33
WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG Olójoojúḿ O Ù K RIN DÚN 2018 ‘Wole Aderinwale

Olójoojúmọ́ - s3-us-west-2.amazonaws.com2018.pdfA ó se àgbéyẹ̀wò àdúrà tí Jesu kọ́àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀yìí, èyí tí a n pè ní àdúrà Olúwa. Ohun

  • Upload
    others

  • View
    0

  • Download
    0

Embed Size (px)

Citation preview

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Olójoojúmọ́

    OṢÙ KẸRIN ỌDÚN 2018

    ‘Wole Aderinwale

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    ÀÌKÚ AJÉ ÌSẸ́GUN ỌJỌ́RÚ ỌJỌ́BỌ ̀

    ẸTÌ ÀBÁMẸ́TA

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ 1 2 3

    4 5 6 7

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ 8 9 10

    11 12 13 14

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ 15 16 17

    18 19 20 21

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ IBÙGBÉ ẸM̀Í MÍMỌ ́ 22 23 24

    25 26 27 28

    TA LÓ NÍ Ẹ̀MÍ MÍMỌ?́ 29 30

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kinni, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (1)

    Matiu 6:9-13

    Nítorí náà, báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbadura: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run: Kí á bọ̀wọ̀ fún orúkọ mímọ́ rẹ, 10kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run. 11Fún wa ní oúnjẹ òòjọ́ wa lónìí. 12 Dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá gẹ́gẹ́ bí àwa náà ti dárí ji àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ wá.13Má fà wá sinu ìdánwò, ṣugbọn gbà wá lọ́wọ́ èṣù.’

    Jésù ni ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ ní àdúrà yìí nígbà tí wọ́n bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa àdúrà gbígbà. Lẹh́ìn ìgbà tí Jesu kú tó sì jíǹde kúrò nínú òkú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni àwọn ọmọlẹýìn rẹ̀, àwọn Aposteli àti àwọn Kristẹni káàkiri gbogbo àgbáye. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà náà ní a ní ànfààní láti rí kókó àdúrà wọn kà nínú àkọsílẹ̀. Ohun tó seni ní kàyééfì ni wípé lẹh́ìn ìgbà tí Jesu kọ́ wọn ní àdúrà yìí, kò sí ọkan nínú wọn tó gba irú àdúrà yìí tàbí ohun tó fara jọ àdúrà yii. Kílóde? Njẹ ́wọn lòdì sí ìlànà Kristi nípa àdúrà ni?

    Tí a bá fẹ ́kí àkòrí ọ̀rọ̀ tàbí ẹ̀kọ́ Bibeli kan tàbí òmíràn yé wa, àwọn ìbéèrè pàtàkì tó yẹ ́kí a bèèrè náà ní wípé “Kíni Bibeli sọ nípa ohun yìị kí Jesu tó kú ati jíǹde kúrò nínú òkú? Kíni Bibeli sọ nípa rẹ̀ lẹh́ìn ìgbà tí Jesu jíǹde kúrò nínú òkú?” Ohun pàtàkì tí ó yẹ kí a mọ̀ ni wípé àwọn ẹ̀kọ́ kan wà tó jẹ ́wípe Jesu kọ́ nítorí àwọn olùgbọ́ rẹ̀ nígbà náà ni.

    A ó se àgbéyẹ̀wò àdúrà tí Jesu kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ yìí, èyí tí a n pè ní àdúrà Olúwa.

    Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ ́kí a mọ̀ ni wípé àdúrà yìí kìíse àdúrà májẹ̀mú titún. Ìdí èyí ni wípé nígbàtí Jesu kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ ní àdúrà yìí, májẹ̀mú titun kò tíì bẹ̀rẹ̀. Lóòótọ́, abala Bibeli tí àwọn òǹtẹ̀wé Bibeli pè ní májẹ̀mú titun (Matiu titi de ìwé Ìfihàn), ni a kọ àdúrà yìí sí, sùgbọ́n àwọn ìsẹ̀lẹ̀ tó mú májẹ̀mú titun wá sáyé kò tíì sẹlẹ̀ nígbà náà. Nítorínáà gbogbo àwọn tó wà láyé nígbànáà wà lábẹ ́májẹ̀mú láéláé.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kejì, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (2)

    Ìgbà wo gan ni májẹ̀mú titún bẹ̀rẹ̀?

    “Nitori eyi li ẹ̀jẹ mi ti majẹmu titun, ti a ta silẹ fun ọ̀pọ enia fun imukuro ẹ̀ṣẹ” (Matiu 26:28)

    “O si fẹrẹ jẹ́ ohun gbogbo li a fi ẹ̀jẹ wẹ̀nu gẹgẹ bi ofin; ati laisi itajẹsilẹ kò si idariji” (Heberu 9:22)

    Nítorínáà, ẹ̀jẹ̀ Jesu ni a fi se èdìdí májẹ̀mú títún. Gbogbo ohun tó sẹlẹ̀ nínú àwọn Ìhìnrere mẹŕin (Matiu, Marku, Luku ati Johanu) kí Jesu tó kú sẹlẹ̀ lábẹ ́májẹ̀mú láéáé. Bẹẹ̀́ náà sì ni ẹ̀kọ́ nípa àdúrà tí Jesu kọ́ àwọn ọmọlẹýìn rẹ̀ ní ìgbà náà. Tó bá jẹ ́wípé àdúrà náà nííṣe pẹ̀lú àwọn tó wà lábẹ̀ májẹ̀mú titun, a kò bá rí àpẹẹrẹ wípé àwọn ọmọlẹýìn rẹ̀ gba àdúrà náà lẹh́ìn ìgbà tí Jesu kọ́ wọn.

    Ó se pàtàkì láti mọ̀ wípé gbogbo ìlànà ẹ̀kọ́ tó nííṣe pẹ̀lú ìgbàgbọ́ Kristẹni dúró lórí ẹ̀kọ́ tí àwọn Aposteli Kristi kọ́ nípa àdúrà.

    Ọpọlọpọ máa n rò wípé kò yẹ ́kí a àwọn ẹ̀kọ́ Bibeli nínú àwọn Episteli látí ọwọ àwọn Aposteli Kristi se pàtàkì ju àwọn ẹ̀kọ́ tí Krístì gàn fúnra ara rẹ̀ kọ́ lọ. Kò rí bẹẹ̀́ rárá. Kò sí onígbàgbọ́ kankan tàbí àtúnbí kan láyé nígbàtí Jesu n se isẹ ́ìránsẹ ́rẹ̀. Ìdí èyí ni wípé kò sí ẹnikẹni tó lè di àtúnbí àyàfi tí Jesu bá kú tó sì jíǹde kúrò nínú òkú

    “Pe, bi iwọ ba fi ẹnu rẹ jẹwọ Jesu li Oluwa, ti iwọ si gbagbọ́ li ọkàn rẹ pe, Ọlọrun jí i dide kuro ninu okú, a o gbà ọ là” (Romu 10:9)

    Nígbà tí Jesu Olúwa kọ́ àwọn ènìyàn nípa àdúrà Olúwa yìí, kò sí ẹnìkan tó ní Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà yẹn náà. Ìdí rẹ̀ ní wípé, nípa àjínde àti ìgòkè re ọ̀run ní ni Jesu fi tú ẹ̀mí Mịmọ́ sílẹ.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ìsẹ́gun, Ọjọ́ Kẹta, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (3)

    Kí Jesu Oluwa tó kú àti jíǹde kúrò nínú òkú, gbogbo àwọn tó wà láyé nígbà náà ló jẹ ́ẹlẹṣ́ẹ̀̀. Ìdí èyí ni wípé Jesu kò tii kó ẹ̀sẹ̀ lọ́ nígbà náà nítorípé nípa ikú rẹ̀ ló fi kó ẹ̀sẹ̀ lọ.

    “]Bi bẹk̃ọ on kì bá ṣai mã jìya nigbakugba lati ipilẹ aiye: ṣugbọn nisisiyi li o fi ara hàn lẹk̃anṣoṣo li opin aiye lati mu ẹ̀ṣẹ kuro nipa ẹbọ ara rẹ̀.” (Heberu 9:26)

    Ní àkópọ̀, àwọn tí Jesu kọ́ ní ẹ̀kọ́ nígbà náà jẹ ́kò tíì di àtúnbí, tí wọn jẹ ́ẹlẹśẹ̀, wọn kò sì ní Ẹ̀mí mímọ́. Èyí kò yọ àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ sílẹ̀ rárá nítorípé Jesu kò tíì kú fún ẹnikẹńi nígbà náà. Èyí ló fàá tí Jesu se sọ wípé nígbàtí ohun bá ti jíǹde kúrò nínú okú ni ohun yóò fún wọn ní ilérí ẹ̀mí mímọ́. Nítórịpé Jesu mọ̀ wípé ohun kò ní wà pẹ̀lú wọn nịpa tí ara mọ́ nígbà náà láti máà kọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ tó niise pẹ̀lú onígbàgbọ́ tàbí àwọn tó ti di àtúnbí, ó sọ wípé Ẹ̀mí Mímọ́ yìị ni yóò máa kọ́ wọn nị ohun gbogbo.

    “Ṣugbọn nigbati on, ani Ẹmí otitọ ni ba de, yio tọ́ nyin si ọ̀na otitọ gbogbo; nitori kì yio sọ̀ ti ara rẹ̀; ṣugbọn ohunkohun ti o ba gbọ́, on ni yio ma sọ: yio si sọ ohun ti mbọ̀ fun nyin” (Johanu 16:13)

    Àwọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ́ wọn náà ni wọn kọ sílẹ̀ ninú àwọn Episteli wọn sí gbogbo àwọn ìjọ Ọlọrun. Nítorí èyí, tí a bá fẹ ́kọ́ ẹ̀kọ́ tó yege nípà àdúrà gbígbà, ohun tó yẹ kí a se náà ní wípé kí a wo ohun tí àwọn Episteli náà kọ́ wa nípa àdúrà.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́rú, Ọjọ́ Kẹrin, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (4)

    “Emi kò si simi lati mã dupẹ nitori nyin, ati lati mã darukọ nyin ninu adura mi” (Efesu 1:16)

    Àsà àti ìse àwọn Aposteli Kristi ni láti máa gbàdúrà fún àwọn ìjọ Ọlọrun nínú àwọn lẹt́à wọn. Paalu pàápàá jùlọ máa n se èyí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwé tọ kọ sí àwọn ìjọ. Àkíyèsí pàtàkì ni wípé, kò sí ibì kan tó tí gbàdúrà Oluwa tí Jesu kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀hìn rẹ̀ tàbí tó ti gbà àwọn ènìyàn níyànjú láti máa gba irú àdúrà náà. Bẹẹ̀́ ni àwọn Aposteli yookù kò mẹńuba ohun kan nípa àdúrà náà.

    Kí ló fa èyí? Tí a bá wo àdúrà yìí fínífíní, a ó rị wípé àwọn kókó àdúrà tó jẹyọ nínú àdúrà náà tako àwọn ọ̀títọ́ májẹ̀mú titun. Fún àpẹẹrẹ “Jẹ ́kí ìjọba rẹ dé”.

