabosipo ni yoo je ti gbogbo eniyan Olorun ni ibi gbogbo ti a ti le ri

won Deut. 30:3, Heb. 8:10. Ogo Jerusalemu ti a ti so asotele re yoo bere si farahan.

AWON IBEERE

1. Bawo ni Jerusalemu se di Olu Ilu Israeli?

2. Kin ni o fa ipadanu Jerusalemu gege bi Olu Ilu?

3. Kin ni eeto Olorun fun imupada Olu Ilu si Jerusalemu? Luku 1:23, Saamu 102:13-16,

Saamu 122:6.

4. N je o seese fun Olorun lati mu eniyan ti o ti sako lo pada si odo Re. Seka. 8:4-5.

ORO IPARI

Ohun gbogbo ni sise fun Olorun Luku 1:37.

Page 43: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KETALELOGOJI - OJO KETALELOGUN OSU KOKANLA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Atubotan Iyipada Otun

KOKO ORO: IJO AJAGUN / IJO ASEGUN

IBI-KIKA: Johannu 17:21-25; I Korinti 12:12-21

ALAYE ISAAJU

Ijo ti a nsoro re yii je apapo awon eniyan Olorun ti won ko ara won jo labe olori kan, Jesu Kristi

(Efesu 2:19-22).Ijo pin si meji, ti agbaye (eyi ni ijo Ajagun) ati ti oke orun (Ijo Asegun).

Ijo Ajagun ni apapo awon onigbagbo ti won ko i tii joko pelu Kristi ni orun sugbon ti won si n ja

ijakadi lati gba isegun lori Satani. Ijo Asegun ewe, gege bi irisi ti Bibeli fun wa, je apapo awon

onigbagbo ti a ti pa lara da, ti won si ti joko pelu Kristi ni awon orun “Ga ju gbogbo ijoba ati ola

ati agbara” (Efesu 1:21; 2:6). Awon wonyi ni yoo joba pelu Jesu Kristi ni isegun lori Satani, ota

ti a ti segun re.

Ireti Jesu fun Ijo Ajagun ni pe ki won wa ni isokan ki won si maa te siwaju ninu ise Oun, lati

maa yin Olorun ati lati maa waasu ihinrere leyin ti Oun ba ti lo (Johannu 17:21-23). Eya kookan

ninu ijo yii ni o se pataki ti a si gbodo fun ni owo ti o ye. Ise Ijo Ajagun ni lati tan ihinrere igbala

ka gbogbo aye (2 Tim. 4:1-2), ki won le mura awon eniyan sile fun iyipada sinu Ijo Asegun.

Jesu, eniti O je Olori ijo so wi pe Oun ki yoo pada wa titi ti ihinrere naa yoo fi kari gbogbo

agbaye (Matt. 24:14).

Leyin ti ihinrere naa ba ti tan ka gbogbo aye ni igbasoke yoo to sele. Gbogbo awon ti won ti gba

ihinrere naa ni a o pa lara da di eni mimo ti won yoo dide ti a o si gba won soke sodo Oluwa won

Jesu Kristi. Awon wonyi ni yoo si di Ijo Asegun ti won yoo maa yin Olorun lojoojumo ni orun

(Ifihan 7:13-17). Awon wonyi naa ni won yoo tun ba Jesu wa nigba ti O ba n pada bo leekeji lati

wa se idajo awon alaiwa-bi-Olorun (Juda 14-15).

AWON IBEERE

1. Kin ni awon wonyi se ye o si:

(a) Ijo Ajagun? IAA 7:51-60; I Kor. 12:10

(b) Ijo Asegun? Ifihan 7:13-17

2. Kin ni iyato laarin “Igbasoke” ati “Ipadabo Jesu leekeji”? I Tess. 4:13-17; Juda 1:14;

Ifihan 19:11-14.

3. Kin ni idi ti o se lodi fun wa lati maa da awon eya Kristeni miiran lebi? Romu 14:1-4; Luku

9:49-50.

ORO IPARI

Dajudaju Jesu n pada bo. E je ki awa ti a si wa ni Ijo Ajagun maa ja ija rere naa ki a le gba ade

iye ainipekun.

Page 44: IPADE OJULE KINNI - OGUNJO OSU KINNI ODUN 2020 …...ipade ojule keji - ojo ketadinlogbon osu kinni odun 2020 agbeyewo: iyipada otun eka agbeyewo: nini oye nipa iyipada ati ilana re

IPADE OJULE KERINLELOGOJI - OGBON OJO OSU KOKANLA ODUN 2020

AGBEYEWO: IYIPADA OTUN

EKA AGBEYEWO: Atubotan Iyipada Otun

KOKO ORO: JERUSALEMU TITUN

IBI-KIKA: Ifihan 21:1-27

ALAYE ISAAJU

Jeresalemu titun ni a tun le pe ni Ago ti Olorun, ilu nla ti o je mimo, ilu nla ti Olorun ati ilu nla ti

orun ati bee bee lo. A tile le so pe orun ti o wa ninu aye sugbon ti a ko fi owo eniyan ko. A toka

sii ni orisirisi ona ninu Bibeli gege bi a ti rii ni (Galatia 4:23-26, Heberu 11:10), sugbon a se

apejuwe re ni kikun ninu ibi kika wa. O je ibi ti o pe ti o si je ibi ayeraye fun ojo iwaju (Ifihan

21:2). Jerusalemu titun yii je apeere iwa ododo, alaafia ati aasiki ibugbe Olorun ati Ijo Re

(iyawo, aya odo aguntan) (Ifihan 21:9). Johannu ko ri tempili ni Jerusalemu Titun “nitori pe

Oluwa Olorun Olodumare ni tempili re ati odo aguntan”Ifihan 21:22.

Bibeli se akosile ibugbe Olorun ti ewa re ko lafiwe; O ba eniyan rin ninu ogba Edeni, O ba awon

omo Israeli gbe ninu ago, leyin eyi ninu tempili. Ese ti awon omo Israeli da ni o je ki iwalaaye

Olorun fi awon ibugbe wonyi sile. Jesu Kristi ba wa gbe nigba ti O wa si aye (Johannu 1:14). Ni

ode oni Olorun ko gbe ninu awon tempili ti a ti owo eniyan ko (IAA 7:4), sugbon ninu wa nitori

pe nitori ara wa ni tempili Emi Mimo (I Korinti 6:19-20).

A gba eni ti a ti ra pada niyanju pe bi o tile je pe wahala wa ninu aye yii ibi ireti kan wa

(Jerusalemu Titun) nibi ti ki yoo si irora, ekun, ibanuje tabi iku.

AWON IBEERE

1. Se apejuwe Jerusalemu Titun bi o se ye o si.

2. Bawo ni imo wa nipa Jerusalem Titun se ran wa lowo ninu irin ajo wa gege bi onigbagbo.

Jiroro lori IOM 253:1.

ORO IPARI

Jerusalemu ile ayo mi

Oruko ti o sowon fun mi

Nigba wo ni wahala mi yoo dopin

Ninu ayo, alaafia ati iwo? CH 158