    Kí Jesu tó jíǹde kúrò nínú òkú, ìwàásù tí wòn máa n wàásù ní wípé ijọba Ọlọrun kù sí dẹ̀dẹ̀̀. Ìyẹń ni wípé ìjọba Ọlọrun kò tíì dé nígbà náà nìyẹn

    “O si nwipe, Ẹ ronupiwada; nitori ijọba ọrun kù si dẹ̀dẹ̀.” (Matiu 3:2)

    Sùgbọ́n lẹh́ìn ìgbà tí Kristi jíǹde, kò sí ibì kankan tí a ti rí irú ìwàásù èyí mọ́. Ohun tí wọn tẹnumọ́ náà ni ajinde Kristi àti ìwẹ̀numọ́ ẹ̀sẹ̀ nịpà ikú àti àjinde rẹ̀. Ìjọ́ba Ọlọrun tụmọ̀ sí ìwàláàyè Ọlọrun nịnú ọmọ ènìyàn. Àjínde Krsiti ló mú èyí wá gẹǵẹ ́bí Peteru se sọ nínú Ìwé Ise Awọn Aposteli.

    Ní ìgbà tí Jesu ti tú Ẹ̀mí Mímọ́ sílẹ̀, kò sí ìdí tí o tún fi yẹ kí a máà sọ wípé kí ìjọba rẹ̀ de mọ́. Ọnà tí Ọlọrun fi n jọba nínú ènìyàn ni nípa Ẹ̀mi Mímọ́. Gbogbo onígbàgbọ́ pátápátá ló sì ní Ẹ̀mí Mímọ́ yìí. Ẹni tí kò bá ní Ẹ̀mí Mímọ́ kìíse ọmọ Ọlọrun rárá

    Nítorínáà, “jẹ ́kí ìjọba rẹ dé” jẹ ́àdúrà fún àwọn tó wà lábẹ ́òfin nígbà náà, kìíse àdúrà ẹni tó bá ti di àtúnbí. (Korinti Kinni 3:16, Korinti Keji 6:16, Romu 8:9)

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Karùún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (5)

    Gbólóhùn tó tún yẹ kí a gbé yẹ̀wò nínú àdúrà Olúwa yìí ni “ifẹ ́tìrẹ ni kí á se ní ayé bíi ti ọ̀run”. Kí ni èyí túmọ̀ sí? Kíni ìfẹ ́Ọlọrun? Ìlànà pàtàkì nínú síse ìtumọ̀ Bibeli ni wípé tí a bá fẹ ́ìtumọ̀ gbólóhun kan nínú ẹsẹ Bibeli tí à n kà, inú ibi kíkà yẹn náà ní a ó tí rí ìtúmọ̀ rẹ̀.

    Nítorínáà, a ó wo gbolohun tó siwájú “ifẹ ́tìrẹ ni kí á se ní ayé bíi ti ọ̀run” nínú ibi kíkà yìí.

    “kí ìjọba rẹ dé, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́n ti ń ṣe ní ọ̀run”

    Lóòọtọ́ gbólóhùn méjí ló wà ní ẹsẹ Bibeli yìị sùgbọ́n kókó àdúrà kan lo wà níbẹ̀. “kí ìjọba rẹ dé” túmọ̀ sí “ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́ n ti ń ṣe ní ọ̀ run”. Èyí ní wípé ìfẹ ́inú Ọlọrun ni wípé kí ìjọba rẹ̀ dé. Ìjọba rẹ̀ túmọ̀ sí bí Ọlọrun yóò se máa jọba nínú onígbàgbọ́ gẹǵẹ ́bí ó se n jọba ní ọrun. Èyí ní ìfẹ ́Ọlọrun láti ìbẹ̀ẹ̀rẹ̀ wá. Ìdí èyí ni Wòlíì Esekieli se sọ nípa èyí.

    “Agọ mi yio wà pẹlu wọn: nitõtọ, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi” (Esekieli 37:27)

    Èyí wá sí imúsẹ ninú májẹ̀mú titún.

    “Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.” (Korinti Keji 6:16)

    Nítorínáà, “ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́ n ti ń ṣe ní ọ̀ run” jẹ ́àdúrà tó ti wá sí ìmúṣe ní ìwọ̀n ìgbà tí a ti wà ní abẹ ́májẹ̀mú titun báyìí. Njẹ ́ó yẹ kí a máa gba irú àdúrà yìí? Tó bá jẹ ́wípé a mọ ìfẹ ́Ọlọrun lórí ohun kan pàtó, a lè gbàdúrà kí ìfẹ ́Ọlọrun lè wá sí ìmúṣe. Sùgbọ́n nínú àdúrà Olúwa tí à n se àgbéyẹ̀wò rẹ̀ yìí, kìíse àdúrà tó yẹ fún wa látí gbà gẹǵẹ ́bí onígbàgbọ́.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Kẹfà, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (6)

    “Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹñi li aiye” (Matiu 6:10)

    Tí a bá se ìlérí ohun kan, tí a si mú ìlérí náà sẹ, kò tún yẹ kí ẹnìkan tún máa rọ̀ wa tàbí bẹ̀ wá kí a mú ìlérí náà sẹ̀ mọ́. Ọlọrun ti mú ìlérí rẹ̀ sẹ nípa ìfifúni Ẹ̀mí Mímọ́. Gẹǵẹ ́bí onígbàgbọ́ se gba Ẹ̀mi Mímọ́ ni ìmúsẹ “ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe ní ayé bí wọ́ n ti ń ṣe ní ọ̀ run”. Èyí ní wípé gẹǵẹ ́bí Ọlọrun se wà láàyè tó ní ọ̀run náà lo n jọba nínú onígbàgbọ́ nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Èyí tún jẹ ́kí a mọ̀ síwájú si nípa ìdí rẹ̀ tí àwọn Aposteli Kristi kò gba àdúrà Oluwa.

    “dárí ẹ̀sẹ̀ wa jìwá gẹ́gẹ́ bí a ti n dárí jí àwọn onígbèsè wa”

    Tí a bá wo gbólóhùn yìí, a ó ri wípé, ẹ̀kọ́ kan pàtàkì tó jẹyọ nínụ rẹ̀ náà ni wípé tị a kò bá dárí ji àwọn tó sẹ̀ wa, ó jẹ ́wípé Ọlọrun tò ní dárí ẹ̀sẹ̀ wa jì wá. Ó fẹ dabi wipe Ọlọrun jẹ ́Ọlọrun se fúnmi kí èmi náà se fún ọ.

    Njẹ ́ohun tí májẹ̀mú titun kọ́ wa nípa gbígba ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ láti ọdọ Ọlọrun lèyí? A ó se àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lórí ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ lábẹ ́májẹ̀mú titun. Tó bá jẹ ́wípé bí ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ se rí ni èyí lábẹ májẹ̀mú titun, a jẹ ́wípé ó tọ̀nà láti máa gbà àdúrà náà lábẹ ́májẹ̀mu titun nìyẹn. Sùgbọ́n bí kò bá rí bẹẹ̀̀́, a jẹ ́wípé kò yẹ ́fún wa lábẹ̀ májẹ̀mú titun.

    “Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀” (Efesu 1:7)

    Bawo ní a se rí ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ gbà? Njẹ ́ẹsẹ Bibeli yìí sọ fụn wa wípé a rí ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ gbà nítorí a dariji àwọn tó sẹ̀ wá? Ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ ́rẹ̀ ní a fí ní ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ gbà. Oore-ọ̀fẹ ́yìí sì fara hàn nípa wípé ó Jesu ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀ láti rà wa padà kúrò nínú ẹ̀sẹ̀.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Keje, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (7)

    Lánàá a sọ wipé gbólóhùn tí Jesu sọ wípé “dárí ẹ̀sẹ̀ wa jìwá gẹ́gẹ́ bí a ti n dárí jí àwọn onígbèsè wa” kò niise pẹ̀lú àwa tí a gba Jesu gbọ́ lẹ̀hìn ìgbà tó ti jíǹde kúrò ninú òkú nítorípé kìíse wipé ìwà wa ni Ọlọ́run wò mọ́ wa lára láti dàri ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá bikose nítorí ẹ̀jẹ̀ Jesu ọmọ rẹ̀.

    “Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun” (Romu 3:25)

    Ẹsẹ yìị náà tún fi yé wa wípé nípa ẹ̀jẹ̀ Jesu ni a fi rí ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ gbà.

    “[4]Ṣugbọn nigbati ìṣeun Ọlọrun Olugbala wa ati ifẹ rẹ̀ si enia farahan, [5]Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́,” (Titu 3:4-5)

    Nítorínáà a ti ríi nínú gbogbo ẹsẹ Bibeli tí a kà yìí wípé ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ nííṣe pẹ̀lú ikú àti àjínde Jesu kìíse nítorí tí a dariji ọmọnìkejì wa. Lóòótọ́ Bibeli gbà wá ní ìyànjú láti dariji ọmọnìkejì sùgbọ́n kò sí ẹsẹ Bibeli kankan nínú àwọn èpisteli (abala tó se pàtàkì jù wà fún gbogbo onígbàgbọ́) tó sọ fún wa wípé ìdí rẹ̀ tó fi yẹ kí a máa dariji ẹnikejì ni wípé kí Ọlọrun lè dariji wa. Tó bá rí bẹẹ̀́ ni, kini iìdí rẹ̀ tí Jesu fi kú nígbà yẹn?

    Tí ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ bá ti di ohun tí à n sisẹ ́fun, kìíse oore-ọ̀fẹ ́mọ́ nìyẹn. Nítorínáà, ó ti hàn kedere báyìí wípé Ọlọrun fẹ ́kí a dárí ẹ̀sẹ̀ jí àwọn tó sẹ̀ wá, sùgbọ́n kìíse nítorípé a dárí ẹ̀sẹ̀ ji àwọn ènìyàn ló se dariji wá bíkòṣe nínú oore-ọ̀fẹ ́rẹ̀. Èyí fihàn wa wịpe “dárí ẹ̀sẹ̀ wa jìwá gẹǵẹ ́bí a ti n dárí jí àwọn onígbèsè wa” kìíse àdúrà ẹni tó wà lábẹ ́májẹ̀mú titun.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

    .

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kẹjọ, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (8)

    “[9]Nitorina bayi ni ki ẹnyin mã gbadura: Baba wa ti mbẹ li ọrun; Ki a bọ̀wọ fun orukọ rẹ.[10]Ki ijọba rẹ de; Ifẹ tirẹ ni ki a ṣe, bi ti ọrun, bẹñi li aiye. [11]Fun wa li onjẹ õjọ wa loni. [12]Dari gbese wa jì wa, bi awa ti ndarijì awọn onigbese wa. [13]Má si fà wa sinu idẹwò, ṣugbọn gbà wa lọwọ bilisi. Nitori ijọba ni tirẹ, ati agbara, ati ogo, lailai. Amin.” (Matiu 6:9-13)

    Lóòótọ́ àdúrà Olúwa kìíse àdúrà onígbàgbọ́ tó wà lábẹ ́májẹ̀mú titun sùgbọ́n ẹ̀kọ́ pàtàkì wà tí a lè rí kọ́ níbẹ̀. Àdúrà náà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú “Baba wa tí mbẹ ní ọ̀run”. Èyí n fi yé wa wípé àdúrà jẹ ́ọ̀rọ̀ láàrin Baba àti ọmọ. Ohun tí èyí jásí se pàtàkì lọ́pọ̀lọpọ̀. Ní àkọ́kọ́, ó jẹ ́kí á mọ̀ wịpé ojú tó yẹ kí a máa wo Ọlọrun ninú àdúrà náà ni ojú tí a fi n wo baba wa tó fẹŕàn wa nípa tí ara.

    “Njẹ bi ẹnyin ti iṣe enia buburu, ba mọ̀ bi ã ti fi ẹ̀bun rere fun awọn ọmọ nyin, melomelo ni Baba nyin ti mbẹ li ọrun yio fi ohun rere fun awọn ti o bère lọwọ rẹ̀?” (Matiu 7:11)

    Ojú tí ọ̀pọlọpọ̀ máa fi n wo Ọlọrun ni ojú ẹní tí kò fẹ ́gbọ́ àdúrà wa rárá ṣugbọn tó bá ri wípé ìyà jẹ wá dáradára tàbí bí a bá sọkún kíkorò tàbí tị a bá fí omijé bèèrè yóò dá wa lohùn. Kò yẹ kó rí bẹẹ̀́ rárá. Tó bá jẹ ́wípé gẹǵẹ ́bí òbí nịpa ti ara, a kò lè retí kí ọmọ wa jẹ̀yà, sọkún kíkorò gidigidi kí a to fún ní ohun tó fẹ,́ kilóde tí a wá n fojú ìkà wo Ọlọrun de ibi wípé a ó wòó bí wịpé kò fẹ ́fún wa. Jesú sọ fún wa wípe baba wa tí mbẹ ní ọ̀run mọ ohun gbogbo tí a nílò kị a tó bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀.

    “Nitori gbogbo nkan wọnyi li awọn keferi nwá kiri. Nitori Baba nyin ti mbẹ li ọrun mọ̀ pe, ẹnyin kò le ṣe alaini gbogbo nkan wọnyi.” (Matiu 6:32)

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kẹsan, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (9)

    Tị a kò bá rí Ọlọrun pẹ̀lú ojú tí a fi n wo baba wa tó fẹ ́wa, n se ni a ó máa gbàdúrà pẹ̀lú àìgbàgbọ́. À gọ́dọ̀ mọ̀ wịpé Ọlọrun setán láti gbọ́ àdúrà wa ju bí àwa gan se setán lái bèèrè lọ. Dídùn inú Ọlọrun ni láti gbọ́ àdúrà wa. Ìdí èyí ni a fi ríi wipé kò sí ibi kàkàn nínú Bibeli tí a lè rí tọ́ka sọ wípé Ọlọrun kọ àdúrà ẹnìkan tàbí òmíràn. Ìtàn ọmọ tó sọnù nínú ìwẹ Luku 15 jẹ ́kí a mọ pàtàki ìbásepọ̀ tó wà láàrin baba àti ọmọ.

    “[17]Ṣugbọn nigbati oju rẹ̀ walẹ, o ni, Awọn alagbaṣe baba mi melomelo li o ni onjẹ ajẹyó, ati ajẹtì, emi si nkú fun ebi nihin. [18]Emi o dide, emi o si tọ̀ baba mi lọ, emi o si wi fun u pe, Baba, emi ti dẹṣẹ si ọrun, ati niwaju rẹ; [19]Emi kò si yẹ, li ẹniti a ba ma pè li ọmọ rẹ mọ́; fi mi ṣe bi ọkan ninu awọn alagbaṣe rẹ. [20] O si dide, o si tọ̀ baba rẹ̀ lọ. Ṣugbọn nigbati o si wà li òkere, baba rẹ̀ ri i, ãnu ṣe e, o si sure, o rọ̀mọ́ ọ li ọrùn, o si fi ẹnu kò o li ẹnu.” (Luku 15:17-20)

    Á ó rí wípé ọmọ náà rò wípé baba kò le gbọ́ ti ohun mọ́ rárá. Sùgbọ́n ohun tí baba ọmọ náà se ní ìgbà tó dé yàá lẹńu. Baba rẹ setan láti fún ju ohun tó pinnu láti bèèrè lọ. Bí ìfẹ ́tó wà láàrin baba àti ọmọ se rí nìyẹn. Ìdí èyí ní Jesu se sọ wípé kí wọn mọ̀ wịpé àdúrà nííṣe pẹ̀lú ibásepọ̀ tó wà láàrin baba àti ọmọ.

    Jesu sọ wipé tí ẹ bá n gbàdúrà ẹ máa wípé “baba wa tí mbẹ ní ọ̀run”

    Kí Jesu tó wá sáyé, orísirísi orúkọ ní àwọn ènìyàn máa fi n pe Ọlọrun gẹǵẹ ́bí orísirísi àwọn ìrírí tí ẹnìkọ̀ọ̀kan bá ní pẹ̀lú rẹ̀. Bí ẹ̀nìkan ti n pèé ní Jehofa Jire, bẹẹ̀́ ni ẹlòmíràn a máa pèé ní El Shaddai àti bẹẹ̀́bẹẹ̀́ lọ. Sùgbọ́n kò sí ẹnikan tó mọ Ọlọrun gẹǵẹ ́bi baba wa. Jesu ni ẹni àkọ́kọ́ tó pe Ọlọrun ní baba. Kìíse wípé èyí se kàyéfì fún àwọn Juu nìkan sùgbọ́n ó tún jẹ ́ohun tó bí wọn nínú gidigidi nítorípé Jesu pe Ọlọrun ni Baba rẹ̀.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹwàá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (10)

    Ó se pàtākí kí onígbāgbọ́ mọ̀ dájú irú ìbásepọ̀ tó wà láàrin on àti Ọlọ́run nítorípé lòrí èyí ni àdúrà onígbàgbọ́ dúro lórí.

    “Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin.” (Johanu 16:23)

    Èyí se pàtàki kí a mọ̀ gẹǵẹ ́bí onígbàgbọ́ wípé lóòótọ́, Ọlọrun jẹ ́Ọlọrun fún gbogbo ènìyàn àtí fún gbogbo ẹ̀dá alààyè, sùgbọ́n kìíse baba fún gbogbo ènìyàn. Ó jẹ ́baba fún àwà tí a bá ti gba Jesu gbọ́ nìkan. Ọlọrun jẹ ́baba wa nípa wípé a to bí wa ni ti Ọlọrun. Gbgbo ẹní tó ti di àtúnbí ni a ti bí nípa ti Ọlọrin láì yọ ẹnìkan sílẹ̀. ” (Peteru Kinni 1:3, Johanu Kinni 3:10)

    Bí gbogbo wa si se jẹ ́ọmọ Ọlọrun, ó yẹ kí a mọ̀ wípé nípasẹ̀ Kristi ni a se di ọmọ Ọlọrun. Nítorínáà, Ọlọrun fẹ ́wa gẹǵẹ ́bó se fẹ ́Kristi náà ni. Síwájú, o tún yẹ kí a mọ̀ wípé nítorí Ọlọrun kò fẹŕàn Kristi ju wá lọ, Ọlọrun a gbọ́ àdúrà wa gẹǵẹ ́bó se gbọ́ àdúrà Krístì.

    Gbogbo ẹ̀tọ́ tó tọ́ sí Kristi ninú àdúrà náà ló tọ́ sí wa nínú àdúrà. Kò sí ìgbà kan tí Ọlọrun kò gbọ́ àdúrà Kristi. Kò sí ìgbà kan tí Kristi se ìyèméjì wípé bóyá Ọlọrun kò ní gbọ́ àdúrà ohun. Nitorínàà, kò sí ìgbà kan tí Ọlọrun yóò kọ àdúrà wa nítorí a ti ní ètọ́ kan náà tí Kristi ní níwájú Ọlọrun. Ìdí èyí ni Jesu se sọ wípé ní ìwọn tí ohun bá padà lọ sọ́dọ̀ baba, ohun kò ní bẹ̀bẹ̀ fún wa mọ́ sugbọn fúnra wa ni a ó máa bèèrè ohun tí a bá cẹ ́lọ́dọ̀ baba àti wípé baba funra rẹ̀ gan ni yóò ma se ohun tí a bá fẹ ́fún wa.

    Àwọn Aposteli Krístì mọ èyí, nitorínàà ni wọn se máa n pe Ọlọrun ní baba ní gbogbo ìgbà. Wọn mọ̀ wípé orísirísi orúkọ tí àwọn ènìyàn máa n pe Ọlọrun nínú májẹ̀mú láéláé nííṣe pẹ̀lú wípé wọn kò ní Ọlọrun ní baba. Ìdí èyí ló fi jẹ ́wípé nínú májẹ̀mú titun, wọn kò pèé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ kí ó baà lè dáhùn àdúrà wọn. Baba níkan ni wọn pèé. Wọn kò bẹ̀rẹ̀ si ni pèé ní orísirisi oríkì bíi atẹŕẹrẹ kárí ayé tàbí, àjàkú tí n mi igbó kìjikìji àti bẹẹ̀́bẹẹ̀́ lọ.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ọjọ́rú, Ọjọ́ Kọkànlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (1)

    Kristẹni jẹ ́ẹni tí a ti gbàlà. Ìgbà míràn wà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Kristẹni máa n gbàgbé bí àwọn ti se di onígbàgbọ́ tàbí wípé ohun tó tilẹ̀ túmọ̀ sí láti jẹ àtúnbí.

    Tó bá dá wa lójú wípé nípa àánú Ọlọ́run ni a se di onígbàgbọ́, a kò lè máa lérí wípé nítorí ìwà rere ti a n wù ni inú Ọlọ́run se dùn sí wa.

    Tí Ọlọ́run bá sọ wipe nípasẹ̀ àìlẹśẹ̀ ni on yóò fi tẹwọ́ gbà wá ni, a ó ri wípé kò sí ẹni náà ti yóò le tẹ ́Ọlọ́run lọ́rùn rárá. Nítorí wípé nípa ìgbàgbọ́ ni a fi ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ni a se n pè wá ní onígbàgbọ́. Ìdí èyí ni wípé ohun tó fi ìyàtọ̀ sáàrin onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́ ni wípé ẹni tó jẹ ́Kristẹni ní tòótọ́ ti gba ìhìnrere ti Krístì gbọ́. Bẹẹ̀́ si ni àwọn tó n sègbé; ìdí tí wọn fi n sègbé ni wípé wọn kò tíì gba ìhìnrere ti Krístì gbọ́. Ìdí èyí èyí ló fi jẹ ́wípé orúkọ ti a n pe àwọn tí o ti gbọ́ tí wọn si ti fi ọkàn wọn gbàgbọ́ nínú ìhìnrere nípa Krístì nínú Bíbélì ni onígbàgbọ́. Ti a bá tú ọ̀rọ̀ yìí palẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni ẹni-tó-ní-ìgbàgbọ́. Ìyẹn ni wípé ohun kan péré tí ẹni náà ní tó fi ìyàtọ̀ sáàrin rẹ̀ àti àwọn yókù ni ìgbàgbọ́ tó ní.

    Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni wọ́n tẹnumọ́ èyí nínú ìwé Ìṣe Àwọn Aposteli, onígbàgbọ́ ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa n tẹnumọ ju láti tọ́ka sí ẹni tó ti di àtúnbí.

    Ẹ jẹ ́kí a wo àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí fún àpẹẹrẹ.

    “A si nyàn awọn ti o gbà Oluwa gbọ kun wọn si i, ati ọkunrin ati obinrin;” (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5:14)

    “Ẹnu si yà awọn onigbagbọ ti ìkọlà, iye awọn ti o ba Peteru wá, nitoriti a tu ẹbùn Ẹmi Mimọ́ sori awọn Keferi pẹlu”. (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 10:45)

    “Ṣugbọn awọn kan ti ẹya awọn Farisi ti nwọn gbagbọ́ dide, nwọn nwipe, a ni lati kọ wọn ni ilà, ati lati paṣẹ fun wọn pe ki nwọn ki o mã pa ofin Mose mọ́.” (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 15:5)...... Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kejìlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (2)

    “O si wá si Derbe on Listra: si kiyesi i, ọmọ-ẹhin kan wà nibẹ̀, ti a npè ni Timotiu, ọmọ obinrin kan ti iṣe Ju, ti o gbagbọ́; ṣugbọn Hellene ni baba rẹ̀: (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 16:1)

    “Nigbati o si nfẹ kọja lọ si Akaia, awọn arakunrin gba a ni iyanju, nwọn si kọwe si awọn ọmọ-ẹhin ki nwọn ki o gba a: nigbati o si de, o ràn awọn ti o gbagbọ́ nipa ore-ọfẹ lọwọ pupọ”. (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 18:27)

    Gbogbo àwọn ẹsẹ Bíbélì ti a ti kà yìí fi yé wa wípé ìgbàgbọ́ ni wọ́n fi se àpèjúwe àwọn Kristẹni. Lóòtọ́ iwa mímọ́ se pàtàkì fún Kristẹni ṣùgbọ́n kiise ìwà ló fi ìyàtọ̀ sáàrin onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́ bikose ìgbàgbọ́ nínú Krístì.

    WàyìÍ, ni ìwọ̀n ìgbà tí a ti in se àtẹnumọ́ ìgbàgbọ́, ìbèrè pàtàkì tó yẹ kí a béèrè ni wípé “ìgbàgbọ́ nínú kíni”. Ó gbọ́dọ̀ ní ohun kan pàtó ti a sáà n sọ wípé kí a gbàgbọ́. Bí a tilẹ̀ ni ìgbàgbọ́ wípé lóòótọ́ ni Ọlọ́run wà tàbí wípé Ọlọ́run lágbára kò gbani là. Èṣù náà gba èyí gbọ́.

    “Iwọ gbagbọ́ pe Ọlọrun kan ni mbẹ; o dara: awọn ẹmí èṣu pẹlu gbagbọ́, nwọn si warìri.” (JAKỌBU 2:19)

    Nítorí Èṣù náà gbàgbọ́ wípé Ọlọ́run wà, kiise irú ìgbàgbọ́ tí a n sọ nìyẹn.

    Ẹ jẹ ́kí a se àyẹ̀wò irú ìgbàgbọ́ yìí.

    Irú ìgbàgbọ́ tó n sọ ènìyàn di àtúnbí ni ìgbàgbọ́ nínú ìhìnrere ti Krístì. Kíni ìhìnrere yìí? Paalu se àkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Episteli rẹ̀ sí àwọn ara Korinti.

    “Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.” (KỌRINTI KEJI 5:19)

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Kẹtàlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (3)

    “Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.” (KỌRINTI KEJI 5:19)

    “Ọlọ́run kìí ka ìrékọjá (ẹ̀sẹ̀) sí wa lọ́run” túmọ̀ sì wípé Ọlọ́run n dárí ẹ̀sẹ̀ jini. Láti rí ìdáríjì yìí gbà kò ní ohunkóhun se pẹ̀lú ìwà rere, ìwà mímọ́, jijẹ ́olúfọkànsìn àti bẹẹ̀́ bẹẹ̀́ lọ. Ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ yí wà fún gbogbo aráyé pátápátá, pàápàá jùlọ fún gbogbo ẹni tó bá ti gbàgbọ́.

    Èyí ni Ìfihàn ojú rere Ọlọ́run nípasẹ̀ Krístì. Olọrun ló n dá ẹlẹṣ́ẹ̀ láre nípa ìgbàgbọ́.

    “Kì iṣe nipa iṣẹ ti awa ṣe ninu ododo ṣugbọn gẹgẹ bi ãnu rẹ̀ li o gbà wa là, nipa ìwẹnu atúnbi ati isọdi titun Ẹmí Mimọ́,” (TITU 3:5)

    Èyí náà ni a n pè ni oore-ọ̀fẹ ́Ọlọ́run nítorípé Ọlọ́run kò bèèrè iṣẹ ́ọwọ́ wa kó tó dá wa láre. Àwa kọ́ ni a sáà bẹ̀bẹ̀ tàbí gbàdúrà kó tó rán Jésù ọmọ rè sí ayé láti wa gbà wá là. Ìfẹ ́ńlá tí Ọlọ́run fẹ ́wa ló fàá tó fi darí ẹ̀sẹ̀ wa ji wá.

    “Ṣugbọn Ọlọrun fi ifẹ On papa si wa hàn ni eyi pe, nigbati awa jẹ ẹlẹṣẹ, Kristi kú fun wa.” (ROMU 5:8)

    “Ẹniti kò da Ọmọ on tikararẹ̀ si, ṣugbọn ti o jọwọ rẹ̀ lọwọ fun gbogbo wa, yio ha ti ṣe ti kì yio fun wa li ohun gbogbo pẹlu rẹ̀ lọfẹ?” (ROMU 8:32)

    Nínú idáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ni àánú Ọlọ́run ti farahàn sí gbogbo ẹ̀dá ọmọnìyàn. Ni ìgbà àtijọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni kò mọ Ọlọ́run rárá. Kiise wípé nítorí wọn kò sín tàbí wọ́n jẹ oníwà búburú ṣùgbọ́n nítorípé wọ́n kò rí Ọlọ́run gẹǵẹ ́bí Olóore àti Aláàánú.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Kẹrìnlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (4)

    “Olukuluku kì yio si mã kọ́ ara ilu rẹ̀ ati olukuluku arakunrin rẹ̀ wipe, Mọ̀ Oluwa: nitoripe gbogbo wọn ni yio mọ̀ mi, lati kekere de àgba. Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.” (HEBERU 8:11-12)

    Nínú ibi kíkà yìí, a ri wípé ohun tí Ọlọ́run n sọ ni wipe àwọn ènìyàn yóò mọ on nítorípé on ó ṣàánú fún wọn bẹẹ̀́ sì ni wípé on kò ní ránti ẹ̀sẹ̀ tàbí àìsedéédé wọn mọ́. Èyí gan ni ìdáríjì ẹ̀sẹ̀, Ọlọ́run kò ní ránti ẹ̀sẹ̀ wa mọ́.

    Ńjẹ ́ìlérí Ọlọ́run yi wà fún àwọn tó wá láyé nígbà náà nìkan bí? Ko rí bẹẹ̀́ rárá. A se àkọsílẹ̀ rẹ̀ fún wa ki a lè mọ̀ wípé ìlérí náà niise pẹ̀lú wa ni.

    Ọlọ́run sọ wípé on kò ní ránti ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Ńjẹ ́èyí fihàn wípé Ọlọ́run máa n gbàgbé nkan bí ènìyàn se ma n gbàgbé orúkọ ẹlòmíràn tàbí bí ènìyàn se máa n gbàgbé ọ̀nà ilé ọ̀rẹ ́rẹ̀ ni? Kiise bẹẹ̀́ rárá. Ohun tí Ọlọ́run n sọ náà ni wípé ìyá tó tọ́ sì ẹ̀ṣẹ̀ kò ní tọ́ sí wa mọ́.

    Ẹnikẹńi tí a bá ṣẹ̀ sí tó bá sì sọ fún wa wípé on ti dáríjì wá ṣùgbọ́n tó tún sọ wípé “Lóòótọ́ ni mo ti dáríjì ọ́ o, ṣùgbọ́n n ó sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jẹ ọ́ ”, Ńjẹ ́ìròyìn rere ni èyí yóò jẹ ́fún wa bí? Ohun tí yóò wá sí wa lọ́kàn náà ni wípé ayédèrú ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ ni. Ìdí èyí ni wípé kò sí idáríjì ẹ̀ṣẹ̀ àyàfi tí a ba mú ìyà ẹ̀sẹ̀ kúrò. Nítorínáà, tí a bá n sọ wípé Jésù tí kó ẹ̀sẹ̀ wa lọ, kiise wípé kò seése ki a dẹṣ́ẹ̀ mọ́, ohun tó túmọ̀ sí ni wípé Jésù ti mú ìyà ẹ̀sẹ̀ wa kúrò.

    Kini ìyà ẹ̀sẹ̀?

    “Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.” ((ROMU 6:23)

    Ikú ni ìyà tó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀. Ìrú ikú wo ni a ṣọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí? “

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (5)

    “Nitori ikú li ère ẹ̀ṣẹ; ṣugbọn ẹ̀bun ọfẹ Ọlọrun ni ìye ti kò nipẹkun, ninu Kristi Jesu Oluwa wa.” (ROMU 6:23)

    Ikú ni ìyà tó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀. Ìrú ikú wo ni a ṣọ nínú ẹsẹ Bíbélì yìí?

    Ó dá wa lójú wípé kiise Ikú nípa ti ara ni a n sọ̀rọ̀ rẹ̀ nítorípé gbogbo ènìyàn ló jẹ gbèsè ikú nípa ti ara. Ikú nípa ti ẹ̀mí jẹ ́ìyapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run títí ayérayé. Èyí ni Jésù gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí èyí ni ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run ti Jésù mú wá fún wa ni Bíbélì pè ní ìyè àìnípẹ̀kun.

    “Ṣugbọn ti a fihàn nisisiyi nipa ifarahàn Jesu Kristi Olugbala wa, ẹniti o pa ikú rẹ́, ti o si mu ìye ati aidibajẹ wá si imọlẹ nipasẹ ihinrere,” (TIMOTI KEJI 1:10)

    Ńjẹ ́a ti ríi báyìí? Jésù ló mú ìyè àti àìdíbàjẹ ́wá. Nítorínáà, ìyà àìnípẹ̀kun tó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ ni Jésù gbà wá lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹni tó bá ti gbàgbọ́ nínú Krístì, ìyà ẹ̀sẹ̀ kò tún jẹ mọ́. Èyí ni Bíbélì fi yé wa. Ọlọ́run kò le ka ẹ̀sẹ̀ sì wa lọ́rùn.

    “Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ.” (KỌRINTI KEJI 5:19)

    Ìpinnu Ọlọ́run ni ìyè ayeraye láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Èyí ni ète àti ìmọ̀ràn Ọlọ́run tó farahàn nínú Krístì. Ọlọ́run ti se ìlérí iyè yìí fún gbogbo ẹ̀dá ọmọnìyàn láti ẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ láti ìgbà àtijọ́ wá.

    “Eyi si ni ileri na ti o ti ṣe fun wa, ani ìye ainipẹkun.” (JOHANU KINNI 2:25)

    Ọlọ́run ti mú ìlérí yìí ṣẹ nípa wípé ó ti fi iyè náà si inú ọmọ rẹ̀ Jésù Krístì.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kẹrìndínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (6)

    “Nitoripe gẹgẹ bi Baba ti ni iye ninu ara rẹ̀; gẹgẹ bẹl̃i o si fifun Ọmọ lati ni iye ninu ara rẹ̀;” (JOHANU 5:26)

    Nítorípé nínú ọmọ rẹ̀ Jésù Krístì ni ìyè wà, ìdí èyí ló fi jẹ ́wípé kò sí ọ̀nà míràn tí a lè fi ni iyè yìí, èyí tiise ìgbàlà kúrò nínú ikú ayeraye, àyàfi tí a bá gbàgbọ́ nínú Krístì ẹni tí Ọlọ́run ti yàn láti fun wa ní iye.

    “Kò si si igbala lọdọ ẹlomiran: nitori kò si orukọ miran labẹ ọrun ti a fifunni ninu enia, nipa eyiti a le fi gbà wa là.” (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 4:12)

    Nítorínáà, ẹnikẹńi tó bá fẹ ́ni iyè náà ni láti gbàá. Bíbélì fi yé wa wípé iyè àìnípẹ̀kun túmọ̀ si ki ènìyàn mọ Krístì. Ìyẹn ni wípé gbogbo eni to bá ti mọ Krístì ti ni iyè ainipẹkun.

    “Iye ainipẹkun na si li eyi, ki nwọn ki o le mọ̀ ọ, iwọ nikan Ọlọrun otitọ, ati Jesu Kristi, ẹniti iwọ rán.” (JOHANU 17:3)

    Ìdí èyí ni Johanu tún fi sọ wípé ẹni tó bá ti gbàgbọ́ nínú Krístì ti ré Ikú kọjá.

    “Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ mi, ti o ba si gbà ẹniti o rán mi gbọ́, o ni iye ti kò nipẹkun, on kì yio si wá si idajọ; ṣugbọn o ti ré ikú kọja bọ si ìye.” (JOHANU 5:24)

    Àkíyèsí pàtàkì tó yẹ kí a se nínú ẹsẹ Bíbélì yí ni wípé Jésù sọ wípé ẹnikẹńi tó bá gbàgbọ́ “o ni iye ti kò nipẹkun”. Jésù kò sọ wípé “yóò ní iyè àìnípẹ̀kun”. Èyí ló n sọ fún wa wípé Jesu fi dá onígbàgbọ́ lójú wípé ó ti ni iyè àìnípẹ̀kun. Ìtumọ̀ gbólóhùn yìí ni wípé ìyà tó tọ́ sí ẹ̀ṣẹ̀ kò tún jẹ irú ẹni bẹẹ̀́ mọ́. Ìdí èyí ló fi sọ wípé irú ẹni bẹẹ̀́ ti “ré Ikú kọjá”.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (7)

    Kini ìtumọ̀ ìgbàlà tí kò bá se wípé Ọlọ́run gbà wá là lọ́wọ́ ewu? Ìdájọ́ ikú ni ewu tó rọ̀ mọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí ìdájọ́ tó n bọ̀ sórí gbogbo aráyé ni Ọlọ́run se gbà wá là. Ní àwùjọ àwa ènìyàn ẹlẹŕan ara gan, kò sí ẹnikẹńi tó lè sọ nípa ìgbàlà tí kò bá se wípé a yọ ẹni náà nínú ewu.

    Fún àpẹẹrẹ nígbàtí Paalu Aposteli wà nínú àhámọ́, nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n, ó bèèrè fún Àdúrà àwọn ará nítorípé inú ewu ló wà nígbà náà ni.

    “Tobẹ ti idè mi gbogbo farahan ninu Kristi larin awọn ọmọ-ogun ãfin ati gbogbo awọn ẹlomiran; [14]Ati pe ọ̀pọlọpọ awọn arakunrin ninu Oluwa, ti o ni igbẹkẹle si ìde mi nfi igboiya gidigidi sọrọ Ọlọrun laibẹru. [16]Awọn kan nfi ìja wasu Kristi, kì iṣe pẹlu õtọ inu, nwọn ngbèro lati fi ipọnju kún ìde mi: [19]Nitoriti mo mọ̀ pe eyi ni yio yọri si igbala fun mi lati inu adura nyin wá, ati ifikún Ẹmí Jesu Kristi,” (FILIPI 1:13-14,16,19)

    Nínú gbogbo àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí, a ri wípé Paalu Aposteli wà nínú ìdè. Ìdí èyí ló fi n bẹ̀bẹ̀ fún Àdúrà fún ìgbàlà. Ìgbàlà tó n sọ niise pẹ̀lú ìtúsílẹ̀ kúrò nínú ìdè tó wà. Ìdè yìí ni ewu tó n wu Paalu nígbà naa. Nítorínáà, pabambarì ohun tí a n sọ náà ni wípé ìgbàlà tí Jésù gbà wá là niise pẹ̀lú ewu to mbọ̀. Tí ó bá si seése kí ewu náà wu wá, a jẹ ́wípé kò gbà wá là ní tòótọ́ nìyẹn.

    Ẹ má gbàgbé wípé Jesu náà ló sọ fún wa wípé ẹnikẹńi tí on ba ti sọ di òmìnira yóò di òmìnira ni tòótọ́ ni.

    “Nitorina bi Ọmọ ba sọ nyin di omnira, ẹ ó di omnira nitõtọ.” (JOHANU 8:36)

    Gẹǵẹ ́bíi Keistẹni ó yẹ kí a mọ̀ wípé irú ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ tí a rí gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni wípé Ọlọ́run kò tún rántí ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́. Ọlọ́run ti fojú fo gbogbo àìsedéédé wa gbogbo nítorípé on gan fúnrarẹ̀ ló pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ.́

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́rú, Ọjọ́ Kejìdínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (8)

    “Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.” (HEBERU 8:12)

    Ìlérí Ọlọ́run ni èyí jẹ.́ Ni ìwọ̀n ìgbà tó jẹ ́wípé ó ti pa gbogbo ẹ̀sẹ̀ wa rẹ ́tó si ti mú ìjìyà rẹ̀ kúrò, tí ìyà ẹ̀ṣẹ̀ bá tún jẹ wa ni ìgbà ìkẹhìn, a jẹ ́wípé àwa gan ni ẹ̀tọ́ láti fi ẹ̀sùn kan Ọlọ́run wípé kiise Olóòtọ́ àti Olódodo sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nìyẹn.

    Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò rí bẹẹ̀́ rárá. Nínú ìhùwàsí rẹ̀, ó hàn kedere wípé a kò tíì bí wa tàbí àwọn baba ńlá baba wa tí Ọlọ́run ti pèsè ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, ìràpadà àti ìdánilare fún wa.

    Kò sí ohun kankan tó lágbára láti yí Ọlọ́run lọ́kàn padà ni ti ìfẹ ́rẹ̀ tó ní sí wa. Nínú àánú rẹ̀ ni on tìkárarẹ̀ ti dá wa láre.

    “Tani yio ha yà wa kuro ninu ifẹ Kristi? ipọnju ni, tabi wahalà, tabi inunibini, tabi ìyan, tabi ìhoho, tabi ewu, tabi idà?” (ROMU 8:35)

    Ẹni tí a bá ti dá láre kúrò nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tàbí ẹ̀sùnkẹśùn ti a fi kan, o túmọ̀ sí wípé kò bá òfin mu ki a tún fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ kan náà jẹ mọ́ nìyẹn. Àwọn míràn tilẹ̀ ma n sọ wípé àwọn ẹ̀sẹ̀ ti a dá kí a tó gba Jésù ni Jésù kú fún kiise àwọn ti a bá dá lẹýìn ìgbà tí a ti mọ Krístì. Irú gbólóhùn yìí ki bá Bibeli mu bẹẹ̀́ ni kò si f'ọgbọ́n yọ rárá ati rárá.

    Èkíní, tó bá jẹ ́wípé àwọn ẹ̀sẹ̀ ìgbà ti a kò tíì mọ Krístì nìkan ni Ọlọ́run darí jì wá ni, a jẹ ́wípé a ó pàpà sègbé náà ni ní ìgbà ìkẹhìn. Ìdí rẹ̀ ni wípé kò sí bí akò se ni se àsìse gẹǵẹ ́bí ènìyàn ẹlẹŕan ara lẹh́ìn ìgbà tí a ti di àtúnbí. Tí a bá se àsìṣe, tani yóò wá bá wa bẹ̀bẹ̀? Kò sí ibi kankan nínú Bíbélì ti a lè tọ́ka sí wípé ẹ̀jẹ̀ Jesu, èyí tó mú ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé lọ kò niise pẹ̀lú ẹ̀sẹ̀ ẹni tó ti di àtúnbí. Ìràpadà tó wà nínú Jesu Krístì kò fi ìyàtọ̀ sáàrin ẹ̀sẹ̀ ti a dá bóyá kí a tó gbàgbọ́ nínú Krístì tàbí lẹýìn tí a gbàgbọ́ nínú rẹ̀.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kọkàndínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (9)

    Tó bá tilẹ̀ jẹ ́wípé Lóòótọ́ ni wípé ẹ̀ṣẹ̀ ìgbàtí a kò tíì gbàgbọ́ nìkan ni ẹ̀jẹ̀ Jésù wà fún ìdáríjì rẹ̀ ni, se kiise wípé Ọlọ́run fẹŕàn àwọn aláìgbàgbọ́ gan ju àwọn ọmọ tirẹ̀ gan lọ nìyẹn? Tó bá darí ẹ̀sẹ̀ ji aláìgbàgbọ́, mélòómélòó ni ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ yóò wà fún àwa ọmọ rẹ̀.

    Àìlóye dáradára nípa ìtumọ̀ ìgbàlà ló máa n fàá tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ onígbàgbọ́ fi ma n rò wípé àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ kan nínú iṣẹ ́ìransẹ Krístì kó tó ló sórí igi agbélèbú jẹ àpẹẹrẹ ìgbàlà.

    Fún àpẹẹrẹ obìnrin tí a ká mọ́ inú ẹ̀ṣẹ̀ agbèrè nínú ìwé Johanu orí kẹjọ.

    “Awọn akọwe ati awọn Farisi si mu obinrin kan wá sọdọ rẹ̀, ti a mu ninu panṣaga; nigbati nwọn si mu u duro larin, [4]Nwọn wi fun u pe, Olukọni, a mu obinrin yi ninu panṣaga, ninu ṣiṣe e pãpã. [5]Njẹ ninu ofin, Mose paṣẹ fun wa lati sọ iru awọn bẹ̃ li okuta pa: ṣugbọn iwọ ha ti wi? [6]Eyini nwọn wi, nwọn ndán a wò, ki nwọn ba le ri ohun lati fi i sùn. Ṣugbọn Jesu bẹrẹ silẹ, o si nfi ika rẹ̀ kọwe ni ilẹ. [7]Ṣugbọn nigbati nwọn mbi i lẽre sibẹsibẹ, o gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun wọn pe, Ẹniti o ba ṣe ailẹṣẹ ninu nyin, jẹ ki o kọ́ sọ okuta lù u. [8]O si tún bẹ̀rẹ̀ silẹ, o nkọwe ni ilẹ. [9]Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà. [10]Jesu si gbé ara rẹ̀ soke, o si wi fun u pe, Obinrin yi, awọn dà? kò si ẹnikan ti o da ọ lẹbi? [11]O wipe, Kò si ẹnikan, Oluwa. Jesu si wi fun u pe, Bẹl̃i emi na kò da ọ lẹbi: mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.” (JOHANU 8:3-11)

    Ó dàbí ìgbà wípé obìnrin yi gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tó fẹ ́fara jọ irú idáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí onígbàgbọ́ nínú Krístì náà gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Lóòtọ́ Jésù sọ fún ọmọbìnrin náà wípé a darí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì, Ńjẹ ́a lè sọ wípé obìnrin náà di ẹni ìgbàlà? Rárá àti rárá, kiise ẹni ìgbàlà nitoripe kò sí ẹnikẹńi tó lè rí ìgbàlà àyàfi ti ènìyàn bá gbàgbọ́ nínú ajinde Krístì.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Ogún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (10)

    Ní àná a n sọ nípa obìnrin tí a ká mọ́ inú ẹ̀ṣẹ̀ àgbèrè. Ni ìgbà náà, Jésù kò tii se iṣẹ ́ ìgbàlà gbogbo aráyé nípa kikú àti jinde kúrò nínú òkú. Nítorí èyí, obìnrin náà, Lóòótọ́ a darí ẹ̀sẹ̀ tó sẹ̀ jìí, kiise ìgbàlà. Nítorí èyí irú ìdárijì ẹ̀sẹ̀ tó gbà kò seé fi wé irú idáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí awá rí gbà gẹǵẹ ́bí ẹni ìgbàlà. Ẹ jẹ ́kí á wo irú ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tó gbà.

    Jésù sọ fún wípé

    “mã lọ, lati igbayi lọ má dẹṣẹ̀ mọ́.”

    Irú gbólóhùn yìí náà ni Jésù sọ fún ẹni tó mú láradá.

    “Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ.” (JOHANU 5:14)

    Èyí n sọ fún wa wípé irú ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ náà ní bóyá tàbí ṣùgbọ́n nínú. Ṣùgbọ́n irú ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ tí awá rí gbà jẹ ́ohun tó sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí a ti dá àti èyí tí a kò tíì dá sí òkun ìgbàgbé pátápátá ni.

    “Nitoripe emi o ṣãnu fun aiṣododo wọn, ati ẹ̀ṣẹ wọn ati aiṣedede wọn li emi kì yio si ranti mọ́.” (HEBERU 8:12)

    Tó bá jẹ wípé Ikú Jésù kò niise pẹ̀lú ẹ̀sẹ̀ tí a fa lẹh́ìn Ìgba tí a ti gbàgbọ́ ni, kí wá ni pàtàkì Ikú rẹ̀ nígbà yẹn? Tó bá jẹ wípé a ó si máa se làálàá láti tẹ ́Ọlọ́run lọ́rùn, a jẹ ́wípé ikú Krístì kò já mọ́ nkankan nìyẹn. Ṣùgbọ́n kò rí bẹẹ̀́, nípa ẹbọ kan sòsò èyí tó fi ara rẹ̀ se, o ri pa iṣẹ ́Èṣù run, ó sì ti sọ onígbàgbọ́ di pípé níwájú Ọlọ́run.

    “Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai.” (HEBERU 10:14)

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Kọkànlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (11)

    “Nitori nipa ẹbọ kan o ti mu awọn ti a sọ di mimọ́ pé titi lai.” (HEBERU 10:14)

    Kilode tí a máa n sọ wípé Jesu kú fún wa? Nigbati Jésù kú, wọn kò tíì bí gbogbo àwa tí a wà láyé òde òní. Èyí túmọ̀ sí wípé nigbati ó san gbèsè ẹ̀sẹ̀ wa, a kò tíì dá ẹ̀sẹ̀ kankan nígbà náà nìwọ̀n ìgbà tó jẹ wípé a ò tíì wá sáyé. Nítorínáà, àsansílẹ̀ ni ẹ̀jẹ̀ Jésù jẹ fún gbèsè ẹ̀sẹ̀ wa. Kò tó di wípé a dẹṣ́ẹ̀ kankan ni a ti fi ẹ̀jẹ̀ Jésù se ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀. Nínú ẹ̀jẹ̀ yìí ni ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ wà. Ìdí èyí ni o se se pàtàkì kí ìgbàgbọ́ ènìyàn wà nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù.

    “Ẹniti Ọlọrun ti gbe kalẹ lati jẹ ètutu nipa igbagbọ́ ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, lati fi ododo rẹ̀ hàn nitori idariji awọn ẹ̀ṣẹ ti o ti kọja, ninu ipamọra Ọlọrun;” (ROMU 3:25)

    Kiise wípé ìgbà tí a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ Jésù ni Ọlọ́run yóò wá jókòó láti ronú si bóyá kí on darí jì wá. Kiise bẹẹ̀́ rárá. Ọlọ́run ti sètò ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Krístì.

    “Ninu ẹniti awa ni irapada wa nipa ẹjẹ rẹ̀, idariji ẹ̀ṣẹ wa, gẹgẹ bi ọrọ̀ ore-ọfẹ rẹ̀;” (EFESU 1:7)

    Ní ìwọ̀n ìgbà tó jẹ ́wípé Ọlọ́run ti sètò ìdáríjì ẹ̀sẹ̀ sílẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Krístì. Ojúse ẹnikọ̀ọ̀kan ni láti lọ gba ohun tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ yìí. Ọ̀nà tí a sì fi lè gbà náà ni nípa ìgbàgbọ́.

    “Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni:” (EFESU 2:8)

    Ìpèsè ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí Ọlọ́run ti pèsè sílẹ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ Jésù yìí ni ìtumọ̀ oore-ọ̀fẹ.́ Nítorí wípé kò sí akitiyan tàbí làálàá wa níbẹ̀ ni a fi n pèé ní oore-ọ̀fẹ.́ Nítorínáà, ìgbàgbọ́ nínú oore-ọ̀fẹ ́Ọlọ́run ló fún wa ní idáríjì ẹ̀sẹ̀. Ìgbàgbọ́ yìí náà ló fún wa ni ìgbàlà.

    WàyìÍ, ni ìwọ̀n ìgbà tí a ti gbàgbọ́ nínú oore-ọ̀fẹ ́Ọlọ́run, ìdárijì ẹ̀ṣẹ̀, èyí ti Ọlọ́run ti se Ìgbékalẹ̀ rẹ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ Jésù, ti jẹ ́tiwa nìyẹn. Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kejìlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    ÌDÁRÍJÌ Ẹ̀ṢẸ̀ (12)

    Ẹ ránti wípé nípa ẹbọ kan ṣoṣo, èyí tiise ẹ̀jẹ̀ Jésù, ni a fi rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ìgbàkígbà tí a bá dẹṣẹ̀, kiise wípé Jésù yóò wá tún padà wá sáyé láti wá kú fún wa lẹẹ̀́kansi. Nípa ẹbọ kan ṣoṣo ló ti san gbèsè ẹ̀sẹ̀ títi láéláé.

    “Ṣugbọn on, lẹhin igbati o ti ru ẹbọ kan fun ẹ̀ṣẹ titi lai, o joko li ọwọ́ ọtún Ọlọrun;” (HEBERU 10:12)

    Ti a bá tún sẹ̀ sì Ọlọ́run ńkọ́? Ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀ lẹẹ̀́kan náà ni yóò se ìwẹ̀mọ́ rẹ̀. Nípaṣẹ̀ ẹ̀jẹ̀ yìí ni a ti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ìyẹn ni wípé gbogbo ìgbà ni ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yìí jẹ ́tiwa. Bóyá a hùwà rere tàbí hùwà búburú, ìdaríjì ẹ̀ṣẹ̀ yìí jẹ tiwa nitoripe kiise nípa ìwà rere ni a fi ri gbà bikose nípa ìgbàgbọ́ nínú oore -ọ̀fẹ ́rẹ̀.

    “[8]Nitori ore-ọfẹ li a ti fi gbà nyin là nipa igbagbọ́; ati eyini kì iṣe ti ẹnyin tikaranyin: ẹ̀bun Ọlọrun ni: [9]Kì iṣe nipa iṣẹ, ki ẹnikẹni má bã ṣogo.” ( EFESU 2:8-9)

    Tó bá jẹ ́wípé kí a tó gba Krístì ni oore-ọ̀fẹ ́rẹ̀ ti wà fún wa, kiise wípé ìgbà tí a bá gba tan ni kò wá ni wà fun wa mọ́. Tí Ọlọ́run kò bá wo ìwà wa kò tó fun wa ni oore-ọ̀fẹ ́rẹ̀, dájúdájú kiise ìwà wa ni Ọlọ́run n wò fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

    Ìgbà tí a kò yẹ ni Jésù kú fún wa. Nítorínáà, lẹh́ìn ìgbà tí Krístì ti kà wá yẹ, idáríjì ẹ̀sẹ̀, èyí tiise àyọrísí ikú ati ajinde rẹ̀ jẹ ́tiwa títí láéláé.

    Paríparí rẹ̀ ni wípé idariji ẹ̀ṣẹ̀ ti jẹ ́tiwa kí a to da ẹ̀ṣẹ̀ kankan. A si ti ri wípé Ọlọ́run ló tikárarẹ̀ se Ìpèsè idáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yìí kiise wípé nítorí a sọkún tàbí a bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ tàbí nítorípé a tọrọ ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.

    Èyí ni ìparí ẹ̀kọ́ yìí

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kẹtàlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    IBÙGBÉ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (1)

    Nínú Májẹ̀mú Láéláé, àwọn ọmọ Israeli rí àgọ́ àjọ gẹǵẹ ́bíi ibi tí Ọlọ́run n gbé.

    “Ki nwọn ki o si ṣe ibi mimọ́ kan fun mi; ki emi ki o le ma gbé ãrin wọn.” (ẸKISODU 25:8)

    Nínú òye wọn, àgọ́ yìí ni ìwàláàyè Ọlọ́run láàrin wọn. Nítorínáà, wọ́n máa n bọ̀wọ̀ fún àgọ́ náà gidi gan ni.

    “Ki ẹnyin ki o si ma pa ọjọ́ isimi mi mọ́, ki ẹnyin ki o si bọ̀wọ fun ibi mimọ́ mi: Emi li OLUWA.” (LEFITIKU 19:30)

    Pẹ̀lú onírúurú iṣẹ ́àmìn àti agbára tí àwọn ọmọ Ísráẹĺì rí, ìgbàgbọ́ wọn ni wípé inú àgọ́ náà ni ibùgbé Ọlọ́run. Pàápàá jùlọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn rò wípé ibi ìtẹ ́àánú gan ni Ọlọ́run n gbé.

    “OLUWA si sọ fun Mose pe, Sọ fun Aaroni arakunrin rẹ, ki o máṣe wá nigbagbogbo sinu ibi mimọ́, ninu aṣọ-ikele niwaju itẹ́-ãnu, ti o wà lori apoti nì; ki o má ba kú: nitoripe emi o farahàn ninu awọsanma lori itẹ́-ãnu.” (LEFITIKU 16:2)

    Ìdí èyí ló fàá tí àwọn ọmọ Ísráẹĺì fi rò wípé ni iwọn ìgbà tí Àpótí ẹ̀rí bá wà lọ́dọ̀ àwọn, wọn yóò mọ ìfẹ ́Ọlọ́run nítorí ọ̀wọ̀ tí wọn fún àpótí naa ni bí ìgbà ti Ọlọ́run bá wà láàrin wọn nípa ti ara.

    Ní ìgbà Joṣua adarí àwọn ọmọ Ísráẹĺì náà, ọwọ́ tó fí mú àpótí ẹ̀rí ni bíi wípé àpótí naa ni iwàláàyè Ọlọ́run. Ìdí èyí ló fi n gbàdúrà níwájú rẹ̀.

    “Joṣua si fà aṣọ rẹ̀ ya, o si dojubolẹ niwaju apoti OLUWA titi di aṣalẹ, on ati awọn àgba Israeli; nwọn si bù ekuru si ori wọn.” (JOṢUA 7:6)

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹrìnlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    IBÙGBÉ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (2)

    Nígbà Dafidi Ọba, ohun ti Dafidi sọ nípa kíkọ́ ilé Oluwa fi han wípé òn naa rò wípé inú àpótí yìí ni Ọlọ́run n gbé. Asọtẹlẹ wòlíì Natani sí Dafidi ni wípé Solomoni ọmọ rẹ̀ ni yóò kọ́ ilé fún Oluwa.

    Pàtàkì gbogbo àlàyé yìí ni wípé kí a lè rí dájúdájú wípé láti inú ijù títí de ìgbà àwọn ọba àti àwọn wòlíì ni àwọn ènìyàn ti rò wípé ilé tàbí àgọ́ tí a lè fojú rí ni Ọlọ́run n gbé. Wòlíì Aisaya sọ asọtẹlẹ nípa ilé tí àwọn ọmọ Ísráẹĺì kọ fún Ọlọ́run.

    “BAYI ni Oluwa wi, pe, Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si ni apoti itisẹ̀ mi: nibo ni ile ti ẹ kọ́ fun mi gbé wà? ati nibo ni isimi mi gbe wà?” (AISAYA 66:1)

    Ìyẹn ni wípé Ọlọ́run n sọ fún Ísráẹĺì wípé on kò gbé inú ilé tí wọn kọ́. Stefanu tọ́ka sí èyí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ àwọn Júù.

    “Ṣugbọn Ọgá-ogo kì igbé ile ti a fi ọwọ kọ́; gẹgẹ bi woli ti wipe, [49]Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si li apoti itisẹ mi: irú ile kili ẹnyin o kọ́ fun mi? li Oluwa wi; tabi ibo ni ibi isimi mi?” (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:48-49)

    Gbólóhùn tí Stefanu sọ yìí jẹ ́kó hàn gedegbe wípé Ọlọ́run kìigbe ilé tí a di ọwọ́ kọ́.

    Nigbati obìnrin ará Samaria nínú ìhìnrere Johanu orí kẹrin n bá Jésù sọ̀rọ̀, ohun tó mu lọ́kàn jù náà ni ibi tí wọn ti lè bá Ọlọ́run pàdé.

    “Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn.” (JOHANU 4:20)

    Ṣùgbọ́n Ìdáhùn Jésù sì obìnrin naa fihàn wípé kò sì inú ilé, tàbí àgọ́ tàbí òkè kàn tó ni ìwàláàyè Ọlọ́run nitorípé ẹ̀mí ni Ọlọ́run .

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́rú, Ọjọ́ Karùndínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    IBÙGBÉ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (3)

    Ìbéèrè pàtàkì tí a ó gbé yẹ̀wò ni wípé “kilode tí Mose pàṣẹ nipa àgọ́, àpótí ẹ̀rí àti bẹẹ̀́ bẹẹ̀́ lọ nígbàtí o jẹ ́wípé Lóòtọ́ Ọlọ́run kò gbé ibẹ̀?”. A ó rí Ìdáhùn èyí nínú ìwé Heberu.

    Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ kí a mọ̀ ni wípé nínú Krístì ni òtítọ́ ti farahàn. Èyí kò túmọ̀ sí wípé irọ́ ni ohun gbogbo tó wà kí Krístì tó dé ṣùgbọ́n nínú Krístì ni ìtumọ̀ àwọn ohun ìsaájú àti Ìfihàn èròngbà Ọlọ́run laisi àyídà ti farahàn.

    “Nitoripe nipasẹ Mose li a ti fi ofin funni, ṣugbọn ore-ọfẹ ati otitọ tipasẹ Jesu Kristi wá.” (JOHANU 1:17)

    Nitorinaa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan ti a rí kà nínú Májẹ̀mú Láéláé jẹ ́ohun tí a fi se àkàwé ohun tó n bọ̀ wá.

    “NITORI ofin bi o ti ni ojiji awọn ohun rere ti mbọ̀ laijẹ aworan pãpã awọn nkan na, nwọn kò le fi ẹbọ kanna ti nwọn nru nigbagbogbo li ọdọ̃dún mu awọn ti nwá sibẹ̀ di pipé.” (HEBERU 10:1)

    Nítorínáà, gbogbo ìlànà nípa àgọ́, àpótí ẹ̀rí, ẹbọ àti ètùtù àti bẹẹ̀́ bẹẹ̀́ lọ jẹ ́àpèjúwe ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn èyí tó farahàn nípasẹ̀ Krístì. Nítorínáà, e jẹ ki a se àgbéyẹ̀wò bí a ti sàlàyé èyí nínú ìwé Hébérù. Nípasẹ̀ Krístì ni a ti rí àgọ́ tòótọ́. Àgọ́ tòótọ́ jẹ ́èyí tí Ọlọ́run n gbé gan. Àgọ́ yìí kiise èyí tí a fọwọ́ kọ́.

    “Ṣugbọn nigbati Kristi de bi Olori Alufa awọn ohun rere ti mbọ̀, nipaṣe agọ́ ti o tobi ti o si pé ju ti iṣaju, eyiti a kò fi ọwọ́ pa, eyini ni, ti kì iṣe ti ẹ̀da yi.” (HEBERU 9:11)

    Ọlọ́run gan fúnrarẹ̀, kiise ènìyàn, ló pa àgọ́ tòótọ́ yìí.

    “Iranṣẹ ibi mimọ́, ati ti agọ́ tõtọ, ti Oluwa pa, kì iṣe enia” (HEBERU 8:2)

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kẹrìndínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    IBÙGBÉ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (4)

    Agọ́ Ọlọ́run ní tòótọ́ títí ayérayé ni Ọlọ́run fún Wòlíì Esekieli ní ìsípayá láti sọtẹĺẹ̀ nípa rẹ̀.

    Ti a bá ránti wípé ìwé Hébérù sọ wípé àgọ́ yi jẹ ́èyí tí Oluwa pa. (Heberu 8:2). Ìyẹn ni wípé, dípò bi a ti pàgọ́ àkọ́kọ́ láti ọwọ́ ènìyàn, èyí tó n tọ́ka sí iṣẹ ́ọwọ́ ènìyàn, akitiyan ati làálàá ènìyàn, àgọ́ tí Ọlọ́run yóò máa gbé títí láéláé kiise iṣẹ ́ọwọ́ ènìyàn. Láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin iṣẹ ́ọwọ́ Ọlọ́run ni yóò jẹ.́

    E jẹ ki a wo asọtẹlẹ nípa èyí ti Ọlọ́run ti ẹnu wòlíì rẹ̀ sọ.

    “Nigbana ni emi o fi omi mimọ́ wọ́n nyin, ẹnyin o si mọ́: emi o si wẹ̀ nyin mọ́ kuro ninu gbogbo ẹgbin nyin ati kuro ninu gbogbo oriṣa nyin. [26]Emi o fi ọkàn titun fun nyin pẹlu, ẹmi titun li emi o fi sinu nyin, emi o si mu ọkàn okuta kuro lara nyin, emi o si fi ọkàn ẹran fun nyin. [27]Emi o si fi ẹmi mi sinu nyin, emi o si mu ki ẹ ma rìn ninu aṣẹ mi, ẹnyin o pa idajọ mi mọ, ẹ o si ma ṣe wọn. [28]Ẹnyin o si ma gbe ilẹ ti emi fi fun awọn baba nyin; ẹnyin o si ma jẹ enia mi, emi o si ma jẹ Ọlọrun nyin. [29]Emi o si gbà nyin là kuro ninu aimọ́ nyin gbogbo: emi o si pè ọkà wá, emi o si mu u pọ̀ si i, emi kì yio si mu ìyan wá ba nyin.” (ISIKIẸLI 36:25-29)

    Ọ̀rọ̀ tó se kókó jùlọ nínú àwọn ẹsẹ Bibeli tí a kà yìí náà ni “Emi”. Èyí ló n sọ fún wa wípé iṣẹ ́ọwọ́ Ọlọ́run ni ohun tí wòlíì yìí n sọtẹĺẹ̀ nípa rẹ̀. Àwọn wo ni iṣẹ ́Ọlọ́run? Àwọn wo ni Ọlọ́run pè ní ibùgbé rẹ̀?

    “Nitori awa ni iṣẹ ọwọ́ rẹ̀ ti a ti dá ninu Kristi Jesu fun iṣẹ rere, ti Ọlọrun ti pèse tẹlẹ, ki awa ki o le mã rìn ninu wọn.” (EFESU 2:10)

    “Awa” túmọ̀ sí àwa onígbàgbọ́. Èyí ni wípé nínú wa ni Ọlọ́run fi se ibùgbé titi láéláé. Nínú Krístì, lábẹ ́Májẹ̀mú Titun ni a ti ri ìmúṣe ohun tí Ọlọ́run sọ láti ẹnu wòlíì Esekiẹli.

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Kẹtàdínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    IBÙGBÉ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (5)

    “Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi.” (KỌRINTI KEJI 6:16)

    Njẹ ́a ṣàkíyèsí bí ẹsẹ yìí se ṣàpèjúwe onígbàgbọ́? Ó sọ wípé “ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye”. Kiise ẹsẹ yìí nìkan. Paalu ti sọ òtítọ́ kan náà yìí nínú Episteli rẹ̀ àkọ́kọ́ sì àwọn ará Korinti.

    “Ẹnyin kò mọ̀ pe tẹmpili Ọlọrun li ẹnyin iṣe, ati pe Ẹmí Ọlọrun ngbe inu nyin?” (KỌRINTI KINNI 3:16)

    Kò sọ wípé ẹ̀yin yóò di tẹmpili Ọlọ́run, ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sì ẹnikẹńi tó bá ti di onígbàgbọ́ nínú Krístì ni. A ti di tempili Olọrun. Nínú Krístì, ilé ijọsin tí a lè fojú rí kọ́ ni tempili Ọlọ́run bikose àgọ́ ara onígbàgbọ́.

    Nitoripe ẹ̀mí ni Ọlọ́run, ò fi agọ́ ara onígbàgbọ́ se ibùgbé. Atubọtan òtítọ́ yìí ni wípé ìwàláàyè onígbàgbọ́ di ìwàláàyè Ọlọ́run.

    Èyí ni ìdàpọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ènìyàn.

    “Olododo li Ọlọrun, nipasẹ ẹniti a pè nyin sinu ìdapọ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.” (KỌRINTI KINNI 1:9)

    Gẹǵẹ ́bí onígbàgbọ́ a ní ìdàpọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ èyí tó n gbé inú wa? A ti di ara kan náà pẹ̀lú Kristi

    “Ṣugbọn ẹniti o dàpọ mọ́ Oluwa di ẹmí kan.” (KỌRINTI KINNI 6:17)

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ābàmẹta, Ọjọ́ Kejìdínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    TA LÓ NÍ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́?

    Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, àsìse ti àwa Kristẹni máa n se ni wípé a kìí ro àròjilẹ̀ ri a bá n kà tàbí kọ́ nípa Bíbélì. Àpẹẹrẹ àsìse yìí ni wípé àwọn kan máa n rò wípé Ẹ̀mí Mímọ́ túmọ̀ sí ẹ̀mí tí kò le gbé inú ẹnikẹńi tó bá ní ẹ̀sẹ̀ kan tàbí òmíràn. Lóòtọ́ Bibeli gbà wá ní Ìmọ̀ràn kí a gbé ìgbésí ayé tó fi ògo fún Ọlọ́run. Ìlànà Ọlọ́run tó dájú ni ku a mase jẹ ohun ikọsẹ̀ fún ẹnikẹńi. Ó yẹ kí ìwà àti ìṣesí onígbàgbọ́ yàtọ̀ sí ti ẹni tí kò mọ Krístì. Bíbélì rọ̀ wa láti ta kété sigbogbo àìsòdodo.

    “Irẹpọ̀ kini tẹmpili Ọlọrun si ni pẹlu oriṣa? nitori ẹnyin ni tẹmpili Ọlọrun alãye; gẹgẹ bi Ọlọrun ti wipe, Emi ó gbé inu wọn, emi o si mã rìn ninu wọn; emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nwọn o si jẹ enia mi. [17]Nitorina ẹ jade kuro larin wọn, ki ẹ si yà ara nyin si ọ̀tọ, li Oluwa wi, ki ẹ máṣe fi ọwọ́ kàn ohun aimọ́; emi o si gbà nyin.” (KỌRINTI KEJI 6:16-17)

    Bẹẹ̀́ náà ni Paalu rọ àwọn ara Romu láti se.

    “Ki ẹ má si da ara nyin pọ̀ mọ́ aiye yi: ṣugbọn ki ẹ parada lati di titun ni iro-inu nyin, ki ẹnyin ki o le ri idi ifẹ Ọlọrun, ti o dara, ti o si ṣe itẹwọgbà, ti o si pé.” (ROMU 12:2)

    Ìyẹn ni wípé kí onígbàgbọ́ máse hùwà tàbí sọ̀rọ̀ tàbí ronú bí àwọn ọmọ ayé yìí. Pàápàá jùlọ, ó tilẹ̀ dájú wípé àwọn ìwa pálapàla, ìwà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ ́ohun ti a fi n ṣàpèjúwe àwọn alaigbagbọ́ gẹǵẹ ́bo Paalu àti àwọn Aposteli Krístì yòókù ti sọ.

    “Arankàn, ipania, imutipara, iréde-oru, ati iru wọnni: awọn ohun ti mo nwi fun nyin tẹlẹ, gẹgẹ bi mo ti wi fun nyin tẹlẹ rí pe, awọn ti nṣe nkan bawọnni kì yio jogún ijọba Ọlọrun.” (GALATIA 5:21)

    Gẹǵẹ ́bí onígbàgbọ́, àwọn ìwà ẹ̀ṣẹ̀ yìí ni a ti gbà wa lọ́wọ́ wọn, bẹẹ̀́ni kò bójú mu ki a tún máa gbe ìgbésí ayé wa nínú wọn mọ́. Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kọkànlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    TA LÓ NÍ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (2)?

    A ti fi hàn wá wípé ìwà mímọ́ se pàtàkì fún onígbàgbọ́. Ní tòótọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ ni a pèé ṣùgbọ́n kò túmọ̀ sí wípé ó pọn dandan kí gbogbo ọ̀nà wa funfun báláú bo ẹ̀gbọ̀n òwú kí a tó lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.

    Nínú ìhìnrere ti Johanu, Jesu sọ wípé àwọn ọmọ ayé yìí kò le gba Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì sọ ìdí ri wọn kò fi lè ri gbà.

    “Ani Ẹmí otitọ nì; ẹniti araiye kò le gbà, nitoriti kò ri i, bẹñi kò si mọ̀ ọ: ṣugbọn ẹnyin mọ̀ ọ; nitoriti o mba nyin gbe, yio si wà ninu nyin.” (JOHANU 14:17)

    Ní inú abala kíkà yìí, ohun tí Jésù n sọ náà ni wípé àwọn ti kò bá mọ Jésù kò le gba Èmi Mímọ́.

    Èyí lo n sọ fún wa wípé gbígba Ẹ̀mí Mímọ́ niise pẹ̀lú kí ènìyàn mọ Krístì nìkan ni. Ẹnikẹńi tó bá ti mọ Krístì ti gba Ẹ̀mí Mímọ́ nìyẹn nitoripe kí ènìyàn mọ Krístì túmọ̀ sí kí ènìyàn ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.

    Àwọn ará Efesu tí Paalu gbọ́wọ́ lé láti gba Ẹ̀mí Mímọ́ yìí kò tíi gbọ́ ìhìnrere Krístì kí Paalu tó dé ibẹ̀, ìdí rẹ̀ nìyẹn tí wọn kò fi mọ Ẹ̀mí Mímọ́ rárá. Nitoripe jíjẹ ́ẹ̀rí nípa ìhìnrere Krístì jẹ ́iṣẹ ́tí a n se nípa Ẹ̀mí Mímọ́, kò sí ẹni tó lè rí Ẹ̀mí Mímọ́ gbà ayafi tó bá gbọ́ ìhìnrere ti Krístì. Ìdí èyí ni àwọn ènìyàn náà fi nílò láti kọ́kọ́ gbọ́ ìhìnrere ti Krístì kí wọn ó lè gba Ẹ̀mí Mímọ́.

    Bẹẹ̀́ náà ni a lè rí nínú ìwàásù Peteru ní ọjọ́ Pentikọsti. Òhun náà ṣọ nípa bí ènìyàn selè rí Ẹ̀mí Mímọ́ gbà. Ẹ jẹ ́kí a se àgbéyẹ̀wò rẹ̀.

    “Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́.” (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:38). Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Ajè, Ọjọ́ Ọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018

    TA LÓ NÍ Ẹ̀MÍ MÍMỌ́ (3)?

    “Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́.” (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:38)

    Tó bá jẹ ́wípé ó se dandan k'ó má sí àléébù kankan nínú ayé wa ku a tó lè rí Ẹ̀mí Mímọ́ gbà ni, ìyẹn ni wípé a ti se aápọn tàbí iṣẹ ́láti gba Ẹ̀mí Mímọ́ nìyẹn. Ohunkóhun tí a bá ṣiṣẹ ́fún kiise ẹ̀bùn mọ. Ṣùgbọ́n Peteru sọ wípé ẹ̀bùn ni Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ.́ Èyí ló tún fi yé wa wípé kò sí akitiyan kankan tí Ọlọ́run bèèrè lọ́wọ́ wa kí á tó lè gba Ẹ̀mí Mímọ́ bikose ìgbàgbọ́ nínú Krístì nìkan. Kiise ibi kan ti Peteru ti pe Ẹ̀mí Mímọ́ ní ẹ̀bùn ni èyí.

    “Njẹ bi Ọlọrun si ti fi iru ẹ̀bun kanna fun wọn ti o ti fifun awa pẹlu nigbati a gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, tali emi ti emi ó fi le dè Ọlọrun li ọ̀na?” (ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 11:17)

    Peteru sọ wípé gbigba Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ ́ ẹ̀bùn. Nínú ẹsẹ yìí kan náà, o tún sọ wípé àwọn tó jẹ ́Aposteli Krístì náà kò se ohun kan tó nira lọ titi bikose láti gba Krístì Oluwa gbọ́. Àwọn náà kò ní ohun àmúyẹ kan tó yàtọ̀ sí ti gbogbo ènìyàn.

    Ẹ̀bùn Ọlọ́run kò seé rà pẹ̀lú owó tàbí pẹ̀lú ìwà rere, nitoripe ẹ̀bùn ni. Ẹnikẹńi tó bá rò wípé ohun àmúyẹ kan tàbí òmíràn wà láti jẹ ́ẹni itẹwọ́gbà níwájú Ọlọ́run láti lè gba Ẹmí Mímọ́. Irú àwọn gbólóhùn tí Peteru sọ sí ọkùnrin oṣó náà ni Samaria Wiwo

    “ọkàn rẹ kò ṣe dédé niwaju Ọlọrun”

    Ẹ̀kọ́ yìí n tẹ̀síwájú lọ́la.......

  • WWW.IDANILEKOBIBELI.ORG

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kinni, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (1)

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kejì, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (2)

    Ọjọ́ Ìsẹ́gun, Ọjọ́ Kẹta, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (3)

    Ọjọ́rú, Ọjọ́ Kẹrin, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (4)

    Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Karùún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (5)

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Kẹfà, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (6)

    Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Keje, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (7)

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kẹjọ, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (8)

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kẹsan, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (9)

    Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹwàá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018BÁYÌÍ NI KÍ Ẹ MÁA GBÀDÚRÀ (10)

    Ọjọ́ Ọjọ́rú, Ọjọ́ Kọkànlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (1)

    Ọjọ́ Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kejìlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (2)

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Kẹtàlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (3)

    Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Kẹrìnlá, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (4)

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kẹẹ̀dógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (5)

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kẹrìndínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (6)

    Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (7)

    Ọjọ́rú, Ọjọ́ Kejìdínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (8)

    Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kọkàndínlógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (9)

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Ogún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (10)

    Ọjọ́ Àbámẹ́ta, Ọjọ́ Kọkànlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (11)

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kejìlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ìdáríjì Ẹ̀ṣẹ̀ (12)

    Ọjọ́ Ajé, Ọjọ́ Kẹtàlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ (1)

    Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, Ọjọ́ Kẹrìnlélógún, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ (2)

    Ọjọ́rú, Ọjọ́ Karùndínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ (3)

    Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kẹrìndínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ (4)

    Ọjọ́ Ẹtì, Ọjọ́ Kẹtàdínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ibùgbé Ẹ̀mí Mímọ́ (5)

    Ọjọ́ Ābàmẹta, Ọjọ́ Kejìdínlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ta ló ní Ẹ̀mí Mímọ́?

    Ọjọ́ Àìkú, Ọjọ́ Kọkànlọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ta ló ní Ẹ̀mí Mímọ́ (2)?

    Ọjọ́ Ajè, Ọjọ́ Ọgbọ̀n, Oṣù Kẹrin, Ọdún 2018Ta ló ní Ẹ̀mí Mímọ́ (3)?